Ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin da àbá láti sọ ìdánwò WAEC, NECO, JAMB di ọ̀fẹ́ nù

Ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin ti fọwọ́ òsì ju àbá láti mú kí ìjọba àpapọ̀ ṣe ètò ìdánwò àṣekágbá ní ilé ẹ̀kọ́ girama (WAEC) di ọ̀fẹ́ fún gbogbo àwọn ọmọ Nàìjíríà fún sáà 2023/2024 nù.

Aṣòfin kan, Anamero Dekeri ló gbé àbá náà dìde pé ó yẹ kí ìjọba àpapọ̀ ṣe ètò ìdánwò WAEC, NECO àti JAMB ní ọ̀fẹ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní sáà yìí àmọ́ àwọn aṣòfin yóò da àbá rẹ̀ nù.

Ìpè yìí ló ń wáyé lásìkò tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn aṣòfin látàrí ọ̀bítíbitì owó tí wọ́n fẹ́ lò láti fi ra ọkọ̀ fúnra wọn.

Dekeri wòye pé ìjọba àpapọ̀ ti rí owó fi pamọ́ látara ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù tí wọ́n yọ àti pé ó yẹ kí wọ́n lo owó náà láti fi ran àwọn ọmọ Nàìjíríà tí kò rọwọ́ fi họrí lọ́wọ́ ni.

Ó ní ó yẹ kí ìjọba pa á láṣẹ fún Iléeṣẹ́ tó ń rí sí ètò ẹ̀kọ́ láti sọ ìdánwò náà di ọ̀fẹ́ fún sáà yìí.

Ó ṣàlàyé pé ṣíṣe àwọn ìdánwò náà ní ọ̀fẹ́ yóò jẹ́ kí àwọn mẹ̀kúnù náà jẹ àǹfàní ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù tí ìjọba yọ.

Àmọ́ àwọn aṣòfin yòókù tako àbá náà.

Olórí ọmọ ilé tó pọ̀ jùlọ Julius Ihonvbere ní kí àwọn aṣòfin san owó àwọn ìdánwò náà tí wọn kò bá lè pa ìjọba àpapọ̀ láṣẹ ṣe bẹ́ẹ̀.

Ṣùgbọ́n aṣòfin Ado Doguwa da àbá Ihonvbere nù pé ọ̀pọ̀ àwọn aṣòfin ló máa ń san owó àwọn ìdánwò náà tẹ́lẹ̀.

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjíròrò, Awaji Abiante pè fún àbá láti da àbá náà nù tí gbogbo àwọn ọmọ ilé sì fẹnukò le lórí.