Àwọn aṣòfin buwọ́lu ẹ̀wọ̀n ọdún kan fún ẹni tó bá ní ìbálòpọ̀ ṣaájú ìgbéyàwó

Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ní orílẹ̀ èdè Indonesia ti buwọ́lu àbá tó fòfin de àwọn ènìyàn tí kò bá sí nínú ìgbéyàwó láti máa ní ìbálòpọ̀ di òfin.

Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kẹfà oṣù Kejìlá, ọdún 2022 ni àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin panupọ̀ buwọ́lu àbá náà dòfin

Àmọ́ ó di ẹ̀yin ọdún mẹ́ta kí òfin náà tó bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ tí ìrètí sì wà pé àwọn ènìyàn máa pe òfin náà lẹ́jọ́.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ló ti bẹ̀rẹ̀ ìwọ́dé níwájú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin tó wà ní Jakarta, olú ìlú orílẹ̀ èdè Indonesia.

Lábẹ́ òfin tuntun yìí, àwọn tó bá jẹ́ arìnrìnàjò tó ń ṣe àbẹ̀wò sí Bali àti àwọn ààyè irin ìnájú mìíràn ní Indonesia ni òfin yìí báwí, tí àwọn tí kò bá sì kìí ṣe tọkọtaya sì lè rí ẹ̀wọ̀n ọdún kan he pé wọ́n ní ìbálòpọ̀.

Bákan náà ni òfin yìí tún fòfin de tí kò bá kìí ṣe lọ́kọláya láti máa gbépọ̀ láì tíì ṣe ìgbéyàwó, tí àwọn tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ sì lè rí ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fa he.

Ajeng, ọmọbìnrin mùsùlùmí ẹni ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n tó ń gbé ní West Java ti Depok ní òun kò lè gbépọ̀ pẹ̀lú olólùfẹ́ òun tí òun ti ń gbépọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ láti ọdún márùn-ún sẹ́yìn.

Ó ní lábẹ́ òfin tuntun yìí, tí ẹnìkan nínú ẹ̀bí àwọn méjéèjì bá fi lè lọ fi ẹjọ́ àwọn sun àwọn ọlọ́pàá, àwọn le lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún kọ̀ọ̀kan.

Ajeng ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ ni nínú ẹ̀sìn òun kí ọkùnrin àti obìnrin tí kò bá tíì gbéyàwó máa bá ara wọn ní àjọṣepọ̀ síbẹ̀ òun kò rò wí pé ó yẹ kí ìjọba gbé òfin rẹ̀ lé òfin ẹ̀sìn kankan.

“Mo gbàgbọ́ pé níní ìbálòpọ̀ tàbí gbígbépọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin kìí ṣe ìwà ọ̀daràn kò sì yẹ kí orílẹ̀ èdè wa gbé òfin rẹ̀ lórí ẹ̀sìn.”

Ó fi kun pé láti ọdún 2019 tí wọ́n ti kọ́kọ́ kéde láti ṣe òfin náà ni òun ti darapọ̀ mọ́ àwọn tó ń ṣe ìwọ́de láti tako òfin ọ̀hún.

Àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn ní àwọn obìnrin, LGBT àti àwọn ẹ̀yà kéékèèté ni òfin náà yóò ṣàkóbá fún nínú àwọn ènìyàn mílíọ̀nù 267 tó ń gbé ní orílẹ̀ èdè náà.

Ilé aṣòfin bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti máa rán àwọn tó bá ní ìbálòpọ̀ ṣaájú ìgbéyàwó lẹ́wọ̀n

Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ní Indonesia ti ń gbé ìgbésẹ̀ láti tọwọ́ bọ òfin kan nínú oṣù yìí.

Ohun tí òfin náà dálé lórí ni fífi ìyà jẹ ẹnikẹ́ni tó bá ṣe àgbèrè yálà ẹni tó ti ṣe ìgbéyàwó tàbí àpọ́n tàbí omidan.

Ìjìyà náà sì lè le débi tí wọn yóò ju ènìyàn sí ẹ̀wọ̀n ọdún kan.

Bambang Wuryato tó jẹ́ olóṣèlú tó wà lára àwọn tó gbé àbá náà kalẹ̀ ní ó ṣeéṣe kó jẹ́ wí pé ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀ ni àwọn yóò sọ àbá ọ̀hún dòfin.

Tí àbá ọ́hún bá dòfin tán àti àwọn ọmọ Indonesia àti àlejò tó bá ń gbé ní Indonesia ni òfin náà yóò bá wí.

Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àbá ọ̀hún, tí ènìyàn bá lọ fi ẹjọ́ sùn àwọn aláṣẹ pé ẹnìkan ti wu ìwà àgbèrè.

Fún àwọn tó bá ti ṣègbéyàwó, ọkọ tàbí ìyàwó ló le lọ fi ẹjọ́ ẹnìkèjì rẹ̀ sùn tó bá ṣe àgbèrè.

Bákan náà ni àwọn òbí le lọ fi ẹjọ́ ọmọ wọn tó bá ni ìbálòpọ̀ láì tíì ṣe ìgbéyàwó sùn fún ìjìyà tó tọ́.

Bákan náà, lábẹ́ òfin yìí, ó ti di èèwọ̀ fún ọkùnrin àti obìnrin tí kò tíì ṣe ìgbéyàwó láti máa gbépọ̀, tí àwọn tó bá sì ṣe bẹ́ẹ̀ le rí ẹ̀wọ̀n ó kéré tán oṣù mẹ́fà he.

Awọn eeyan kan ko faramọ abadofin yii

Àwọn olókoòwò ti ń fi ìkọnilóminú wọn lórí òfin hàn wí pé ó ṣeéṣe kó ba ọrọ̀ ajé orílẹ̀ èdè náà jẹ́ pàápàá lẹ́ka ìnàjú.

Wọ́n wòye pé àwọn tó máa ń wá sí Indonesia fún ìsinmi ni wọn yóò máa rò ó ní ẹ̀ẹmèjì kí wọ́n tó wá tí wọ́n bá fi lè tọwọ́ bọ àbá ọ̀hún dòfin.

Igbákejì alága ẹgbẹ́ àwọn tó ń pèsè iṣẹ́ ní Indonesia, Shinta Widjaja Sukamdani ni òfin náà kò ní jẹ́ kí àwọn ènìyàn dókoòwò pẹ̀lú orílẹ̀ èdè àwọn mọ́.

Ní ọdún 2019 ni ìjọba Indonesia ti kọ́kọ́ fẹ́ buwọ́lu òfin yìí ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ṣe ìwọ́de láti tako òfin náà.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn tó fi mọ́ àwọn ọ̀dọ́ ló ṣe ìwọ́de nígbà náà ni èyí tó dá wàhálà ńlá sílẹ̀ ní olú ìlú orílẹ̀ èdè Indonesia ìyẹn Jakarta.

Àwọn olùfẹ̀hònúhàn náà ju òkúta lu àwọn ọlọ́pàá, tí àwọn ọlọ́pàá náà sì ń ju omi àti afẹ́fẹ́ tajútajú lu àwọn tó ń fẹ̀hónú hàn ọ̀hún.

Irú àwọn òfin báyìí pàápàá èyí tó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ wọ́pọ̀ ní àwọn agbègbè tí mùsùlùmí pọ̀ sí ní orílẹ̀ èdè Indonesia.