You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ta ni ọmọ ẹ̀lẹ̀ yìí, Olorì Tobi Phillips tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ ààfin Ooni Ife?
Kìí ṣe ohun tuntun nílẹ́ Yorùbá pé kí Ọba ní olorì púpọ̀, ohun àtayébáyé ni tí èyí kò sì yọ àwọn Ọba òde òní sílẹ̀.
Ní Ile Ife, ààfin Arole Oduduwa ni Olódùmarè ti ń ṣọlá rẹ̀ báyìí pẹ̀lú fífi àwọn ayaba tó jojú nígbèsè dá Ọọni lọ́lá.
Ẹ ó rántí pé nínú oṣù Kejìlá ọdún 2021 ni olorì Silekunola Naomi kéde lórí ayélujára pé ìgbéyàwó òun àti Ọọni ti túká.
Láti ìgbà náà ni àwọn ènìyàn ti ń fojú sọ́nà lórí wí pé ta ni yóò jẹ́ olorì tuntun ní ààfin.
Kò pẹ́ kò jìnà, Ọọni Ogunwusi gbé Mariam Anako níyàwó gẹ́gẹ́ bí olorì tuntun nínú oṣù Kẹsàn-án.
Ní báyìí ó jọ wí pé Ọọni kò ì tíì dáwọ́ dúró pẹ̀lú bí àwòrán tuntun ṣe n gbòde pé àwọn olorì míì yóò tún wọ ààfin, ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí, ìròyìn ti jáde pé olorì Tobi Phillips náà tún ti wọ ààfin.
Ta ni Tobi Phillips?
Ní ọjọ́ Ẹtì ọjọ́ Kẹsàn-án oṣù Kẹwàá ni Olorì Tobi Phillips wọ ààfin Ọọni Ile Ife, Ọba Enitan Ogunwusi Ọjaja II gẹ́gẹ́ bí olorì tuntun.
Tobi Phillips ni olorì kejì tí yóò wọ ààfin Ọọni láàárín oṣù kan síra wọn lẹ́yìn tí Ọọni gbé Olorì Mariam Anako níyàwó nínú oṣù Késàn-án.
Ọmọ bíbí ìlú Erinje-Ikale ní Okitipupa ní ìpínlẹ̀ Ondo ni Tobi Phillips.
Ní ọdún 2013 ni Tobi kẹ́kọ̀ọ́gboyè nínú ìmọ̀ nípa sáyẹ́ǹsì orí omi (Marine Science) ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ìlú Eko, UNILAG.
Iṣẹ́ aṣọ rírán, títá àti ṣíṣe ara ní ọ̀ṣọ́ tó fi mọ́ oge ni Tobi yàn láàyò kó tó di wí pé ó di olorì láàfin Ọọni.
Òun ló ni iléeṣẹ́ gbajúgbajà aránsọ QTP Luxury Fashion tó sì ti ń ránṣọ ìgbàlódé láti ọdún 2018.
Yàtọ̀ sí aṣọ rírán Tobi jẹ́ arìnrìn oge láti ìgbà tó ti wà ní ilé ẹ̀kọ́.
Nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan tí Tobi ṣe pẹ̀lú iléeṣẹ́ ìròyìn Blueprint lọ́dún 2014, ó ní ọdún 2009 ni òun ti bẹ̀rẹ̀ sí ní rin ìrìn oge nígbà tí òun ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ ilé ẹ̀kọ́.
Ó ní gbígbégbá orókè níbi ìdijé omidan Madam Tinubu Hall ní ọdún 2009 ló ṣí ojú òun sí ohun tí òun ti ń gbèrò láti ṣe láti kékeré òun wá.
Ìrìn oge ti gbé Tobi dé orílẹ̀ èdè South Korea nígbà tó lọ ṣojú àwọn ilé ẹ̀kọ́ ilẹ̀ adúláwọ̀ níbi tó ti gba oyè omidan ilé ẹ̀kọ́ gíga ilẹ̀ adúláwọ̀ àgbáyé (World Miss University Africa).