Bí iná ṣe sọ tí ilé alájà méjì àti ẹ̀gbẹ̀lẹ́gbẹ̀ dúkìá ṣòfò nílùú Osogbo

Awọn ile meji to wa ni Ọja Akindeko, lagbegbe Alekuwo ni Osogbo lo ti jona l'Ọjọbọ.

Gẹgẹ bii ohun ti awọn ti isẹlẹ ina ọhun ṣoju wọn sọ, wọn ni inu ile, Art Deco Building nibi ti wọn ti n ta awọn ohun elo aga, nkan èlò inu ile ati ẹrọ itanna lo ti bẹrẹ.

Ina náà tun gba ile oloke meji to wa lẹgbẹẹ ile ìtajà Art Deco to sì jó kanle pẹlú àwọn dukia ẹgbẹlẹgbẹ owo ninu rẹ.

A gbọ pe laarọ kutu Ọjọbọ ni nnkan bi aago kan ni iṣẹlẹ ina na bẹrẹ.

Ọga ile iṣẹ panapana ni ipinlẹ to ba akoroyin BBC News Yoruba sọrọ ṣo pe nkan bi aago mẹta oru ni iṣẹlẹ naa dé eti wọn tí àwọn si bẹrẹ lati sa gbogbo ipa awọn lati pa iná náà.

Ohun to ṣokunfa ina naa

Ohun to fa iṣẹlẹ ina ọhun ni ko tii di mímọ bayii lasiko ti a n ko iroyin yii jọ.

Àwọn ará àdúgbò tí ìṣẹ̀lẹ̀ iná náà soju wọn ni waya iná lo kàn ara wọn, eyii tó fa ijamba náà tí ọkàn lára àwọn olutaja to n gbìyànjú láti kó àwọn ẹrú jáde sí fara pa, toun ti ọkàn lára àwọn òṣìṣẹ́ panapana kan.

Ara adugbo naa tun fi ya wá pe àwọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana gbìyànjú pupọ, ti wọn sì ṣe iṣẹ takuntakun.

Oyetola ba awọn to n ṣowo ninu ile naa kẹdun

Ẹwẹ, gomina ipinlẹ Osun, Gboyega Oyetola ti ba awọn to ni ile naa atawọn oniṣowo to n lo ile naa kẹdun.

Ninu atẹjade kan loju opo Instagram rẹ, Oyetola ni inu oun dun pe ẹmi ẹnikẹni ko ba iṣẹlẹ naa lọ.

Lẹyin naa lo gboṣuba kare fun awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panpana ipinlẹ Osun fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe lati pa ina ọhun.