You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Nnamdi Kanu yóò ṣì wà ní àhámọ́ DSS – Ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn
Ile ẹjọ Kotẹmilọrun ti paṣẹ ni ọjọ Ẹti lati da are fun ẹjọ kotẹmilọrun ti ijọba apapọ Naijiria pe lodi si idajọ ile ẹjọ giga to dá adari ikọ IPOB, Nnamdi Kanu lare ni ọjọ Kẹtala Oṣu Kẹwa.
Bakan naa ni adajọ Haruna Tsammani tun paa laṣẹ pe ki wọn fi abajade idajọ naa ranṣẹ si ile ẹjọ giga julọ fun gbigbọ kiakia.
Ki ni idajọ yii tumọ si fun Kanu?
Ohun ti eyi tumọ si ni wipe Ọgbẹni Kanu yoo ṣi wa ninu ahamọ ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ titi di igba ti ile ẹjọ giga yoo gbọ ẹjọ ti wọn fi ṣọwọ si ibẹ.
Ni ọjọ Kẹtala Oṣu Kẹwa ni ile ẹjọ Kotẹmilọrun dajọ pe Kanu ko jbi ẹsun ti ijọba apapọ fi kan an nile ẹjọ̀ giga to wa ni Abuja lori awọn ẹsun to nii ṣe pẹlu dida alafia ilu ru ati igbesunmọmi.
Ẹwẹ, igbimọ ẹlẹni mẹta ka ni ile ẹjọ Kotẹmilọrun wa sọ pe ile ẹjọ giga ṣalaini agbara lati fi ẹsun kan an lori bi ijọba ṣe gbe e lodi si ofin ti wọn si gbe e janto wa si Naijiria eyi to lodi si ofin mimu eeyan wọ orilẹede kan.
Ile tun ni awọn ẹsun kan ti wọn fi kan Kanu ko ṣe afihan ibi, ọ́jọ, akoko ati irufẹ ẹsun naa ki wọn to gbe e wọ Naijiria lodi si ofin eyi to si tasẹ agẹrẹ si ofin agbaye gedegbe.
Nitori ọna ati wa di itusilẹ Kanu lọwọ ni ijọba apapọ ṣe gba ọna pe ki wọn so idajọ naa rọ na titi ti esi nipa iwe ẹjọ Kotẹmilọrun yoo fi jade ni ile ẹjọ to ga ju lọ. Adajọ Tsanammi sọ ni ọjọ Ẹti pe iwe ẹri atako ti ikọ awọn agbẹjọro fun Kanu gbe wa lati tako ijọba lee ṣi eeyan lọkan.
Ẹsun dida alafia ilu ru
Ọpọlọpọ igba ni ẹgbẹni Kanu ti pe fun yiya kuro lara orilẹede Naijiria fun ekiri ero eeyan lati iha Guusu Naijiria lati orilẹede ti yio maa jẹ Republic of Biafra.
Ni Oṣu Kẹwa ọdun 2015, ijọba apapọ fi ofin gbe e lori ẹsun mọkanla ọtọọtọ to da lori igbesunmọmi, dida alafia ilu ru, didari ẹgbẹ ti ko lofin, agbejade ọrọ alufansa, kiko nkan ija oloro pamọ lọna aitọ́ to fi mọ kiko ọja wọle lai bofin mu atawọn nnkan mii.
Nigba to di inu Oṣu Kẹrin ọdun 2017, wọn da a silẹ lẹyin ti ikọlu kan waye si ile rẹ.
Ẹwẹ, Ọgbẹni Kanu sa kuro ni orilẹede nimu Oṣu Kẹsan lọdun 2017 lẹyin ti awọn ologun Naijiria ṣe ikọlu si ile rẹ ni Afara-Ukwu ni ẹba Umuahia, ipinlẹ Abia.
Nigba to ya ni awọn kan ri ni ilẹ Israel to si tẹsiwaju ninu kiko awọn alatilẹyin rẹ lorilẹ̀ẹede Naijria jọ ninu oniruuru ẹsun iwa ipa lati gbajọba ti wọn n ja fun. Ọpọlọpọ ẹsun ni ijọba ti ka si lọrun lati igba naa lara eyi to jẹ pe “o n da wahala silẹ lori ẹrọ amohunmaworan, rẹdio ati igbohunsafẹfẹ ori ayelujara lodi si
Naijiria ati atawọn ileeṣẹ nla nla Naijiria”.
Minisita eto idajọ, Abubakar Malami sọ eyi lẹyin ti wọn tun fi ofin gbe Kanu lọdun 2021.
Bakan naa, wọn fi ẹsun kan pe “Kanu n da rugudu silẹ paapaa ni apa Ariwa-Guusu Naijiria eyi to ti fa adanu ẹmi ọpọlọpọ eeyan ati dukia awọn araalu, ologun, afaraj’ologun, ọlọpaa ati biba awọn ileeṣ nla nla jẹ to fi mọ awọn ami idamọ aṣẹ”
Si gbogbo eyi, ẹgbẹni Kanu ni ko si ootọ nibẹ, oun ko si jẹbi ẹsun kankan.