You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ó kéré tán ìkọ̀ ọmọogun Russia 400 ló kú ní ìkọ̀lù àdó olóró – Ukraine
Orilẹede Ukraine ti ni o kere tan ikọ ọmọogun Russia irinwo lo ba ikọlu ti wọn ṣe si agbegbe Makiivka lọ.
Bakan naa ni Ukraine ni o le ọọdunrun awọn soja ti wọn fi ara pa ninu iṣẹlẹ naa.
Amọ Russia ni o kere tan ikọ ọmọogun awọn mọkandinlaadọrun lo ku ninu ikọlu ti Ukraine ṣe si awọn.
Agbegbe Makiivka, ni agbegbe Donetsk ni Russia gba lọwọ Ukraine ninu ogun to n lọwọ.
‘’Awọn ṣoja to n lo foonu lọgọọrọ lo je ki wọn kosi panpẹ ikọlu Ukraine’’
Orilẹede Russia ti ni idi ti Ukraine fi ṣe aṣeyọri ninu ikọlu si awọn soja wọn ni pe awọn ọmọogun naa n lo ẹrọ ilewọ wọn lọgọọrọ lasiko ikọlu naa.
Wọn ni ẹrọ ilewọ naa lo fi wọn han pe wọn pọ ni agbegbe naa, ti Ukraine fi ṣe ikọlu si wọn.
Eyi ni iku ikọ ọmọogun Russia to pọju lọ lati igba ti ogun ti bẹrẹ laarin orilẹede Ukraine ati Russia.
Ninu atẹjade ti Russia fi lede mo wọn ti ni ado oloro rọkẹẹti mẹfa ni ikọ ọmọogun Ukraine ju lu ileẹkọ awọn ọmọogun wọn.
Awọn ọmọogun naa ni wọn ṣẹṣẹ darapọ mọ ikọ to wa loju ogun.
Bakan naa ni wọn fi kun un pe igbakeji adari ikọ ọmọogun, Ọgagun Bachurin ba ikọlu naa lọ.
Ijọba Russia fikun un pe iwadii n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa.