You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọmọdékùnrin tó dúró síwájú ọkọ̀ Peter Obi lásìkò ìpolongo ìbò 2023 gba ìtúsílẹ̀ lẹ́yìn oṣù mẹ́ta lọ́gbà ẹ̀wọ̀n
Quadri Alabi, ọmọ ọdún mọ́kànlá tó di gbajúmọ̀ nígbà tó dúró siwájú ọkọ̀ Peter Obi lásìkò ìpolongo ètò ìdìbò ọdún 2023, ti gba ìtúsílẹ̀ kúrò ní àhámọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n Kirikir, ìpínlẹ̀ Eko tó ti wà láti bíi oṣù mẹ́ta sẹ́yìn.
Ní ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹtàdínlógún, oṣù Kẹrin ni adájọ́ ilé ẹjọ́ Májísíréètì Apapa sọ pé kí Alabi máa lọ sílé rẹ̀ láyọ̀ àti àlááfíà lẹ́yìn tó gba àmọ̀ràn iléeṣẹ́ Director of Public Prosecutions tí ìpínlẹ̀ Eko.
Ẹ̀ka ìjọba náà sọ pé kò sí ẹ̀rí kankan láti fi gbe ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan ọmọkùnrin náà múlẹ̀.
Agbẹjọ́rò ọmọ náà, Inihebe Effiong tó kéde ìtúsílẹ̀ Quadri Alabi lórí ìkànnì X rẹ̀ lọ́jọ́rú, sọ pé àwọn ọmọ ìta kan ní agbègbè Amukoko ló mọ̀ọ́mọ̀ parọ́ mọ́ ọmọ náà lẹ́sẹ̀.
Ó ní àwọn èèyàn náà gbé Alabi tí wọ́n sì lọ fà á lé àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́ pẹ̀lú ẹ̀sùn pé ó kópa níbi ìjà ìgboro kan tó wáyé ní agbègbè náà.
Gẹ́gẹ́ bí Effiong ṣe sọ, láti ọdún 2023 tí ọmọ náà ti rí àwọn owó kan gbà látọwọ́ àwọn alátìlẹyìn Peter Obi ni àwọn èèyàn kan ti ń dúnkokò mọ́ ọn.
Ó fi kun pé àwọn àgbààgbà agbègbè wọn ní kí àwọn òbí rẹ̀ ra màálù, kí wọ́n pe àpèje àmọ́ tí àwọn òbí ọmọ náà kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Ó ní èyí ló mú káwọn èèyàn agbègbè ọ̀hún máa dúnkokò mọ́ ọmọ náà láti ìgbà náà.
"Ní ilé ẹjọ́ lónìí, Adájọ́ A. O. Olorunfemi tẹ̀lé ìmọ̀ràn ẹ̀ka Director of Public Prosecutions tí iléeṣẹ́ ètò ìdájọ́ ìpínlẹ̀ Eko, tí wọ́n sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé kò sí ẹ̀rí láti fìdí ẹ̀sùn olè jíjà tí wọ́n fi kan Quadri Alabi múlẹ̀.
"Eyí ló sì jẹ́ kí adájọ́ fi ní kó máa lọ sílé láyọ̀ àti àlááfíà."
Effiong wá kan sáárá sí DPP fún dídúró lórí òdodo lórí ọ̀rọ̀ ọmọ náà.
Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀sùn ìjà ìgboro ni wọ́n fi kọ́kọ́ kan ọmọ náà, ó ní ẹ̀sùn ìdigunjalè làwọn ọlọ́pàá gbé lọ sílé ẹjọ́ lọ́jọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kìíní, odún 2025.
Ó ní láti ìgbà náà ló ti wà ní àhámọ́ pẹ̀lú àwọn àgbàlagbà mẹ́rin mìíràn tí kò mọ̀ rí, tí wọ́n sì tún parọ́ ọjọ́ orí rẹ̀ pé ó tip é ọmọ ọdún méjìdínlógún.
Effiong wá pè fún fífi ojú àwọn ọlọ́pàá, pàápàá DPO Amukoko àtàwọn ọlọ́pàá míì tó wà nídìí ìṣẹ̀lẹ̀ ọmọ náà winá òfin.
Ó ní kí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ náà, kí wọ́n sì san owọ gbà mábinú ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù náírà fún-un.