Wo kókó márùn-ún tó wà nínú ọ̀rọ̀ tí Tinubu sọ lórí yíyọ 'subsidy,' àbádòfin owó orí tuntun àti ìṣèjọba rẹ̀

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Aarẹ Bola Tinubu ti sọ pe oun o kabamọ lori igbesẹ toun gbe lati yọ owo iranwọ ori epo bẹntirolu kuro nigba toun gori aleefa gẹgẹ aarẹ orilẹede Naijiria.

Agogo mẹsan alẹ ọjọ Aje to kọja yii ni Aarẹ Tinubu sọrọ yii lasiko to n dahun awọn ibeere tawọn akọroyin n bi i leere lori eto iṣejọba rẹ.

Lasiko to n dahun oriṣiriṣi ibeere naa ni aarẹ ti mẹnuba ọrọ eto aabo, eto ọrọ aje, to fi mọ owo iranwọ ori epo bẹtiroolu to yọ kuro ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Wọnyi ni awọn koko aridimu pataki to wa ninu ọrọ ti aarẹ ba awọn ọmọ Naijiria sọ nigba to n dahun ibeere lati ọdọ awọn akọroyin niluu Eko:

Itẹra-ẹni-pa to ṣẹlẹ

Aarẹ Tinubu ba gbogbo mọlẹbi awọn to padanu ẹmi wọn ati awọn to farapa kẹdun, to si mẹnuba idi to fi ṣe pataki lati maa ṣaanu awọn eeyan.

"Ibanikẹdun mi lọ sọdọ mọlẹbi awọn to padanu ẹmi wọn, ṣugbọn o dara lati maa fifun-ni. Mo ti n pin ounjẹ fawọn eeyan ni Bourdinllon.

"Bi o ba mọ pe o ko ni nnkan to pọ lati fun awọn eeyan, ma ṣe polongo rẹ faraye."

Eto aabo

Aarẹ Tinubu mẹnuba ọrọ eto aabo, paapaa awọn iṣoro to n dojukọ eto aabo, ati aṣeyọri ti iṣakoso rẹ ti ṣe.

Nigba to n sọrọ, Aarẹ loun nigbagbọ ati afojusun rere ninu agbekalẹ eto aabo to wa nita lasiko yii, paapaa lawọn agbegbe ti eto aabo ti mẹhẹ lorileede naa.

"Lonii, mo nigbagbọ ninu agbekalẹ eto aabo ti mo ṣe," Aarẹ lo sọ bẹẹ

"O ṣeni laanu pupọ wi pe fun bi ogun ọdun sẹyin, a ti ri oriṣiriṣi ipaniyan. Mo ranti igba ti mo ni lati da eto ipolongo idibo mi duro, lati le ṣabẹwo ibanikẹdun si Maiduguri, Katsina, Kaduna ati Kogi.

"Lonii, ẹ le rin irin ajo lawọn opopona wọnyi, eyi ti ko ṣee ṣe tẹlẹ. Iṣẹ kan ṣoṣo lo gba lati dabaru eto agbegbe kan."

Yiyọ sọbsidi

Aarẹ Tinubu ko tun ṣai mẹnuba owo iranwọ ori epo rọbii to yọ danu lọjọ to gbọpa aṣẹ gẹgẹ bi aarẹ, leyi to ti da oriṣiriṣi awuyewuye silẹ ni Naijiria.

Aarẹ jẹ ko di mimọ pe ko sohun to le jẹ ki wọn tun pada sẹyin mọ lori owo iranwọ ori epo toun yọ danu, nitori pe ohun to ṣe pataki ni lati fi ọjọ ọla rere silẹ fawọn iran to n bọ lẹyin.

"Ọjọ iwaju wa ni a n na danu. Niṣe la n na ogun awọn iran to n bọ. A ko dokoowo,a ko tọju nitori ọjọ iwaju; niṣe la kan n tan ara wa jẹ lasan ni," Aarẹ fidi rẹ mulẹ.

Siwaju sii ni Aarẹ ṣalaye pe awọn igbesẹ naa 'se pataki pupọ fun orileede to ba ni afojusun rere fun ọjọ iwaju, to si ni pataki nnkan to le gbe eto ọrọ aje orileede duro niyẹn.

Owo ori fun eto ọrọ aje igbalode

Aarẹ jẹ ko di mimọ pe bi araalu ba fẹ ki eto ọrọ aje Naijiria maa figagbaga pẹlu ti awọn orileede to ti ni idagbasoke lagbaye, afi ki wọn bẹrẹ ofin owo ori tuntun.

O ni awọn ko le maa tẹsiwaju ninu awọn nnkan ti wọn n ṣe tẹlẹ lasiko yii.

Ninu ọrọ rẹ, o ni "Agbeyẹwo owo ori tuntun ti de lati duro. A ko le maa tẹsiwaju lati maa ṣe awọn nnkan ti a n ṣe ni ana mọ ninu eto ọrọ aje tonii."

Ipa rere ninu agbekalẹ

Aarẹ Tinubu ṣalaye awọn ipa rere to ni ki awọn araalu maa reti ninu agbekalẹ atunto rẹ, to si ni gbogbo eeyan ni yoo jẹ anfaani.

O rawọ ẹbẹ sawọn araalu lati ṣe suuru fun iṣakoso oun, ati pe gbogbo iṣoro ti araalu n dojukọ loun mọ nipa rẹ.

"Atunto maa n waye pẹlu inilara igba diẹ ni ṣugbọn ẹ ni lati mọ daju igba pipẹ ni awọn araalu yoo fi jẹ anfaani rẹ. Kii ṣe eyi ti yoo jẹ Eldorado fun gbogbo eeyan, ṣugbọn igba ọtun ti de bayii."