Ìyàwó, Bàbá àti ìyá Mohbad yọjú sílé ẹjọ́ láti sọ ohun tí wọn mọ nípa ikú rẹ̀

Ní ọjọ́rú, ọjọ́ Karùndínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹwàá ọdún 2023 ni ìgbẹ́jọ́ láti fìdí ohun tó ṣokùnfà ikú gbajúmọ̀ olórin tàkasúfèé nnì, Oladimeji Aloba tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Mohbad múlẹ̀, tún tẹ̀síwájú ní ilé ẹjọ́ gíga kan ní ìpínlẹ̀ Eko.

Ìyàwó Mohbad, bàbá àti ìyá rẹ̀ wà lára àwọn tó péjú sí ilé ẹjọ́ láti jẹ́rìí lórí ìgbẹ́jọ́ náà.

Wunmi Aloba, tó jẹ́ ìyàwó olóògbé náà kò ì tíì sọ ohunkóhun láti ìgbà tí ọkọ rẹ̀ ti papodà nínú oṣù Kẹsàn-án ọdún 2023.

Bákan náà ni kò fèsì sí gbogbo àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án pé ó mọ̀ nípa ikú ọkọ rẹ̀.

Ilé ẹjọ́ kò ní kí nọ́ọ̀sì, tí àwọn ọlọ́pàá ní ó jẹ́ afurasí gbòógì lórí ẹjọ́ náà, yọjú sí ilé ẹjọ́

Ní ọjọ́ Kẹtàlá oṣù Kẹwàá ni Adájọ́ Adedayo Shotobi sún ìgbẹ́jọ́ lórí ikú náà sí ọjọ́ Karùndínlọ́gbọ̀n tó sì ní kí Naira Marley, Primeboy àti Sam Larry yọjú síbi ìpẹjọ́ náà.

Adájọ́ náà ni kí àwọn ọlọ́pàá ri dájú pé àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta péjú pésẹ̀ sí ilé ẹjọ́.

Àmọ́ ilé ẹjọ́ kò ní kí nọ́ọ̀sì, tí àwọn ọlọ́pàá ní ó jẹ́ afurasí gbòógì lórí ẹjọ́ náà, yọjú sí ilé ẹjọ́.

Naira Marley àti Sam Larry ń kojú ìgbẹ́jọ́ fẹ́sùn pé wọ́n dúnkokò mọ́ Mohbad nígbà tó wà láyé.

Bákan náà ni kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Eko, Idowu Owohunwa ní Primeboy náà ní ẹjọ́ láti jẹ́ lórí ẹjọ́ náà nítorí àpá tó dá sí Mohbad lára nígbà tí ìjà dú wọn.

Mohbad bẹ̀rẹ̀ sí ní bì lẹ́yìn tí nọ́ọ̀sì fún ní abẹ́rẹ́ tán, DJ Mohbad ṣàlàyé fún ilé ẹjọ́

Ajisegiri Ayobami, ti a mọ si DJ ni akọrin takasufee to doloogbe, Ilerioluwa Aloba, t'awọn eeyan mọ sì Mohbad, ti sọ fun ile ẹjọ to n ṣe iwadii lori ohun to ṣe iku pa a.

DJ ni ṣe ni Mohbad bẹrẹ sí ni bi lẹyin ti nọọsi fun un ni abẹrẹ tan.

O ni gbogbo ounjẹ ti aburo rẹ, Adura Aloba se fun un, ni o bi patapata.

DJ Ayobami sọ fun ile ẹjọ pe lọjọ Àìkú to ku ọla ti Mohbad yoo fi aye silẹ, ni awọn jọ lọ sí Ikorodu nibi to ti lọ ṣere.

O ni nigba ti awọn n pada bọ ni awọn kan da ọkọ Jiipu Prado awọn lọnà eyi to mu ki Mohbad bọọlẹ lati ba ọrẹ rẹ Primeboy ja ti o sí farapa níbẹ.

DJ Mohbad ni apa to wa lọwọ rẹ ko pọ amọ ọwọ naa ti wu nigba ti awọn dele ni òru.

O ni awọn gbiyanju lati pe nọọsi Mohbad lori foonu amọ o ni oun o si nile.

Nigba naa ni ọkan lara awọn ọrẹ rẹ ti o n jẹ Spending pe nọọsi to wa fun Mohbad ni abẹrẹ.

Ayobami ni ko si nkan to ṣe Mohbad ki nọọsi to wa fun ni abẹrẹ.

"Nọọsi yii lo sọ pe ki a lọ ba Mohbad ra oogun wa.

Nile oogun ní mo wa ti wọn ti sọ fun mi lori foonu pe ki n maa pada bọ sí ile.

Nigba ti mo pada de ni mo bá wọn nibi ti wọn ti n gbe e sinu ọkọ alabagbe rẹ kan ki wọn le tete gbe e lọ sile iwosan.

Amọ, bi mo ṣe ri i, ko si ẹmi lara rẹ mọ tori pe oju rẹ ti pade, ọwọ rẹ si ti da walẹ.

Ile iwosan ni wọn ti sọ fun wa pe Mohbad ti ku," DJ Mohbad lo ṣalaye fún ilé ẹjọ́ bẹẹ.

Mohbad ti ku ki wọn to pe mi - Baba Mohbad sọ fun ile ẹjọ

Ọgbẹni Joseph Aloba to jẹ baba oloogbe Mohbad, Wunmi to jẹ iyawo rẹ pẹlu mama Mohbad tó fi mọ DJ Ajisegiri Ayobami lo foju han nile ẹjọ lati salaye ohun ti wọn mọ nipa iku Mohbad.

Ninu ọrọ tiẹ, baba Mohbad ni Mohbad ti ku tan ki wọn to sọ fun oun.

"Mo ri Mohbad ni ọjọ mẹta sí ọjọ to kú, emi ati Mohbad si jọ sọrọ pọ.

Ọdun mejidinlogun ni Mohbad fi gbe pẹlu mi ki o to pinnu lati lọ maa gbe ibo miran.

Igba kan ṣoṣo ti mo gbe lọ fún itọju ri nigba ti o wa ni kekere, ti wọn sí tọju rẹ.

Wọn ti fi owu si imu rẹ nigba ti mo de ibi ti wọn gbe e sí.

Ni nkan bii ago marun ùn irọlẹ ni mọmọ rẹ pe mi wí pe nkan ti ṣe Mohbad.

Bí ago mẹsan an abọ ni mo de ibẹ, amọ ẹlẹmi ti gba a.

A gbe e lọ sí ile iwosan ijọba ni Ikorodu, wọn o gba a lọwọ tori a kò ní iwe lati ọdọ awọn ọlọpaa lọwọ.

Nigba ti wọn ko gba oku rẹ sí mọṣuari ni mo sọ pe ki a ṣe eto lati sìn in.

Mi o le wa wo oku ọmọdekunrin mi bayẹn gẹgẹ bii ọmọ Yoruba ti mo jẹ.

Mi o si le gbe oku rẹ sí ile bakan naa.

Ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Darosha ni o ṣeto posi ti a fi sin Mohbad,'' baba Mohbad lo sọ bẹẹ.