You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Èyi ni ohun tí àwọn òṣèré sọ nípa ikú agba oṣere, Agbako, tó jáde láyé
Gbara ti iroyin iku agba oṣere nni, Abdulsalam Ishola Sanyaolu,ẹni tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Àgbákò, jade lori ayelujara ni awọn eeyan ti n daro rẹ, paapaa julọ, awọn oṣere ẹgbẹ rẹ.
Aarẹ TAMPAN, Bolaji Amusan, iyẹn Mista Latin lo kọkọ fidi iku naa mulẹ pẹlu ọrọ idaro to kọ soju opo Instagram rẹ pe. ’’ o daarọ baba’’
Bakan naa ni agba ọsere mi-in lagboo tiata Yoruba, Alagba Jide Kosoko naa kọ nipa Oloogbe pe, ‘’O daarọ o, Baba Charles ta a tun mọ si Agbako, ọgọrun-un kan ọdun (101 years) ba wasa ba. Sun ‘re o.
Awọn oṣere yooku to tun daro Oloogbe Charles Olumo Agbako ni:
Funke Akinde: “Awwwwwwww, ki Ọlọrun fun ẹmi wọn nisinmi. Wow. Oluwa tobi lọba.’’
Mercy Aigbe: K’Ọlọrun f’ọrun kẹ wọn.
Biodun Okeowo: Ẹ sun ‘re sir. Bo ṣe le wu ki arugbo wa dagba to, a ki i fẹ ki wọn lọ.!
Kunle Afod: O daarọ, Pa Charles Olumo (Baba Agbako), oṣere to dagba ju lọ. Ọgọrun-un ati ẹyọ kan ọdun, sun ‘re ooo. O dabọ, o di oju ala.
Awọn mii ti wọn tun daro oloogbe naa ni:
Madam Ṣajẹ (Ṣajẹ ti o lọga) Ẹ sun ‘re, baba.
Kemity: Sun ‘re, agba oṣere
Wumi Ajiboye: Ẹ sun ‘re sir, o daarọ, agba oṣere
Foluke Daramola: Baami ti lọ.
Ronke Ojo (Ronke Osodi Oke) Sun ‘re, baba mi.