Ilé ẹjọ́ pàṣẹ pé kí wọn gbé Naira Marley wá jẹ́jọ́ ẹ̀sùn lílu jìbìtì wíwọ́ ike owó

Egbinrin ọ̀tẹ̀, bí a ṣe ń pá ọkàn, ní òmíràn ń rú ní ọrọ ayé gbajúmọ̀ akọrin takasufe nnì, Azeez Fashola, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ sí Naira Marley.

Ìdí ni pé kàkà kí ewé àgbọn dẹ lórí àwọn ẹ̀sùn tí wọn fi kàn-án nílé ẹjọ́, kò kò kò ló tún ń le si.

Bẹẹ ba gbagbe, Naira Marley yìí ni àjọ EFCC tí ń bá rò ẹjọ tẹ́lẹ̀ lórí ẹ̀sùn onikoko mọ́kànlá àti lílu jìbìtì gba owo olówó lórí ayélujára láti ipaṣẹ ike wiwọ.

Naira Marley yìí náà sì tún ni ẹnu ń kùn lórí ọ̀rọ̀ ikú akọrin takasufe nnì, Ilerioluwa Aloba, ti ọpọ eeyan mọ sì Mohbad, tó sì ti fa ara rẹ kalẹ fáwọn ọlọ́pàá.

Agbẹjọro fun Naira Marley ni onibara oun ko le yọju sile ẹjọ tori pe o wa ni ahamọ ọlọpaa lori iku Mohbad

Àmọ́ nílé ẹjọ́ lónìí, lórí ẹ̀sùn mọ́kànlá tó nii ṣe pẹ̀lú lílu jìbìtì nípa gbígba owó láti inú ike owó ọ̀pọ̀ èèyàn èyí tó ti ń jẹ́jọ́ rẹ tẹ́lẹ̀, ṣe ni ọrọ tún bẹyin yọ fún.

Idi ni pé Naira Marley, ti wa ni ahamọ àwọn ọlọ́pàá láti Ọjọ́ Isẹgun lórí ìwádìí ikú Mohbad, èyí tó mú ko má ṣeeṣe fún láti yọjú sile ẹjọ́ náà lónìí fún itẹsiwaju ẹ̀sùn ike wíwọ.

Atẹjade kan tí àjọ EFCC fi lédè làwọn ojú òpó ayélujára rẹ wá kéde bí ọ̀rọ̀ ṣe bẹyin yọ nílé ẹjọ́ lónìí.

Atẹjade náà ni nígbà tí ìgbẹ́jọ́ náà wáyé loni, aṣáájú ikọ̀ agbẹjọro fún Naira Marley, àgbà amofin Olalekan Ojo sọ fún ile ẹjọ pe onibara oun ko wa sile ẹjọ́ nítorí pé ó sì wà ní ahamọ ọlọ́pàá lórí ikú Mohbad.

Ojo wá rọ ile ẹjọ pe ko sún ìgbẹ́jọ́ náà síwájú di ọjọ́ miran, ọjọ́ re.

"Ile ẹjọ kẹ̀yìn sí ẹ̀bẹ̀ agbẹjọ́rò Naira Marley, ó ní kó wá jẹ́jọ́ tó ń lọ lọ́wọ́ tẹ́lẹ̀"

Àmọ́ nígbà tó ń fèsì lórí ìbéèrè Ojo, agbẹjọro fún ikọ̀ olupẹjọ, Bilikisu Buhari rọ ile ẹjọ láti pàṣẹ pé kí wọn fa Naira Marley silẹ, ko le wa jẹjọ naa, èyí tó ti ń lọ lọ́wọ́ tẹ́lẹ̀.

Adajọ Oweibo, tile ẹjọ́ gíga ijọba àpapọ̀ tó wà ní Ikoyi wa fontẹ lu ìbéèrè agbẹjọro ikọ̀ olupẹjọ naa, tó sì ni kí Naira Marley yọjú láti wá jẹjọ naa.

Adajọ náà wa sún ìgbẹ́jọ́ síwájú di Ọgbọnjọ oṣù kẹwàá ọdún 2023, tí ìrètí wà pé Naira Marley gbọ́dọ̀ yọjú sílé ẹjọ́ naa.