Ọwọ́ tẹ aṣíwájú ẹgbẹ́ ajìjàgbara Cameroon lórílẹ̀èdè Norway

Oríṣun àwòrán, Ambazonian Defence Forces
- Author, Paul Njie
- Role, BBC News, Yaoundé
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3
Ajọ ajafẹtọ, Amnesty International ti fẹsun ipaniyan, ifipabanilopọ ati ifiyajẹni kan awọn ologun ijọba ati ikọ ologun ti awọn adijagbara naa.
Oṣiṣẹ ijọba Cameroon sọ fun BBC pe adehun wa laarin orilẹede Norway ati Cameroon lori eto abo, eyi ti yoo ri daju pe Norway fi Cho ransẹ pada si orilẹede Cameroon.
Agbẹjọro rẹ ni oun ko mọ ohunkohun nipa pe wọn fẹ gbe Cho pada si Cameroon lati wa koju ofin.
Taa ni Lucas Ayaba Cho?
Cho, ẹni to ṣapejuwe ara rẹ gẹgẹ bii ajafẹtọ ọmọniyan, to si jẹ ọkan gboogi to nlewaju ninu pipe fun ominira igun Anglophone kuro lorilẹede Cameroon.
Loju opo ayelujara, ẹni ọdun mejilelaadọta pe ara rẹ ni Ọgagun ati olori ologun fun ileeṣẹ ologun Ambazoninan, ọkan ninu ẹgbgẹ adijagbara to n pe fun ominira kuro orilẹede Cameroon.
Lati orilẹede Norway lo ti n pasẹ fun awọn alatilẹyin rẹ, to si tun paṣẹ konile gbele fun ọsẹ meji laipẹ yii.
Ninu oṣu Kini ọdun 2027, ori ko yọ nigba ti awọn kan fẹ ṣekupa lẹyin to ṣe ipade tan pẹlu pẹlu awọn olorin adijagbara yooku ni orilẹede Belgium.
Ni Ọjọbọ ọsẹ yii ni ileeṣẹ ọlọpaa gba aṣẹ lati fi ofin mu.
“A ti wa ni ipele akọkọ iwadii wa, to si tun ku awọn ipele mii ti a ma se,” Olupẹjọ Anette Berger ṣalaye.
Emmanuel Nsahlal, agbẹjọro kan to wa ni US to n soju awọn eeyan kan to padanu ẹmi wọn lasiko ija abẹle naa, kan sara si bi ọlọpaa se mu Cho, to si ṣapejuwe gẹgẹ bii aṣeyọri nla lori ikọju awọn adijagbara.
Cho kọ ni ẹni akọkọ to ni ajọsepọ pẹlu ominira igun kan ti wọn yoo mu ni oke okun.
Ni ọdun 2018, Julius Sisiku Ayuk Tabe, olori ẹgbẹ ajijagbara ati awọn mẹrindinlaadọta mii ni ọwọ tẹ lorilẹede Naijiria, ti wọn si fi wọn ransẹ pada si orilẹede Cameroon.















