You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mọ̀ nípa àwọn àǹfààní tó wà nínú Kùnú mímu
Kunu ki i ṣe nnkan mimu lasan, ọkan lara awọn nnkan ajogunba Naijiria tawọn eeyan n mu kaakiri agbegbe ilẹ yii ati ni awọn ilu to sunmọ Naijiria ni.
Kunu ladun, wọn maa n fi jero ṣe e, wọn n lo agbado, irẹsi ati ohun ti a mọ si sorghum lede oyinbo.
Oriṣi Kunu kọọkan lo ni adun tirẹ, eyi da lori ohun ti wọn ba fi ṣe e.
Awọ Kunu mi-in yoo da bii yẹpẹ ilẹ, awọn mi-in aa si funfun lẹlẹ bi wọn ba fi jero, irẹsi tabi agbado ṣe wọn.
Kunu ṣiṣe ko ṣoro rara, jero ni ọpọlọpọ eeyan fi maa n ṣe e ju ni Naijiria. Oriṣi jero ti wọn n lo maa n yatọ sira wọn ṣaa nigba mi-in.
Dokita Saadatu Sulaiman to jẹ agbaọjẹ ninu imọ nipa ounjẹ, ṣalaye pe ipa pataki ni Kunu n ko laye awọn eeyan ni Naijiria.
Kunu ti di ounjẹ fun ọpọ eeyan to n gbadun rẹ laaarọ, paapaa nigba ti wọn ba fi akara, mọin-mọin tabi masa mu un.
Bi o ba fi Kunu mimu bẹrẹ ọjọ rẹ, afaralokun ni, yatọ si pe dun pẹlu awọn nnkan ti eeyan le fi mu Kunu naa.
Anfaani to wa lara Kunu
Anfaani pọ lara Kunu, eyi ri bẹẹ nitori ounjẹ onikoro ti wọn fi n ṣe e, ati awọn eroja mi-in to wa ninu rẹ.
Dokita Sulaiman ṣalaye pe awọn eroja bii fiber, protein, ọra to daa fun ara ( healthy fat), iron ati folate wa ninu Kunu.
O ni o maa n ṣeranwọ fun bi ounjẹ yoo ṣe tete da ninu eeyan, o n fun ara lokun, o si maa n gbe awọn ṣọja ara duro.
Bakan naa ni Kunu tun wulo fun alaafia inu bi Dokita Sulaiman ṣe sọ.
Bi Kunu yoo ṣe ṣiṣẹ lara eeyan to, da lori iru ounjẹ onihoro ti wọn fi ṣe e.
*Kunu ti wọn fi jero ṣe, ni awọn eroja fiber ati afaralokun, to ṣe pataki fun ipese ẹjẹ pupa lara.
*Kunu ti wọn fi Fonio ṣe (awọn mi-in n pe Fonio yii ni acha) wulo fun ki ṣuga ma pọju ko si ma ṣe aito ninu ara. Bakan naa lo n pese eroja protein sinu ara.
*Kunu ti wọn fi Sorghum ṣe, ni eroja protein, fiber, iron, ati magnesium ninu. Kunu onisorghum yii lo n fun ara ni protein ju awọn yooku lọ.
* Kunu ti wọn fi irẹsi ṣe maa n kúnná daadaa, o si maa n dun. Bẹẹ lo ni eroja afaralokun ti a mọ si carbohydrates ninu.
Kunu ti wọn fi ẹpa ṣe, ni ororo to daa fara ninu, bakan naa lo ni eroja protein to daa f''ara to si daa keeyan fi ṣe ounjẹ aarọ.
Kunu ti wọn fi Moringa ṣe, ni eroja fitamin A, C, ati E ninu. Pẹlu ohun ti a mọ si antioxidants to maa n ran awọn ṣọja ara lọwọ (support immune system).
Gẹgẹ bi Dokita Sa'adatu ṣe wi, o ni Kunu jẹ ounjẹ kan ti eeyan le sare lo laaarọ nigba ti oju ba di pẹlu iṣẹ. O ni o maa si maa n jẹ ki omi wa lagọ ara eeyan bo ṣe yẹ.
Awọn ohun to wa ninu Kunu ti wọn fi Jero ṣe
Energy 365 Kcal
Carbohydrate 64.2g
Fiber 9.0g
Protein 9.3g
Fat 5.9g
Iron 15.2mg
Folate 160µg
Cholesterol 0mg
Sat Fat 0.96 g
Mono unsaturated fat 1.10g
Poly unsaturated fat 2.19g
Awọn ohun to wa ninu Kunu ti wọn fi Fonio ṣe
Energy 334 Kcal
Carbohydrate 59.7g
Fiber 16.4g
Protein 7.1g
Fat 3.8g
Iron 29.4mg
Folate 120µg
Cholesterol 0mg
Sat Fat 0.59g
Mono unsaturated fat 0.81g
Poly unsaturated fat 1.30g
Awọn ohun to wa ninu Kunu ti wọn fi Ẹpa ṣe
Energy 574 Kcal 574
Carbohydrate 17.4g
Fiber 8.3g
Protein 22.4g
Fat 44.2g
Iron 3.5 mg
Folate 110µg
Cholesterol 0mg
Sat Fat 8.92g
Mono unsaturated fat 20.64g
Poly unsaturated fat 12.72g
Awọn ohun to wa ninu Kunu ti wọn fi Soghum ṣe
Energy 342 Kcal
Carbohydrate 61.1g
Fiber 11.9g
Protein 11.5g
Fat 3.5g
Iron 6.8mg
Folate 64µg
Cholesterol 0mg
Sat Fat 0.48g
Mono unsaturated fat 1.16g
Poly unsaturated fat 0.86g