You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Obìnrin tó pa ọ̀rẹ́ rẹ̀, kun-ún wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ nítorí ogún rí ẹ̀wọ̀n ọdún 34 he
Obìnrin kan tó pa ọ̀rẹ́ rẹ̀, kun òkú rẹ̀ wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ kó tó ko sínú àpò ti rí ẹ̀wọ̀n he.
Jemma Mitchell yóò ṣe ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n lọ́gbà ẹ̀wọ̀n fẹ́sùn wí pé ó pa Mee Kuen Chong, ẹni ọdún 67 ní ìlú London nínú oṣù Kẹfà ọdún 2021.
Nígbà tí adájọ́ ń gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀, ó ní bí Jemma ṣe pa ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó sì tún kun ún wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ ló jẹ́ kí òun fun ní iye ọdún náà.
Adájọ́ ní òun gbàgbọ́ wí pé Jemma kò ṣe òtítọ́ lórí ẹjọ́ náà
Ní ọjọ́ Ẹtì ni adájọ́ Richard Mark rán Jemma tó jẹ́ ẹni ọdún 38 lẹ́wọ̀n ní Old Bailey.
Mitchell ni apànìyàn àti obìnrin àkọ́kọ́ tí wọ́n yóò rán lọ sí ẹ̀wọ̀n tí wọ́n yóò gbé lórí amóhùnmáwòrán láti ìgbà tí òfin ti fàyè gba lílo ẹ̀rọ ayàwòrán ní ilé ẹjọ́ ní England àti Wales.
Adájọ́ Mark ní Jemma kò ti ẹ̀ ṣe bí ẹni wí pé òun jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án rárá bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ẹ̀rí tó wà níwájú òun ṣàfihàn pé ó jẹ̀bi ẹ̀sùn náà.
Àwọn onímọ̀ tó ṣe ìwádìí lórí òkú Chong kò lè sọ ní pàtó ohun tó fà ikú rẹ̀ nítorí bó ṣe ti jẹrà tó ṣùgbọ́n ìwádìí fi hàn pé wọ́n la nǹkan mọ lórí ni.
Bákan náà ni egungun ìhà rẹ̀ hàn wí pé ó ti kán nínú àpò tó ko sí.
Agbẹjọ́rò ìjọba ní Jemma ti ní èròńgbà láti pa opó ọ̀hún láti ìgbà tó ti ń ba ṣọ̀rẹ́ nígbà tí wọ́n pàdé ní ilé ìjọsìn kan.
Ó ní tí kò bá jẹ́ wí pé Jemma lọ́wọ́ nínú ikú obìnrin náà, kí ló fà á tó fi kun òkú rẹ̀ wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ tó sì tún lọ sọ́ òkú náà sí Salcombe.
Adájọ́ Mark ní ilé ẹjọ́ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Jemma ṣe ìwé ayédèrú láti fi jogún àwọn ilé ìgbé Chong èyí tí iye rẹ̀ tó £700,000.