You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo àwùjọ tí àwọn ìyà ti ń bẹ̀bẹ̀ ọkọ fún àwọn ọmọ wọn obìnrin
- Author, Fan Wang
- Role, BBC News
- Reporting from, Singapore
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
Ọkunrin ogun ni iya Chen wa fun un lati fẹ. Gbogbo ogun yii lo si ba jade lọkọọkan.
Chen ni awọn ọkunrin wọnyii le ju ara wọn lọ nitori pe ohun kan wa ninu igbe aye rẹ ti pupọ ninu awọn ọkunrin to pade fun ọrọ ifẹ ko fẹ gba.
Ohun naa si ni pe, Chen ko fẹ bimọ.
“Ọmọbibi jẹ ohun to nira pupọ. Emi o fẹ bimọ’” ni ariwo ti orin ti Chen, to ti le diẹ logun ọdun n pariwo.
O ni nitori ati ba ọkunrin kan jẹ orukọ loun ṣe fẹ ṣe igbeyawo.
“Ṣugbọn o ṣoro lati ri ọkunrin to fẹ ṣe igbeyawo lai ni bi ọmọ. Bi igba ti eeyan fẹ pa ọkunrin ni ti ko ba bimọ.”
Pẹlu gbogbo ijakulẹ to n ni lọdọ awọn ọkunrin wọnyii, awọn to yii ka kii ye fun ogun mọ ọ lọrun pe asiko ti n pẹ fun un lati gbeyawo.
Àwọn ìròyìn míràn tí ẹ tún lè kà:
- Ìran kan si ìkejì ló n gbèrò láti ṣe ìgbéyàwo àjùmọ̀ṣe 'Shao' fọ́mọ wọn
- Ṣé òfin Nàíjírìà dá ìgbéyàwó rẹ mọ̀? Bí o ṣe lè mọ àrídájú rẹ̀ nìyí
- Yorùbá ní ìlànà fún àyẹ̀wò mímọ ọmọ ọkọ yàtọ̀ sí ọmọ àlè lówó tí kò ga ju ara lọ - Ifayemi Elebuibon
- "Lẹ́yìn oṣù díẹ̀ tí mo ṣe ìgbeyàwó ni mo bẹ̀rẹ̀ sí tọ̀ sílé pada"
Ni ọdun to kọja iye awọn eeyan to wa lorilẹede China din ku fun igba akọkọ laarin ọgọta ọdun.
Iye awọn eto igbeyawo to waye jẹ miliọnu mẹfa o le ẹgbẹrun lọna ẹrin ati mẹta (6.83 million), ko si dinku to bẹẹ rii lati ọdun 1986.
Nitori segesege ọrọ aje ati aisi iṣẹ to n gogo sii lorilẹede China, awọn ọdọ lorilẹede naa ti n kẹyin si ilana igbeyawo ti awọn obi wọn yan.
Awọn oṣiṣẹ ijọba ‘ko ni oye irora yii’
Ọrọ yii ti n kọ olori orilẹede China, Xi Jinpin pẹlu lominu. Laipẹ yii lo sọrọ lori igbeyawo ati ibimọ lorilẹede naa. O ni a ṣe pataki lati tubọ “mu ki eto iṣejọba gbopọn sii” nibẹ lati lee mu ayipada ba iwoye awọn ọdọ nipa eto igbeyawo, ọmọ bibi ati ẹbi nini.
Kii ṣe pe awọn adari iṣejọba lorilẹede naa ko tii gbiyanju.
Kaakiri orilẹede naa lawn aṣiwaju ti n ke si awọn ọd lati gbeyawo, ti wọn si tun n rọ awọn to ti gbeyawo lati duro ninu igbeyawo wọn ki wọn si tun bimọ.
“Awọn kan pẹgan mi nitori pe mo fẹ ọkunrin to jẹ akanda ẹda’ Ni ibẹrẹ ọdun yii, ileto kekere kan lẹkun ila oorun Zhejiang kede pe awọn yoo fun awọn lọkọlaya ni ẹgbẹrun kan yuan owo ilẹ naa (iyẹn dọla mẹtadinlogoje $137) gẹgẹbi ẹbun owo bi ọjọ ori iyawo ninu igbeyawo bẹẹ ko ba ti ju ọdun marundinlọgbọn lọ.
Ikede yii ya ọpọ lẹnu, o si tun bi awọn olugbe agbegbe naa ninu gidi debi pe wọn n tọka si ijọagbegbe naa gẹgẹ bi eyi ti ko lọpọlọ lati maa ni ero pe ẹbun owo to kere bẹẹ lee mu ki awọn ọdọ yi ipinnu wọn pada lori ohun to ṣe pataki bẹẹ.
Bakan naa ni awọn alaṣẹ ijọba nibẹ tun n pe fun eto binukonu ọlọgbọn ọjọ fun awọn tọkọtaya to ba fẹ kọ ara.
Eyi pẹlu ti mu ki awọn eeyan maa kọminu pe o ṣeeṣe ko maa fa idiwọ fun awọn to fẹ ṣe ipinnu fun ara wọn, paapaajulọ awọn obinrin ti awọn ọkọ wọn n lu wọn.
Ni awọn ileto kekeke nibi ti awọn ọdọkunrin ti n koju ipenija pupọ lori ọrọ ati ri aya fẹ, awọn alaṣẹ ijọba ti paṣẹ fun awọn obinrin lati dẹkun bibeere owo ori to ga ju ẹmi lọ fun ati fẹ iyawo.
Amọṣa, onimọ nipa ọrọ aje kan, Li Jingkui sọ pe eyi ko le ran ọrọ to wa nilẹ.
Awọn akọṣẹmọṣẹ n sọ pe awọn adari orilẹede China ko lee mọ ohun to n ṣe iwuri fun awọn ọdọ, paapaajulọ awọn obinrin lati yan ohun ti wọn fẹ.
“Gbogbo awọn oṣiṣẹ ijọba wọnyii lo ni iyawo, nitori naa irora ti awọn eeyan n doju kọ yii ko le ye wọn” ni ọrọ ti ọgbẹni Li sọ gẹgẹ bi alaye.
Ifẹ ko wọn mọ bayii bii ti igba kan
Awọn onimọ n woye pe igun meji lo wa laarin awọn apọn lorilẹede China: awọn obinrin to wa ni ilu nla, ati awọn ọ̀kunrin to wa ni ẹsẹ pupu, iyẹn ileto kekeke.
Awọn ọkunrin to wa ni ileto kekeke n dojukọ ipenija ọrọ aje to lagbara bii owo ori to gọbọi ati wiwa iṣẹ lati fi gbe ẹbi ro. Eyi lo n mu ki awọn ọdọbinrin to wa lẹsẹ kuku o maa dẹsẹ duro pupọpupọ lori ọrọ a n ṣe igbeyawo
Awọn obinrin to wa ni ilu nla gbogbo ni tiwọn pẹlu n kọminu lori alafo to n wa laari afojusun wọn fun igbeyawo ati afojusun awọn eeyan yooku laujọ wọn.
“Emi o kaya soke rara nitemi o. Awọn to yi mi ka lo n ko mi laya soke.” Eyi lọr ti Chen sọ.
Chen ni asiko ti yatọ si igba ti awọn obi oun to jẹ pe ipenija nla ni lati ri ifẹ ti igbe aye si nira, o ni nisiyi awọn eeyan, paapaajulọ awọn obinrin ni ọpọlọpọ ohun lati yan ohun to wu wọn.
“Lode oni, awọn n lero pe kii ṣe didan ki eeyan bimọ.”
Bakan naa lawọn obinrin n kọminu pe ori awọn obinrin ni gbogbo ipolongo ati itaniji ti ijọba nṣe n da le, ti wọn si n pa ọrọ awọn ọkunrin ati ojuṣe wọn gẹgẹbi alabaṣe ninu irinajo igbeyawo ti si ẹgbẹ kan.
Lorilẹede China, “nṣe lawọn obinrin to ti bimọ, “n tọ ọmọ wọn bi ẹni pe ọkọ ti wọn bi awọn mọ naa fun ti di oloogbe.” Eyi fihan pe awọn ọkọ kii ṣe ojuṣe wọn ni ile tabi ninu eto titọ awọn ọmọ wọn.
Arabinrin ẹni ọdun mẹtalelọgbọn kan ti ko fẹ ka darukọ oun ṣalaye pe “gbogbo awọn ọkunrin to ti gbeyawo ti mo mọ ni wọn n lero pe ojuṣe kan ṣoṣo ti wọn ni ninu ẹbi ni lati pa owo.
“Awọn iya maa n ni ọgbẹ ọkan pe awọn ko ṣe ojuṣe wọn fun awọn ọmọ wọn. Wọn a tilẹ maa ro pe ẹṣẹ nla ni lati pẹ wọle, ṣugbọn awọn baba kii ri ẹbi ninu eyi rara.”
Nibayii, awọn ọdọ lorilẹede China ti wa fariga mọ awọn adari eto iṣejọba lorilẹede naa lọwọ pe iṣẹ ṣi pọ fun wọn lati ṣe ki wọn to lee mu awọn yi ọkan pada lori ọrọ igbeyawo.
“Awa ni iran to kẹyin” ni ọrọ akọmọna ti awọn ọdọ orilẹede naa fi n da awọn adari ijọba lohun nigbakugba ti wọn ba ti n ṣe ijiroro nipa igbe aye wọn lorilẹede China.