Àkójọpọ̀ iye ìgbà tí Ààrẹ Tinubu ti rìnrìnàjò ilẹ̀ òkèèrè lọ́dún 2024

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Kii ṣe ohun tuntun pe awọn Aarẹ orilẹede maa n rinrinajo kaakiri agbaye.

Lara awọn irinajo naa ni lati lọ ṣe ipade pẹlu awọn oniṣowo agbaye tabi awọn olori orilẹde mii fun itẹsiwaju orilẹede wọn.

Bola Tinubu, gẹgẹ bii awọn ojugba rẹ lagbaye, naa lọ ọpọ irinajo ninu ọdun yii si oniruru orilẹede fun oniruru idi.

Ninu iroyin yii, a gbiyanju lati ṣe akojọpọ diẹ lara awọn irinajo ti Aarẹ Naijiria, Bola Ahmed Tinubu lọ ninu ọdun yii.

Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kinni, ọdun 2024 ni Tinubu bẹrẹ awọn irinajo rẹ ninu ọdun yii to si sọ pe oun yoo pada wale laarin ọsẹ kinni, inu oṣu Keji.

Amọ ṣa, ọọfisi Aarẹ ko ṣalaye ni kikun ohun ti irinajo naa da le lori, eyii to mu ki ọpọ araalu gbagbọ pe kii ṣe iṣe ilu lo lọ ṣe nibẹ.

Nigba ti yoo di ọjọ kẹrinla, oṣu Keji ni Tinubu lọ si ipade ajọ African Union niluu Addis Ababa, lorilẹede Ethiopia.

Ipade pẹlu Emir Qatar

Nigba ti yoo di ipari oṣu naa, Tinubu lọ si Qatar, nilẹ Arab.

Gẹgẹ bii atẹjade lati ọọfisi Emir Sheikh Tamim bin Hamad Al Thani, Emir naa funra rẹ lo fi iwe pe Tinubu.

Irinajo lọ Senegal

Lọjọ kinni, oṣu Kẹrin, Tinubu rinrinajo lọ Senegal lati yọju si iburawọle Aarẹ tuntun ilẹ naa, Bassiropu Faye.

Tinubu lọ si ayẹyẹ naa gẹgẹ bii alaga ajọ ECOWAS.

Tinubu lọ si Netherlands

Nigba ti yoo di ọjọ kẹtalelogun oṣu kan naa, o lọ si Netherlands lati lọ ṣabẹwo si olootu ijọba orilẹede naa, Mark Rutte.

Nibi ipade ọhun ni wọn ti jiroro lori ibaṣepọ laarin orilẹede mejeji.

World Economic Forum ni Saudi Arabia

Lati Netherlands ni Aarẹ ti morile Saudi Arabia fun ipade ọrọ aje agbaye, World Economic Forum.

Nnkan bii ẹgbẹrun kan aadari orilẹede kaakiri agbaye lo pejọ sibi apero naa to waye niluu Riyadh.

Iburawọle ni Chad

Lọjọ kẹtalelogun, oṣu Karun un, ọdun 2024 ni Tinubu lọ sibi iburawọle Aarẹ Mahamat Déby ni Chad.

Ọpọ awọn olori ninu ijọba Tinubu lo tẹle lọ Chad fun iburawọle ọhun.

Iburawọle ni South Africa

Lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹfa, Aarẹ lọ si South Africa fun iburawọle Aarẹ orilẹede naa, Cyril Ramaphosa lẹyin to wọle saa keji.

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ati igabkeji rẹ, Obafemi Hamzat wa lara awọn to tẹle Aarẹ lọ ilẹ naa.

Ipade ajọ AU

Logunjọ oṣu Keje, Aarẹ Tinubu ọ si Ghana fun ipade ajọ AU to waye ni Accra.

Minisita fun ọrọ ilẹ okere, Yusuf Maitama Tugar lo ba Tinubu lọ si Ghana, ti aṣoju ijọba Naijiria nibẹ, Dayo Adeoye si pade wọn ni papakọ ofurufu.

Ọjọ mẹta ni Equatorial Guinea

Tinubu lọ si Equatorial Guinea fun ọjọ mẹta bẹrẹ lati ọjọ kẹtalata oṣu Kẹjọ.

Lara awọn nnkan ti oun ati Aarẹ ilẹ naa jiroro le lori ni irẹpọ laarin orilẹede mejeji ati ibaṣepọ nipa ọrọ aje.

Ileeṣẹ Aarẹ ra ọkọ ofurufu tuntun

Lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹjọ, Tinubu rinrinjo lọ si France ninu baluu tuntun.

Ọọfisi Aarẹ ni wọn ra baluu naa latari pe ọjọ ti lọ lori baluu ti ileesẹ Aarẹ n lo lati ọdun mọkandinlogun sẹyin.

Ipade pẹlu Aarẹ China pẹlu awọn riniajo mii

Lọjọ kọkandinlọgbọn, Tinubu lọ si China.

Nibi ipade naa ni oun ati Aarẹ Xi Jinping atawọn olori orilẹede mii ti jiroro.

China ni Aarẹ gba lọ silẹ Gẹẹsi nibi to ti lo ọjọ diẹ.

Ọpọ ipade mii ti Aarẹ tun lọ

Yatọ si awọn irinajo wọnyii, Aarẹ Tinubu tun lọ si UK, Saudi Arabia, Brazil, France ati South Africa ninu ọdun 2024.