You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ sọ àwọn ọmọdé mílíọ̀nù mẹ́rin sínú àìrí oúnjẹ jẹ
- Author, Madina Maishanu
- Role, BBC News
- Reporting from, Katsina
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7
Ní ọjọ́ tí mo bá rí oúnjẹ, àwọn ọmọ máa lè jẹun àmọ́ ọjọ́ tí kò bá ti sí oúnjẹ, ọyàn nìkan ni wọn yóò máa mú títí. Èyí ni àwọn ni ọ̀rọ̀ tó ń jáde lẹ́nu Murja, ìyàwó ilé kan, ẹni tí ọjọ́ orí rẹ̀ ti lé ní ogún ọdún tó sì ní ọmọ méjì lọ́wọ́ tó ń tọ́jú.
Abúlé kan tó súnmọ́ ìlú Katsina ní àríwá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni Murja ń gbé. Láìpẹ́ yìí ni ó gba ọmọ oṣù méje, Ummi, tó jẹ́ ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tọ́ lẹ́yìn tí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ náà jáde láyé. Láti ìgbà náà lọ ti ń làkàkà láti tọ́jú àwọn méjéèjì. Murja ní èyí tó jẹ́ àgbà nínú àwọn ọmọ náà ti ń gbìyànjú láti rìn tẹ́lẹ̀ àmọ́ oúnjẹ tí kò rí jẹ́ kánú ti dènà ìgbésẹ̀ náà.
Ní àárín igbó kan ni ilé wọn tí wọ́n fi amọ̀ kọ́ wà tí kò sì sí iná mọ̀nàmọ́ná níbẹ̀. Kò sí ibi tí atẹ́gùn ń gbà wọlé tàbí jáde tí gbogbo ibẹ̀ sì ń gbóná. Oúnjẹ kékeré ni Murja máa ń rí jẹ ní ẹ̀ẹ̀kan lójúmọ́ léyìí tó ti mú àdínkù bá omi ọyàn rẹ̀.
“Ó jẹ́ ohun tó máa ń bàmí lọ́kàn jẹ́ nígbà tí mo bá rí àwọn ọmọ míì tí wọ́n tóbi, tí àláfíà wọn tún pé àmọ́ Ummi kàn ń kéré si ní ojoojúmọ́,” ó sọ.
Àìsí oúnjẹ tó ṣara lóore
Bí àìrí oúnjẹ jẹ ṣe ń pọ̀ si ní àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́fà ní ẹkùn àríwá Nàìjíríà jẹ́ ohun tó burú jáì. Ẹ̀ka tó ń rí sí ọ̀rọ̀ oúnjẹ lábẹ́ àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé ní àwọn ọmọdé tí ọjọ́ orí wọn kò ì tíì pé ọdún márùn-ún ti iye wọn tó mílíọ̀nù 4.4 àtàwọn olóyún tí iye wọn súnmọ́ 600,000 ni ebi ń dà láàmú.
Gẹ́gẹ́ bí WFP ṣe sọ iye àwọn ọmọdé tí wọn kò rí oúnjẹ jẹ ti lékún ní ìdá ọgọ́rùn-ún láàárín ọdún tó kọjá sí àsìkò yìí.
Adarí Médecins Sans Frontières’s, Catherine Van Overloop ní àwọn ọmọ tí kò rí oúnjẹ tó ṣara lóore jẹ ní ẹkùn àríwá ni iye wọn ti lékún ní ìlọ́po méjì.
“Àwọn ọmọdé yìí ni ó ṣeéṣe kí wọ́n má dàgbà bí ó ṣe yẹ,” ó ṣo bó ‘se ń ṣàlàyé àwọn ipa tó le ní lórí àwọn ọmọ náà.
“Wọ́n le má ga tó bó ṣe yẹ kí wọ́n ga dé, ọpọlọ wọn le má dàgbà tó bó ṣe yẹ, wọ́n le má ríbi kẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́, àwọn ọmọdé yìí sì ni ọjọ́ ọ̀la Nàìjíríà.”
Kí ló fà á?
Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ń kojú àìsí oúnjẹ tó péye lásìkò yìí. Àpapọ̀ èèyàn mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ni wọn kò ní oúnjẹ láàárín oṣù Kẹwàá sí oṣù Kejìlá ọdún 2023. Iye yìí ni wọ́n ní àlékún máa bá ní oṣù Kẹfà sí oṣù Kẹjọ ọdún 2024 gẹ́gẹ́ bí ìwádìí WFP ṣe sọ.
Àmọ́ ẹkùn àríwá Nàìjíríà ni ìṣòro náà ń bá fínra jùlọ. Àwọn iwá ipá àti làásìgbò tó máa ń wáyé ní gbogbo ìgbà wà lára àwọn nǹkan tó ń fa ebi.
Láti bíi ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn ni ẹkùn ìlà oòrùn àríwá Nàìjíríà ti ń kojú ìṣòro Boko Haram àti ISIS. Ikọ̀ yìí ti pa ọ̀pọ̀ èèyàn, tí wọ́n sì ti mú kí ọ̀pọ̀ fi ilé wọn sílẹ̀ láti sálọ sáwọn ìlú mìíràn àtàwón orílẹ̀ èdè tó súnmọ́ Nàìjíríà bíi Niger, Chad àti Cameroon.
Báwọn ọmọ ogun ṣe ń kojú ikọ̀ Boko Haram, làásìgbò tó ń wáyé láàárín àwọn àgbẹ̀ àtàwọn darandaran ti di ohun tí àwọn èèyàn kò bọ̀wọ̀ fún òfin mọ́ lórí rẹ̀.
Láti nǹkan bíi ọdún mẹ́jọ báyìí ni àwọn ọ̀daràn kan ti ń kó ara wọn jọ èyí tí àwọn èèyàn ń pè ní agbébọn, tí wọ́n sì ń jí àwọn èèyàn gbé láti fi gba owó. Ọ̀pọ̀ àwọn àgbẹ̀ àti darandaran ni wọ́n ti sá kúrò nílé wọn.
Àyípadà ojú ọjọ́ tó ń bá gbogbo àgbáyé fínra náà ń ṣàkóbá fún èrè oko àti àsìkò tó yẹ kí àwọn àgbẹ̀ fi gbin oúnjẹ.
Ọ̀wọ́n gógó gbogbo nǹkan tó ń bá Nàìjíríà fínra látàrí bí iye owó oúnjẹ àti epo ṣe ń gbówó lórí ń mú kó ṣòro fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti rí oúnjẹ jẹ bó ṣe yẹ.
Dída ẹkùn ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà rú
Àwọn onímọ̀ ní ètò ààbò tó mẹ́hẹ àti oúnjẹ tó ń di ọ̀wọ́n gógó ní ẹkùn àríwá Nàìjíríà le ní ipa lórí àwọn orílẹ̀ èdè tó súnmọ́ Nàìjíríà ní ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà.
Wọ́n ní ó le mú àlékún bá àìsí oúnjẹ káàkiri àwọn orílẹ̀ èdè ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà, tó lè mú kí àwọn èèyàn máa kúrò ní ilé wọn tó sì lè mú àlékún bá àìsí ètò ààbò tó péye.
Bulama Bukarti tí Extremism Policy Unit of the Tony Blair Institute ní àwọn àjọ ẹlẹ́yinjú àánú nílò láti mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kó má tùn-ún pọkún àwọn ẹ̀ka mìíràn bíi ètò ìlera.
Àwọn àjọ ẹlẹ́yinjú àánú bíi Médecins Sans Frontières (MSF) ṣèkìlọ̀ pé owó tó wà láti fi máa dásí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni kò sí mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀.
Ẹ̀ka tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọdé ní àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé (Unicef) ti mú àdínkù bá àwọn ìjọba ìbílẹ̀ tí wan ń pèsè àwọn ohun ìtùnú fún láti mẹ́tàlélógún di mẹ́rìnlá ní ìpínlẹ̀ Katsina bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní àwọn ṣì ń gbìyànjú láti túnbọ̀ ṣe ìkówójọ si.
Àwọn agbébọn ti gba gbogbo nǹkan wa
Ṣáájú ni BBC ti ṣe ìròyìn nípa ipa tí àìsí ètò ààbò àti àìtẹ̀lé òfin ní ẹkùn àríwá Nàìjíríà ń ní lórí èèyàn.
Jamila, ẹni tó jẹ́ àgbẹ̀ nígbà tó ń bá BBC sọ̀rọ̀ láti ibi ilé ìwòsàn MSF ní Katsina sọ pé àwọn agbébọn yabo ilé òun tí wan sì gba gbogbo oko tí òun ń dá.
Ní ọjọ́ díẹ̀ sẹ́yìn ni Jamila gbé ọmọ rẹ̀, Aliyu lọ sílé ìwòsàn náà lẹ́yìn tí ara rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní wú tí kò sì rí ìtọ́jú fún-un.
“A ò yàtọ̀ sí àwọn atọrọjẹ báyìí, àwọn agbébọn ti gba gbogbo nǹkan tí a ní. Ìgbé ayé tí mò ń gbé tẹ́lẹ̀ dára, a má ń tà lára èrè oko wa, tí àwa náà sì máa jẹ níbẹ̀.”
Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, gààrí ni Jamila, ẹni tó ní ọmọ mẹ́ta ń fi ń gbéra báyìí.
Bíi Jamila, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn Katsina tó jẹ́ àgbẹ̀ ni àwọn agbébọn ti lé kúrò lórí ilẹ̀ wọn, tí wọn kò sì ní iṣẹ́ kankan tí wọ́n fi ń gbéra mọ́.
Alhaji Abubakar tó ń gbé ní ilé àwọn aṣàtìpó pẹ̀lú ìyàwọ rẹ̀ mẹ́ta àtàwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́tàlélógún ní ọ̀pọ̀ oko àgbàdo, jéró, òwú àtàwón màlùú ni òun ní tẹ́lẹ̀ àmọ́ tí kò sí nǹkankan mọ́ lẹ́yìn táwọn agbébọn lé òun àtẹbí kúrò nílé.
Inú ilé kan ni gbogbo àwọn ẹbí náà ń gbé báyìí pẹ̀lú ilé ìgbọ̀nsẹ̀ kan. Ẹ̀ẹ̀kan lójúmọ́ ni wọ́n ń lè jẹun.
“Èmi tó jẹ́ pé mo máa ń fún àwọn èèyàn lóúnjẹ ti wá di ẹni tí wọ́n ń fi oúnjẹ ràn lọ́wọ́ le mú kí ọkàn mi pòruru.”
Inú ilé tó ń gbé ni ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tí wọn kò lè dúró nílé wọn mọ́ láti ìpínlẹ̀ Katsina ń gbé pẹ̀lú. Àjọ Smiling Heart Initiative International ní àìsí ìmọ́tótó tó péye ní àwọn ilé yìí ti mú àlékún bá àjákalẹ̀ àìsàn ibà, kọ́lẹ́rà àti títa.
Alhaji Abubakar ní inú òun yóò dùn bí ìjọba bá lè mójútó ètò ààbò kí àwọn le padà sí oko àwọn.
Dídènà ìjàmbá
Médecins Sans Frontières’s, Catherine Van Overloop láti lè mójútó làásìgbò yìí, ìjọba Nàìjíríà nílò láti gbé ìgbésẹ̀ akin láti pèsè oúnjẹ àti abẹ́rẹ́ àjẹsára.
“À ń bẹ̀bẹ̀ pé kí wọ́n tún ṣe ìpolongo lórí abẹ́rẹ́ àjẹsára,” ó sọ bí ó ṣe fi kun pé níní àǹfàní sí omi tó ṣe é bùmu bùwẹ̀ jẹ́ ọ̀nà kan láti fòpin sí àwọn àìsàn bíi ìgbẹ́ gbuuru àti títa láàárín àwọn ọmọdé.
Ó ní MSF ń bá àwọn iléeṣẹ́ tó ń rí sí ètò ìlera àti pé wọ́n ti gbé iks kan dìde tí yóò mójútó àwọn ìṣòro.
Àmọ́ igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Katsina, Faruk Lawal Jobe ní òun kò gbà pé àìrí oúnjẹ jẹ láàárín àwọn ọmọdé àtàwọn ìyá ń lékún si ní ìpínlẹ̀ náà.
Ó ní àwọn àgbéjádse tó látọ̀dọ̀ àwọn àjọ ilẹ̀ òkèrè kò sí ní ìbámu pẹ̀lú àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní ìpínlẹ̀ náà àti pé ìjọba àwọn ń gbé àwọn ìgbésẹ̀ tó yẹ láti kojú ìṣòro ètò ààbò àti àìsí oúnjẹ.
“A ti ń ra àwọn oúnjẹ oníkóró ta ma gbé kalẹ̀ fún àwọn àgbẹ̀ ní owó péréte. A ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ètò kan pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò níbi tí a ti tú bùba àwon agbébọn ká láti ri pé àwọn èèyàn padà sí oko.”
Iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà náà ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti fòpin sí àwọn ọ̀daràn ní agbègbè náà.
Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ológun, Ibrahim Ali Bukar ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní gbógúnti àwọn agbébọn láti lè ri pé àwọn àgbẹ̀ padà sí oko kí oúnjẹ le pọ̀ ní ìlú.
Ali Bukar ní òun kò lè sọ àwọn ìgbésẹ̀ tí àwọn ń gbé náà àmọ́ àwọn èèyàn yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní rí àyípadà láìpẹ́.
Àmọ́ fún àwọn ọmọdé tí ebi ń ṣọkọ fún bíi Ummi, ó ṣeéṣe kí àyípadà kankan má wáyé láìpẹ́, Murja ní òun kàn dáwà ni.
“Ohun tí mò ń fẹ́ ni pé kí àwọn ọmọ mi méjéèjì dàgbà nínú àláfíà, kí wọ́n sì ṣoríire lọ́jọ́ iwájú.”