You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ta ni Malcolm-Jamal Warner, òṣèré aláwọ̀ dúdú ọmọ ilẹ̀ America tó kú sínú òkun?
Bo tilẹ jẹ pe Malcolm -Jamal Warner ki i ṣe oṣere orilẹede Naijiria, ọpọ eeyan to mọ ọn lori amohumaworan lo ti n daro iku rẹ bo ṣe papoda lọjọ Aiku ọsẹ yii.
Ẹni ọdun mẹrinlelaaadọta (54) ni oṣere alawọ dudu ọmọ ilẹ America naa ko too jade laye.
Iroyin sọ pe Malcolm Jamal to kopa Theodore Huxtable ninu ere agbelewo, '' The Cosby Show'' ri sokun ni.
A gbọ pe isinmi ni oloogbe ati mọlẹbi rẹ lọ fun ni Costa Rica ti ijamba omi naa fi waye.
Gẹgẹ bi iroyin iku naa ṣe gbode, ni nnkan bii aago meji aabọ ọsan ọjọ Aiku, ogunjọ oṣu Keje ọdun 2025 ni Malcolm ni ki oun wẹ lodo.
Nibi to ti n wẹ iwe naa ni Playa Grande,nitosi ilu Cahuita Limón, Costa Rica, ni omi ti ru de lojiji, o si fa a Malcolm wọ agbami okun lọ.
Eyi to pada ja si iku rẹ.
Ikọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ Costa Rica, ṣalaye pe awọn eeyan to wa letikun lasiko ọhun gbiyanju lati ran Oloogbe lọwọ, ṣugbọn ajọ alagbelebuu pupa (Red Cross) to wa nibẹ fi ye wọn pe o ti ku.
Ta a ni Malcolm-Jamal Warner?
Ọmọ bibi New Jersey, l'America, ni Oloogbe Malcolm-Jamal Warner.
Ọmọ ọdun mẹsan-an pere lo wa to ti bẹrẹ si i kopa ninu awọn eto to le fi I han fun aye.
Ọdọkunrin ti ko ti i pe ogun ọdun lo wa to ti kopa bii ọmọkunrin kan ṣoṣo fun Bill Cosby ninu ere oniṣe to gbajumọ laaarin ọdun 1984 si 1992.
Ere naa ṣafihan awọn alawọ dudu ilẹ America ti wọn ko fẹẹ di atẹmẹrẹ lati ọdọ awọn alawọ funfun.
O si wa fun lati fi han pe bi oyinbo ṣe n tọju ọmọ rẹ ni alawọ dudu naa ko mu ọrọ obi ati idile ni yẹpẹrẹ
Bakan naa ni Malcolm tun maa n kọrin nigba aye rẹ.
Ọlọkan-o-jọkan ami ẹyẹ ni Oloogbe Malcolm Jamal gba fun ipa Theo to ko ninu Bill Cosby Show, o si tun gba ami ẹyẹ Grammy fun orin kikọ.
Ni 2015 lo gba ami ẹyẹ ẹni to daa ju nibi idije R&B, orin rẹ to pe ni "Jesus Children lo fi gba ami ẹyẹ naa
Bakan naa ni wọn tun fi orukọ rẹ ranṣẹ gẹgẹ bi ẹni to kọ ewi to daa ju ni 2023.
O tẹsiwaju ninu iṣẹ ere ori tẹlifiṣan, lara awọn ere to ti kopa ni "Touched by an Angel," "Community," "Key and Peele," "Suits," "Sons of Anarchy" ati "American Horror Story."
Lọdun to kọja, Warner fi eto kan to pe ni "Not All Hood", lọlẹ, afojusun rẹ lori eto naa ni lati maa ṣafihan ilẹ alawọ dudu ati ẹwa rẹ.
Oloogbe Warner gbe e kalẹ lati ṣoju awujọ alawọ dudu lori ayelujara ni.
Ṣugbọn pẹlu iku ojiji to pa a yii, ọpọ eeyan lo n ṣedaro Malcolm-Jamal-Warner to dagbere f'aye.