Awakọ̀ bàálù kú lásìkò tó ń wa bàálù láti US lọ sí Turkey

    • Author, Paul Kirby
    • Role, BBC News
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Awakọ baalu kan to jẹ ti Turkish Airlines ti padanu ẹmi rẹ lẹyin ti aisan deede kọluu lasiko to n wa baalu lati ilu Seattle to wa ni apa ariwa ilẹ Amẹrika lọ si ilu Istanbul ni orilẹede Turkey.

Ilcehin Pehivan, ẹni ọdun mọkandinlọgọta, lo deede ṣubu lasiko to n wa baalu, ti akẹgbẹ si ni lati gba akoso wiwa baalu naa - agbẹnusọ ileeṣẹ baalu naa ṣalaye loju opo ayelujara.

“Nigba ti itọju pajawiri ninu baalu ko sisẹ, awọn akẹgbẹ awakọ baalu ni lati baalẹ ni kiakia sugbọn o ti jade laye ki wọn to balẹ,” Yahya Ustun ṣalaye.

Ọkọ baalu Airbus A350 lo balẹ siluu New York, ti wọn si n gbero lati ko awọn eeyan lọ si ilu Turkey lati ibẹ.

Wọn gbera lati Seattle ni aago meje alẹ ni ọjọ Iṣẹgun. Kudiẹkudiẹ ba ilera awakọ baalu ni agbegbe Canada, Nunavat ki wọn akẹgbẹ rẹ to balẹ si paapa ofurufu John. F Kennedy.

Lati ọdun 2007 ni Pehivan ti n wa ọkọ baalu Turkish Airlines, to si jẹ ninu oṣu Kẹta, lo ṣe ayẹwo ara rẹ, ko si si nnkan to se ara rẹ ti o le se akoba fun iṣẹ rẹ.

Ajọ to n risi ọkọ ofurufu lorilẹede Turkey, TATCA ti ransẹ ibanikẹdun si awọn mọlẹbi ati awọn akẹgbẹ oloogbe naa.

Bo ti lẹ jẹ pe wọn ko ti i sọ ohun patọ to ṣokunfa iku oloogbe naa.

Irufẹ iṣẹlẹ yii waye ni ọdun 2015 nigba ti awakọ baalu, ẹni ọdun mẹtadinlọgọta kan sadede subu, to si gba ibẹ ku lasiko to n wa baalu lati Phoenix lọ si Boston.