Ìjàmbá iná sọ nílé aṣòfin Kogi,Ìjọba ṣèlérí pé àsírí òkùnfà iná náà yóò jáde láìpẹ́

Kingsley Fanwo kọmiṣana feto iroyin nipinlẹ Kogi ti n tan imọlẹ si iṣẹlẹ ina to ṣẹyọ nile aṣofin ipinlẹ naa.

Ninu atẹjade kan to fi sita ni alaye yi wa.

Kingsley Fanwo fi sita sọ pe idaji ni ina naa sọ,atipe awọn onimọ ti n ṣiṣẹ lori iwadii lati mọ ohun gan to ṣokunfa ijamba ina naa.

Atẹjade naa tun jẹ ko di mimọ pe ọpọ dukia olowo iyebiye at’awọn lo ba ijamba ina naa lọ.

Ijọba ipinlẹ Kogi to sọ ọ ninu atẹjade naa pe oun yoo kede abajade iwadii naa fawọn eeyan ipinlẹ naa fi kun un pe eto ti n lọ lati wa aaye fun ijoko awọn aṣofin nipinlẹ naa lati rii daju pe ofin ṣi f’ẹsẹ mulẹ nipinlẹ naa

Ìjàmbá ina jó ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Kogi ráú-ráú, bó ṣe ṣẹlẹ̀ rèé

Ina kan ti sọ ninu ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kogi, eyi to jo ile naa run, ti ọpọ dukia si ṣofo. Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, ko sẹni to tii le sọ ohun pato to ṣokunfa ina naa. Iroyin ni ina ọhun, to bẹrẹ ni nnkan bii aago meje si mẹjọ aarọ ọjọ Aje jo gbogbo ile igbimọ aṣofin naa kọja ala. Agbẹnusọ ile naa, Mathew Kolawole, sọ fun awọn akọroyin pe awọn agbofinro yoo ṣe iwadii ohun to ṣokunfa rẹ lai fi akoko ṣofo. O fi kun pe iṣẹlẹ naa ko ni dawọ iṣẹ awọn gẹgẹ bii aṣofin duro, paapaa ohun ti wọn fẹnuko le lori ileeṣẹ Dangote Cement Plc.