You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn kéde àtúndi ìbò ní Zamfara, Ó ní ìbò tó gbé gómìnà Lawal wọlé kò parí
Ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn tó fi ìlú Abuja ṣe ibùjókòó ti ní ètò ìdìbò tó wáyé sípò gómìnà ní ìpínlẹ̀ Zamfara lọ́jọ́ Kejìdínlógún oṣù Kẹta ọdún 2023 lásìkò ètò ìdìbò gbogbogboò kò parí.
Níní ìfẹnukò àwọn adájọ́ ẹlẹ́ni mẹ́ta tí Adájọ́ Oyebisi Folayemi ṣaájú ní ìbò tó gbé gómìnà Dauda Lawal tẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP wọlé kò múna dóko.
Fún ìdí èyí, wọ́n ní àwọn wọ́gilé èsì ìbò náà.
Adájọ́ Sybil Nwaka tó ka ìdájọ́ náà síta pàṣẹ fún àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò Nàìjíríà, INEC láti ṣètò ìdìbò tuntun ní àwọn ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́ta ní ìpínlẹ̀ náà.
Wọ́n ní àwọn ibi tí ìbò náà ti ma wáyé ni àwọn ibi tí wọn kò ti dìbò tẹ́lẹ̀ àtàwọn ibùdó ìdìbò tí wọn kò ti ka ìbò wọn fún ìdí kan tàbí òmíràn.
Àwọn ìjọba ìbílẹ̀ tí àtúndì ìbò náà ti máa wáyé ni Maradu, Birnin-Magajji àti Bukkuyum.
Ilé ẹjọ́ ní kò tọ̀nà fún INEC láti fi èsì ìbò tí wọ́n rí lórí IreV nìkan láti fi kéde ẹni tó jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò.
Ìdájọ́ ọ̀hún ló ń wáyé lẹ́yìn tí olùdíje sípò gómìnà ìpínlẹ̀ Zamfara lẹ́gbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC tó tún jẹ́ gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ náà, Bello Matawalle pè tako ìjáwé olúborí gómìnà Lawal.
Ààrẹ Bola Tinubu ti yan Matawalle gẹ́gẹ́ bí Mínísítà kejì fétò ààbò.