You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìdí rèé tí ìgbìmọ̀ olùgbẹ̀jọ́ ìbò gómìnà Osun ṣé sún ìjòkó síwájú
Igbimọ to n gbẹjọ awuyewuye to tẹyin idibo Gomina ni ipinlẹ Osun ti sun igbẹjọ wọn to n lọ lọwọ si ọjọ mii.
Igbimọ kede pe ni ọjọ kẹtala oṣu Kẹwaa lawọn yoo joko lati gbẹjọ ibẹrẹpẹpẹ to jẹyọ latari awọn ẹsun ti Gomina Gboyega Oyetola fi tako ijaweolubori Ademola Adeleke ti ẹgbẹ oṣelu PDP.
Nibi ijoko igbimọ to waye ni ọjọ Iṣẹgun ni agbẹjọro Oyetola Lasun Sanusi ti sọ fun ileẹjọ pe awọn ti ṣeto gbogbo esi to yẹ tawọn si ti fi ṣọwọ ki ileẹjọ baa le ṣagbeyẹwo wọn.
O ni awọn ikọ agbẹjọro mejeeji ti fẹnuko lori asiko tawọn yoo fọrọ wa awọn ẹlẹri gbogbo lẹnu wo ki igbẹjọ naa ma ba pẹ ju bo ṣe yẹ lọ.
''Awa mejeeji ti gba pe ifọrọwanilẹnuwo ẹlẹri kọọkan ko yẹ ko ju iṣẹju marun un lọ .ẹrọ ifọrọwanilẹnuwo lati ọdọ ikọ keji naa ko si yẹ ko ju iṣẹju mẹwaa lọ.Ti awọn akọṣẹmọṣẹ ba si ni lati jẹri ti wọn naa, ko yẹ ko ju iṣẹju mẹẹdogun lakọkọ, ati ogun iṣẹju lẹẹkeeji tabi iṣẹju marun fun ibere akotan''
Bakan naa lo sọ fun igbimọ igbẹjọ pe awọn agbẹjọ ro mejeeji ti gba lati joko igbẹjọ laarin ọjọ Aje si ọjọ Ẹti .
Bẹẹ wọn lawọn gba pe ki wọn gbe gbogbo ẹri wa siwaju igbimọ ti o ba si ni eleyi ti atako wa fun, ki wọn ṣe igbẹjọ eleyi nigba ti idajọ yoo ba waye lori ẹjọ naa.
Ninu ọrọ tirẹ, agbẹnusọ ajọ INEC, Alex Izinyon ati agbẹjọro Adeleke Kehinde Ogunwumiju jẹri si pe awọn faramọ ilana akoko igbẹjọ ti agbẹjọro to pẹju mu wa.
A ni ẹlẹri to pọ lati mu wa-agbẹjọro Oyeleke
''Asiko ka maa mu ọrọ ti ko fẹsẹ rinlẹ lati fi da agbẹjọro lọna ti kọja bayi''
Ohun ti agbẹjọro Oyetola sọ ree to si ni awọn ko ni lo gbogbo asiko lati fi maa dahun si ọrọ tawọn agbẹjọro Adeleke ba mu wa.
O fi kun pe ''a ri eleyi gẹgẹ bi ọna lati maa fi ọrọ falẹ ṣugbọn esi to ba yẹ la maa fun wọn''
Lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ lyin ti igbimọ pari ijọko, agbẹjọro Sanusi(SAN) sọ gbogbo bi nkan ṣe waye ni ile ẹjọ lo tẹ oun lọrun ati pe ''a ni awọn ẹlẹri to pọ jadurata lati tẹsiwaju pẹlu ẹjọ yi niwaju igbimọ''
Asiko awọn igbẹjọ ibẹrẹ́pẹpẹ si ni ẹjọ yi wa bayii.
Ọjọ mẹrinla si ni wọn yoo fi ṣe abala igbẹjọ yi ki ẹjọ to bẹrẹ ni pẹrẹwu.
Ọjọ Kẹtala oṣu kẹwaa ni igbimọ sun igbẹjọ si.