Ọkọ lu ìyàwò pa nìpínlẹ̀ Ogun nítorí pé kò yọ̀nda ilé ẹ̀kọ́ tó kọ́ fún-ùn

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti mu ọkunrin kan, Segun Ebenezer, fun ẹsun pe o lu iyawo rẹ Bukola pa.

Iroyin sọ pe Ọgbẹni Ebenezer lu iyawo rẹ pa nitori pe obinrin naa kọ̀ lati yọnda ile ẹkọ alakọbẹrẹ kan to kọ́ ni orukọ ara rẹ fun-un.

Gẹgẹ bi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe sọ ninu atẹjade kan lọjọ Aje, ọwọ tẹ arakunrin ọhun lẹyin to ti kọkọ salọ.

Fọnran ohun kan ti oloogbe Bukola ka silẹ lori foonu rẹ, to si fi ranṣẹ si ẹbi rẹ lo tu aṣiri pe ọkọ rẹ lo paa.

Obinrin naa ka oun ara rẹ silẹ lati jẹ ki awọn eeyan mọ pe ọkọ oun fi agadagodo lu u ni ori lasiko to n na oun.

O ni ti oun ba ku, o n fẹ ki wọn mọ pe ọkọ oun lo pa oun.

Awọn ọlọpaa sọ pe ni kete ti wọn fun ọkunrin naa ni fnran naa lati gbọ, lo salọ, ki ọwọ to o pada tẹ ẹ.

“Bi ileeṣẹ ọlọpaa nilu Kemta ṣe ri fọnran naa gẹgẹ bi ẹri, ni wọn bẹrẹ si ni tọpinpin ọkunrin naa, ki ọwọ to o tẹ ni abule Akinseku to salọ nilu Abeokuta.

“Iwadii ti a kọkọ ṣe fihan pe ija ti ma n waye ni ọpọ igba laarin oloogbe naa to kọ ile ẹkọ aladani kan ni orukọ ara rẹ, ati ọkọ rẹ to jẹ kafinta (carpenter).

“Ọkọ rẹ ọhun ti n gbiyanju lati gba iṣakoso ile ẹkọ naa lọwọ rẹ, amọ ti iyawo to jẹ akẹkọọjade fasiti kọ̀ jálẹ.”

Ọlọpaa ni nitori naa lo ṣe ma n lu u ni gbogbo igba, titi di ọjọ to fi agadagodo ti wọn fi n ti ilẹkun lu u ni ori, eyi to pada yọri si iku rẹ.

Kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankole ti paṣẹ pe ki wọn o gbe afurasi naa lọ si ẹka to n wadii iwa ọdaran, fun iwadii.