''Allah kìí gba ẹran àgbò Sallah tí wọ́n bá fí owó olè rà ''

Onimọ nipa ẹsin Islam, Sheikh Tukur Jangebe ti ni ẹnikẹni to ba ji ẹran agbo gbe lo ni laada lọdọ Allah.

Sheikh ọhun sọ eyi lẹyin ti fidio kan ja ranyin lori ẹrọ ayelujara nibi awọn ọkunrin meji kan ti lọ ji ẹran ileya gbe.

Awọn ọkunrin mejeeji ọhun ni ọwọ tẹ ti wọn si wa ni panpẹ ọlọpaa.

Amọ ninu ọrọ rẹ, onimọ nipa ẹsin Islam naa tako ole jija to si ni Allah kii fun ẹnikẹni to ba ja ole owo tabi nkan miran ni oore kankan.

Ẹnikẹni to ba ji owo fi ra agbo fun Sallah n tan ara rẹ jẹ ni

O ni ẹnikẹni to ba ji owo to fi ra agbo fun Sallah n tan ara rẹ jẹ ni ko ni gba oore kankan lati ọwọ Ọlọrun.

Bakan naa lo ni ọjọ odun ileya ni wọn pa ẹran Sallah kii ṣe o ku ọjọ kan tabi ni alẹ.

Sheikh Tukur Jangebe tun rọ awọn eniyan lati maa ṣe ohun to tọ ni awujọ ki adura wọn ma ba ni idena.

Ọwọ́ tẹ afurasi olè méjì tó jí àgbò iléyá ní Ogun

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun ni ọwọ awọn titẹ ọkunrin afurasi meji ti wọn fi ẹsun kan pe wọn ji ẹran ileya ni ipinlẹ ogun.

Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa naa fi lede wọn ni Ọjọ Karun, Oṣu Keje yii ni awọn fi panpẹ ọba mu Adetunji Alagbe ati Opeyemi Ogunlokun lori ẹsun pe wọn ji ẹran agbo ileya.

Awọn wọnyii ni wọn fi panpẹ mu ni agbegbe Ogijo lẹyin ti arakunrin Sodiq Abolore salaye bi wọn ṣe ji ẹran ọhun gbe lọ.

Bi wọn se ji ẹran ileya gbe lọ re e…

Sodiq ni oun sun ni oun gbọ ẹsẹ girigiri ni nkan bi aago meje oru ti oun si wo oju ferese oun.

Lẹyin naa lo ripe ilẹkun onirin ti o de oju ọna ti oun gbe ẹran agbo ọdun Salah ọhun si ti ja lulẹ.

Eleyii mu ki o jade sita to si ni ẹran agbo to ra ni 120,000 naira pe ko si nibẹ mọ, to si bẹrẹ si ni wa kaakiri.

Asiko to n wa kaakiri naa lo ni awọn ọkunrin mẹta ti wọn n fi tipatipa ti ẹran agbo si inu ọkọ Mazda ti wọn wa gunlẹ.

Kete ni o fi igbe bọ ẹnu ti wọn sipe ọlọpaa, wọn ri meji mu ninu awọn mẹta naa pẹlu ẹran ileya ọhun, amọ ẹyọkan ninu wọn salọ.

Kọmisọnna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Lanre Bankole ni awọn mejeeji ti ọwọ tẹ naa ti wa ni panpẹ ọlọpaa bayii, ti iwadii si ti bẹrẹ ki wọn to gbe wọn lọ si ile ejo.