You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ipò tí àwọn ìjọba ìpínlẹ̀ yóò bá ara wọn tí ìjọba àpapọ̀ kò bá fún wọn ní owó
Idajọ ile ẹjọ lati fofin de owo ti ìjọba apapọ n fun ìjọba ìpinlẹ Rivers ni o ti fa ọpọlọpọ awuyewuye lorilẹede Naijiria.
Adajọ Joyce Abdulmalik ti ile ẹjọ gíga to n jokoo niluu Abuja lo paṣẹ fun banki apapọ bẹẹ, to si salaye pe ọna ti Gomina Siminalayi Fubara gba lati gbe eto isuna ipinlẹ naa lọ siwaju awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin mẹrin ni ko ba ofin ọdun 1999 mu.
Bakan naa ni Adajọ ni owo ti Fubara gba lati oṣu kini si oṣu kẹwaa lo tako ofin.
Bẹẹ ba gbagbe, irufẹ iṣẹlẹ yii waye lọdun 2004 nigba ti ìjọba Aarẹ Olusegun Obasanjo kọ lati fun ìjọba ìpinlẹ tí Aarẹ Bola Ahmed Tinubu jẹ gomina nigba ni owo nitori idasilẹ ìjọba ibilẹ tuntun.
Ohun gboogi to fa ọpọlọpọ awuyewuye ni ipo ti ipinlẹ Rivers yoo wa lẹyin ti ìjọba apapọ ko ba fun ni owo mọ.
Kí ni ofin sọ nipa pinpin owo ìjọba si ẹka ìjọba?
Pinpin owo ìjọba lo wa laarin ẹka ìjọba mẹta gẹgẹ bii ofin ṣe gbe kalẹ.
Ofin ni ijọba apapọ ni anfani si ida 52.68, ìjọba ìpinlẹ ida 26.72, ti ijọba ibilẹ ni ida 20.60 ni oṣoṣu.
Ohun tí ile ẹjọ n sọ nípa ipinlẹ Rivers ni pe awọn aṣofin tí Gomina Fubara lo safihan eto isuna fun ni wọn ko ki n se ojulowo ọmọ ile igbimọ aṣofin nitori wọn ti kuro ninu ẹgbẹ oselu to gbe wọn wọle.
Ni bayii gbogbo oju lo wa lori ẹjọ kotẹmilọrun tí Gomina Fubara pe.
Awọn ipinlẹ wo ni ko gbe ara le owo ijọba apapọ?
Iwadii BudgetIT ninu oṣu kẹwaa safihan pe ipinlẹ mọkanlelọgbọn ni orilẹede Naijiria lo n gbe ọkan le tí ìjọba apapọ n fi ransẹ.
Iwadii tẹsiwaju lati safihan awọn ipinlẹ ti wọn ko nilo lati gbe ara le ijọba apapọ ti wọn jẹ ipinlẹ Eko, Rivers, Anambra, Kwara ati Cross River.
BudgetIT ni awọn ipinlẹ yii nìkan ni wọn le se ìjọba lia gba owo lọwọ ijọba apapọ.
Onimọ nípa imọ isiro, Malam Abubakar Aliyu ni ipo ti ọpọ yoo wa ko ni dara tí wọn ba gba lati ọwọ ìjọba apapọ.
"Ijọba o ni le san owo oṣu, ṣe awọn isẹ akanṣe ati awọn isẹ ìjọba."
BudgetIT ni awọn ipinlẹ yii ni anfani lati tan isoro wọn nitori owo ti n ri fun ara wọn, ti wọn si pawo si apo lai nani owo ìjọba apapọ.
"Awọn ipinlẹ kọkanlelọgbọn yoo ku ni lati wa ọna lati ma pawo wọle kí wọn to le sọ pe awọn ko nilo owo lati apo ìjọba apapọ."