You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ẹ ò gbọdọ̀ lo àwọn ọkọ̀ tó ní àmì ìdánimọ̀ ìjọ láti rìnrìnàjò mọ́ - CAC ṣèkìlọ̀ fáwọn ọmọ ìjọ
Awọn alaṣẹ ijọ Aposteli ti krisiti , ìyẹn Christ Apostolic Church, (CAC) ni orilẹ-ede Naijiria ti rọ awọn ọmọ ilẹ ijọsin naa kaakiri orilẹ ede yii lati yago fun ṣiṣe irinajo pẹlu awọn ọkọ to ni ami idanimọ ile ijọsin naa lara ni asiko yii.
Arọwa yii lo wa ninu atẹjade kan ti ile ijọsin naa kọ ranṣẹ si gbogbo awọn pasitọ ati awọn oludari agbegbe ti ijọ CAC.
Akọwe gbogbogboo ijọ naa, Pasitọ Emmanuel Mapur lo buwọlu atẹjade ọhun.
Wọn ni ti o ba pọn dandan fun wọn lati rinrinajo pẹlu ọkọ ile ijọsin ọhun, wọn nilo lati gba awọn ọlọpaa to ni to ni ohun ija ogun lọwọ lati tẹle wọn rin irinajo bẹẹ.
Ẹ o ranti pe ni nnkan bi ọsẹ mẹta sẹyin ni awọn ajinigbe ji awọn akọrin ogun to jẹ ọmọ ijọ CAC ni ipinlẹ Ondo gbe lasiko ti wọn ṣe irinajo lọ si ibi eto ayẹyẹ isinku kan.
Atẹjade naa ni o jẹ ohun to awọn lominu bi wọn ṣe n ji awọn eniyan gbe lasiko yii paapaa ti wọn ba ti wa ninu ọkọ to ni ami idanimọ lara.
O fi kun pe ijinigbe to waye ni ipinlẹ Ondo nibi ti wọn ti ji awọn akọrin ile ijọsin naa gbe ni ijọba ibilẹ Ose jẹ ohun to pe fun ki awọn tunbọ wa ni oju lalakan fi n ṣọri.
“Àṣẹ ti wá pé gbogbo awọn ọmọ ijọ to ba fẹ rinrinajo pẹlu awọn ọkọ to ni ami ile ijọsin lara gbọdọ gba awọn ọlọpaa to ni ohun ija ogun lọwọ lati tẹle wọn foun irinajo bẹẹ.”