Ìjọba àpapọ̀ bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti já owó gáàsì ìdáná wálẹ̀

Ijọba apapọ ilẹ Naijiria ti kọminu lori owo gọbọi ti araalu n ra gaasi idana, leyi to ti mu ki wọn gbe igbimọ kan kalẹ lati ṣeto bi owo ori gaasi idana yoo fi walẹ laarin ọsẹ kan ti ko si nii si idiwọ fun ipese rẹ.

Minisita abẹlẹ fọrọ epo rọbi (to n moju to ọrọ gaasi), Ekperikpe Ekpo, n lo ti da si awọn ipenija to n doju kọ ipese gaasi naa ati oye ti wọn n taa nigboro.

Oluranlọwọ lori eto iroyin fun minisita ọun, Louis Ibah, n lo wi pe bi owo kilo gaasi kan ṣe fo soke lati ẹẹdẹgbẹrin naira si ẹẹdẹgbẹrun naira bi oye to kere ju lawọn agbegbe kan lo mu ki minisita naa o da si ọrọ naa.

Iroyin fi ye ni pe owo ori kilo kan gaasi ti n ra baba laarin ẹgbẹfa naira soke lawọn agbegbe kan.

Ibah ṣalaye ninu atẹjade to fi sita pe, lara awọn koko to mu ki owo gaasi idana o jgbẹnusoke ni ọwọn gogo dollar ati bi awọn to n ta gaasi nigboro ko ṣe rii gba to latọwọ awọn to n pese rẹ.

Awọn lọgalọga nileeṣẹ iwapo bii Chevron, NMDPRA ati NNPCL lo peju sibi ipade ti minisita naa pe ni olu ileeṣẹ ajọ NNPC l'Abuja.

Minisita naa to woye pe Naijiria ni anito ati aniṣẹku alumọni gaasi wi pe bi awọn ileeṣẹ iwakusa gaasi ati epo rọbi ṣe mu ṣiṣu gaasi loṣuka lọ oke-okun lai ṣe ipese ti yoo kaju lilo rẹ nilẹ yi ni ko boju mu to.

Eyi lo mu ki minisita naa o gbe igbimọ kan dide ti ọga-agba ileeṣẹ NMDPRA, Farouk Ahmed, yoo jẹ alaga rẹ, lati wo saakun bi ipese gaasi lọpọ yanturu laarin ilu yoo ṣe waye laarin ọsẹ kan ti owo rẹ yoo si walẹ daadaa.