"Pẹtiró tán nínú ọkọ̀ ojú omi tó ń gbé wa lọ Europe lórí òkun, èèyàn 300 pòórá - Èrò ọkọ̀"

"A to ogoje eeyan to gbera ninu ọkọ oju omi ni ọganjọ oorun ni bi aago meji ."

Doudou Diop, ẹni Ọgbọn ọdun lati orilẹede Senegal lo jade laye lasiko to n rin irinajo pẹlu ọkọ oju omi lọ ilẹ Europe, kilomita 1700 lati Senegal lọ ilu Canary niluu Spain.

Irinajo lori omi Atlantic ni o ti jẹ yọ ninu iroyin lẹnu ìjọ mẹta lẹyin ti ileeṣẹ kan tí ki ṣe tí ìjọba kede pe o to ọkọ oju omi mẹta to n gbe eeyan toto 300 to poora lati ìparí oṣu kẹfa.

"Mo rin irinajo lọ abule kan ti wọn n pe ni Kafountine, ní apa guusu Senegal ni bi ti a ti bẹrẹ irinajo."

"A ti fẹrẹ de Canary, o ku kilomita 500 nigba ti ọkọ oju omi wa sadede pana"

Ilu Kafountine yii jẹ ibi ti ọpọlọpọ maa n wa lọdọdun lati gbera lọ soke okun fun igbe aye gidi.

Mo salabapade Doudou Diop to joko si iwaju ile rẹ lasiko ti ojo n rọ, ti gbogbo obìnrin to jẹ mọlẹbi si yi ka.

"A gbera laisi wahala titi ta fi de Morocco.

"A ti fẹ de Canary, o ku kìilomita 500 nigba ti ọkọ oju omi wa saadede pana.

Epo tan lẹnu ọkọ oju omi naa laarin omi, ti a ko si le tẹsiwaju mọ."

O ni ijọba Morocco ko gbogbo wọn, ti wọn si gbe wọn lọ ilu Nouadhibou to sunmọ orilẹede Mauritania.

"Wọn gba orukọ wa ati idanimọ wa, wọn fi wa sinu ọkọ pada si Senegal.

O ti to ọsẹ kan ti wọn ti n wa, inu awọn mọlẹbi rẹ dun lati ri pada pẹlu alaafia.

O sokunkun boya wọn darakọ ọkọ oju to wa ninu ikede.

Bakan naa ni ìja bẹ silẹ laarin ìjọba Senegal ati ẹgbẹ awọn arin irinajo ti wọn n pe ni 'Walking Borders' lori eeyan to sọnu ninu omi.

Spain doola ẹmi eeyan 86, Morocco doola 260 ninu ọkọ oju omi

Oludasilẹ 'Walking Borders', Helena Maleno kesi awọn eeyan lọjọ kẹsan an oṣu keje pe oun ti kesi ìjọba orilẹede Spain, Mauritania, Morocco ati Senegal lati fọwọsowọpọ wa awọn eeyan to sọnu sodo.

Ìjọba orilẹede Spain dola ẹmi eeyan mẹrindinaadọrun ninu ọkọ oju omi tí wọn gbera lati Canary lọ wa awọn eeyan to sọnu.

Ẹka ìjọba to n risi ọrọ nípa orilẹede miiran fi atẹjade síta.

Maleno ni iwadii ni ko lẹsẹ nilẹ ati pe eeyan 260 ọmọ Senegal ni awọn doola ni Morocco lati ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹfa di ọjọ kẹsan an oṣu keje.

Lati ibẹ, ẹgbẹ 'Walking Borders' naa fi atẹjade sita pe awọn eeyan ti ìjọba Senegal kede pe awọn doola naa ni awọn eeyan to kuro lorilẹede Senegal.

Lọjọ kẹtala oṣu keje, ọkọ oju omi to n gbe arin irinajo mọkanlelogoji balẹ si Canary lati Senegal.

Osisẹ alaabo kan ni ọpọlọpọ awuyewuye tí n waye lori bi eeyan 300 ṣe poora

Nigba ti mo n ba awọn eeyan sọrọ, mo pade obìnrin kan ni Kafountine to ni eeyan kan wa ninu mọlẹbi oun to ru irinajo yii ni ko wale mọ.

Arábìnrin ọhun ti ko fẹ ka darukọ rẹ ni o ti pẹ́ ti oun ti gburo lati ọdọ aburo rẹ ọmọ ọdun mẹtadinlogun.

O da bi pe o wa ninu ọkọ oju mẹta naa "Ẹru n ba mi, a ko gbọ iroyin kankan nípa rẹ.

Osisẹ alaabo kan naa ni ọpọlọpọ awuyewuye lo tí waye lori bi awọn eeyan 300 ṣe poora

O ni " Lẹyin arábìnrin yii, ẹnikẹni ko ti wa sọ pe awọn n wa mọlẹbi wọn kan.

Ṣugbọn awọn eeyan kan n wa lati agbegbe miiran, ti wọn ko ki n se ọmọ abule yii.

Gẹgẹ bii ajọ agbeye ṣe sọ, o to eeyan 559 to padanu ẹmi wọn lọdun to kọja nítorí wọn gbinyanju lati lọ Canary lati Senegal.

Ati pe ninu oṣu mẹfa akọkọ ọdun yii, Canary ti gba alejo toto ẹgbẹrun meje.

"Gbogbo erongba mi ni ko wa si imusẹ"

Bi nnkan ṣe rí lo n mu ọpọlọpọ eeyan ma wa anfani lati wa igbeaye to rọnu.

Doudou n gbe gbogbo igbeaye reni apa guusu Casamance lorilẹede Senegal. Lẹyin iku Baba rẹ, o ni ẹru wa lori oun lati pese fun mọlẹbi gẹgẹ akọbi ọkùnrin.

"Mo fẹ igbeaye to dara, ọpọlọpọ owo lati tọju Iyawo, ọmọ mi obinrin, iya mi ati awọn mọlẹbi miiran " eyi ni ọrọ rẹ to si ni ijoko ninu ọkọ oju omi naa lo jẹ 400000 CFA(US682)

"Mo kuro lia sọ fun ẹnikẹni. Mo pinnu lati lọ Europe nitori ko si nnkan ni ibi bayi, n ko si ni nkankan.

"Iya n jẹ wa nibi, ko si isẹ, ko si iranlọwọ lati ọdọ ìjọba "

"O dun mi nitori mo fẹ lọ Spain, mo ni awọn ọrẹ nibẹ, ti wọn si n retí mi.

Niluu Kafountine, awọn ọdọ maa n kora wọn jọ labẹ ile. Bi awọn kan ṣe n tayo ni awọn miiran n sọrọ nípa oṣelu.

Gnara Diabang Ba jẹ ọkan lara igbakeji olori ati ọkan ọmọ ẹgbẹ oselu alatako.

"Kama parọ, o n bami lọkan jẹ pe a wa di ilumọka nitori bí awọn ṣe n wa gbogbo lati lọ ilẹ Europe.

"Gẹgẹ bii asofin, mo rí pe ẹtọ wa ni, ti a ba fẹ jẹ ki awọn ọdọ wa duro, a gbọdọ pese isẹ fun ati eto ẹkọ. Tí a ba ti kuna lati se eyi, a ti padanu.

David Diatta, ọmọ ẹgbẹ oselu kana pẹlu ọrọ rẹ to si fikun bí eto abo ṣe rí lasiko ṣe afikun si nnkan to n ṣẹlẹ.

Airi isẹ awọn ọdọ tí gbẹnu soke sì ida ogoji paapa pẹlu awọn akẹkọọ jade.

"Iya n jẹ wa ni bi bayi, ko si isẹ, ko si iranlọwọ lati ọdọ ìjọba " eyi ni ọrọ Ibrahima, ẹni ọdun mejidinlọgbọn ọmọ fasiti.

"Pupọ awọn ọrẹ mi lo ti ba ọkọ oju omi lọ Canary tí wọn sì ti se orire. A n rí wọn lorí ayelujara.

"O wumi lati lọ lọjọ kan sugbọn mo nilo owo."