You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Nàìjíríà ló ń léwájú nínú àwọn ọmọ Yahoo tọ́wọ́ ọlọ́pàá Interpol ti tẹ̀ l'Africa
Ajọ Interpol ti fidi rẹ mulẹ pe o le ni eeyan ọọdọrun ti wọn jẹ afurasi onijibiti ayelujara ti ọwọ ti tẹ lorilẹede Afrika fun ẹsun lilu jibiti.
Interpol ṣafihan orilẹede ilẹ Afrika meje ti awọn ọdaran ti n ṣiṣẹ, ti awọn alaṣẹ ilu si fun laṣẹ lati mu awọn afurasi mẹfalelọọdọrun
Gẹgẹ bii Interpol ṣe ṣalaye, iwadii wọn lo da lori awọn afurasi ti wọn n lu awọn eeyan jibiti pẹlu ileeṣẹ ifowopamọ ori ayelujara, ti wọn siti lu eeyan 1,500 ni jibiti.
"Iwadii Operation Red Card ni a fi mu awọn eeyan yii, bẹrẹ lati oṣu kọkanla ọdun 2024 si oṣu keji ọdun 2025, ẹyi ni a gbe kalẹ lati fopin si lilu awọn eeyan to wa ni orilẹede mii ni jibiti, eyi to n ṣe ọpọ akoba fun idokowo.
"Awọn agbofinro lorilẹede ilẹ Afrika meje naa ni wọn ti mu to eeyan mẹfalelọọdọrun, ti wọn si tun gba ọpọ ẹrọ ti wọn n lo fi ṣe iṣẹ yii lọwọ wọn.
Awọn orilẹede fun iwadii Operation Red Card ni Benin, Côte d'Ivoire, Nigeria, Rwanda, South Africa, Togo ati Zambia.
Orilẹede Nigeria ni ọwọ ti tẹ ọpọ afurasi ju, ti Rwanda, South Afrika ati Zambia si tẹle.
Wo orilẹede ati iye afurasi ti ọwọ Interpol tẹ
Nigeria
Fun orilẹede Naijiria, Interpol ni ọwọ tẹ eeyan 130 to fi mo 113 ọmọ ilẹ okeere lori ẹsun lilu eeyan jibiti ori ayelujara.
Bẹẹ ba be, ajọ EFCC kede pe awọn ṣawari ẹgbẹ kan ti ọpọ wọn jẹ oyibo jẹ ọmọ ẹgbẹ naa ti wọn n lu awọn eeyan ni jibiti Yahoo-Yahoo lorilẹede Naijiria.
Iṣẹlẹ yii lo waye ninu oṣu kejila ọdun 2024.
Bakan naa, EFCC ni awọn oyibo ti ọwọ tẹ naa ni awọn n gba awọn ọdọ Naijiria si iṣẹ, fun wọn ni ẹrọ ayarabiaṣa ati foonu, koda wọn si oju opo ayelujara fun wọn lati ma lu awọn eeyan ni jibiti.
Interpol ni "Ọmọ orilẹede Naijiria ti ọwọ tẹ lo jẹ 130, to fi mọ 113 ọmọ okeere, ti wọn lọwọ ninu iṣẹ jibiti naa."
Interpol ni awọn afurasi naa n gba awọn eeyan si iṣẹ lati ọpọ orilẹede Naijiria lati ma ba lu awọn eeyan ni jibiti.
Wọn fikun pe pẹlu iwadii, wọn gba ọkọ ayọkẹlẹ mẹrindinlọgbọn, ile mẹrindinlogun, ilẹ mọkandinlogoji ni Naijiria.
Rwanda
Lasiko iwadii naa, awọn agbofinro ilẹ Rwanda mu eeyan marundinlaadọta ti wọn n se iṣẹ jibiti, ti wọn si ri ọpọ ẹgbẹrun dọla gba pada lọwọ wọn.
Interpol ni awọn agbofinro mu ikọ awọn afurasi ọdaran lẹyin ti wọn lu eeyan kan ni jibiti owo to le ni $305,000 ni ọdun 2024.
South Africa
Ni orilẹede South Africa, Interpol mu eeyan ogoji ti wọn n se iṣẹ , ti wọn si n fi ipe agbaye lu awọn eeyan ni jibiti.
O le ni ẹgbẹrun simmu ti wọn gba lọwọ awọn afurasi naa ti wọn fi n se iṣẹ ibi naa.
Zambia
O to eeyan mẹrinla ti wọn mu lorilẹede Zambia ni wọn n lo ọna eburo wọ ori foonu awọn eeyan.
Awọn afurasi yii ni wọn n lọ atẹjisẹ ayederu, to jẹ pe ti awọn eeyan ba ti ka atẹjisẹ naa tabi tẹ linki to wa ninu rẹ, appu kan yoo wọ ori foonu wọn.
Eyi ni ọna ti awọn afurasi naa n lo lati se ijamba fun awọn eeyan nipa wiwọ ori ile ifowopamọ wọn lori ayelujara.