Àwọn ajínigbé ṣekúpa Pásítọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n gba N1m owó ìtúsílẹ̀

Olusọ aguntan ile ijọsin Evangelical Church Winning All, Pasitọ David Musa lo ti dero ọrun bayii lẹyin ti awọn ajinigbe gba milọnu kan naira, ti wọn dẹ tun ṣekupa.

Pasitọ yii lo bọ sọwọ awọn ajinigbe lọjọ kọkanla oṣu kọkanla ọdun 2023 ni agbegbe Obajana ni ijọba ibilẹ Lokoja nipinlẹ Kogi.

Ọkan lara ọmọ lẹyin Pasitọ yii ti orukọ rẹ n jẹ Mary salaye pe Pasitọ lọ sí oko lọjọ to bọ sọwọ awọn ajinigbe gbe yii, ti ko si pada wa si ile lasiko to yẹ.

"Iyawo Pasitọ lo pariwo síta pe oun ko ri ọkọ oun ni alẹ ọjọ naa, eyi lo jẹ ki awọn ara adugbo pẹlu awọn eeyan ile ìjọsin bẹrẹ si ni wa Pasitọ naa.

"Mo wa pẹlu wọn lọjọ naa. Awọn ajinigbe naa ba àwọn mọlẹbi Pasitọ sọrọ, ti wọn si bere fun ogun milọnu naira. Ile ijọsin ati Mọlẹbi ko ri owo naa, ti wọn si rawọ ẹbẹ si awọn ajinigbe naa pẹlu milọnu kan naira.

"Awọn ajinigbe yii sọ fun awọn mọlẹbi pe ki wọn mu awọn nnkan bí adiyẹ, ọtí ati awọn nnkan mii dani lọwọ.

"Nigba ti wọn dẹ sì ọdọ awọn ajinigbe, wọn rí Pasitọ wa laye. Awọn ajinigbe yii ni kí Pasitọ wa ati awọn meji to gbe owo wa ma lọ sí ile sugbọn wọn pe Pasitọ pada, ti wọn si yin ìbọn.

"Oku Pasitọ ni wọn gbe pada wa si ilu Obajana."

Agbẹnusọ ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Kogi, William Aya fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, to si jẹ ko di mimọ pe iwadi ti bẹrẹ lati sawari awọn ajinigbe naa ni kiakia.