Àwọn afurasí mẹ́ta pa ọlọ́kadà, ju orí rẹ̀ sínú odò ní Kwara

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ọwọ ṣikun ọlọpaa ileeṣẹ Kwara ti tẹ awọn afurasi mẹta kan ti wọn fẹsun kan pe wọn ṣekupa arakunrin kan, Rafiu Akano, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn, ti wọn si ge ori rẹ.

L’ọjọru, ọjọ kẹfa, oṣu Kọkanla, ọdun 2024 ni ileeṣẹ ọlọpaa Kwara ṣafihan awọn afurasi mẹta naa.

Orukọ awọn afurasi naa gẹgẹ bi ọlọpaa ṣe sọ ni Peter Samuel, Jeremiah Tiozinda ati Sunday Agbenke.

Nibi afihan awọn afurasi wọn yii, Kọmiṣanna ọlọpaa ni Kwara, CP Victor Ọlaiya, sọ pe lọjọ Kẹrin, oṣu Kọkanla, ọdun 2024, ni awọn mẹta kan Abdulrasheed Ọla Sheu, Ismail Muhammad ati elomii lati agbegbe Asunlere, Oke-Oyi, mu ẹsun wa si ileesẹ ọlọpaa pe awọn ri ara ti ko lori kan ni eti odo kan ni ilu naa.

Kọmiṣanna naa sọ pe lọgan ni awọn gbera lọ sibẹ lati bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa ti wọn si gbe ara ti ko lori naa lọ si ile iwosan ẹkọṣẹ fasiti Ilọrin fun ayẹwo.

O sọ pe nibi iṣẹlẹ naa ni awọn ti ri ẹrọ ibanisọrọ kan ti awọn fura si pe o jẹ tawọn to ṣiṣẹ laabi ọhun ati ọkada ti wọn woye pe o jẹ ti oloogbe, to fi mọ erọ ibanisọrọ oloogbe to wa lara rẹ.

Olaiya ni nipa iwadii to muna doko, ọwọ tẹ awọn afurasi mẹta yii laarọ ọjọ Kẹfa, oṣu kọkanla, ni aaye ọtọọtọ.

Wọn ri pe ẹrọ ibanisọrọ ti wọn ri naa jẹ ti Samuel Peter, ẹni to n gbiyanju lati sa kuro niluu Ilọrin, kọwọ to tẹ ẹ, awọn afurasi naa si jẹwọ pe lootọ lawọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn.

O ni awọn afurasi naa ni inu odo ni awọn ju ori ti wọn ge naa si, wi pe iwadii n lọ lọwọ lati ri ori naa. O sọ pe, lẹyin iwadii, wọn yoo foju ba ile ẹjọ.

Àlàyé lórí àgbẹ̀ tí aráàlú ṣì mú fún afurasí

Ṣaaju ni awọn ara ilu ti kọkọ nawọ gan eeyan kan ti wọn furasi pe biya oun lo ṣiṣe laabi yii.

Lasiko ti awọn ara ilu n le ẹni naa, ti wọn si fẹ fiya jẹ lo sare wọ agọ ọlọpaa Oke-Oyi lati sa asala fun ẹmi ara rẹ.

Eyi fa ọpọlọpọ awuyewuye bi awọn kan ṣe n fẹsun kan pe wọn ọlọpaa n dawọ bo awọn afurasi.

Ọga ọlọpaa naa wa ṣalaye bi ọrọ naa ṣe jẹ to si sọ pe agbẹ kan to n kọja lọ sinu oko rẹ jẹjẹ ni awọn araalu ṣi mu gẹgẹ bii ẹni to lọwọ ninu iku oloogbe naa.

O ni bi wọn ṣe ko firi rẹ, ni awọn araalu ati ọlọkada bẹrẹ si n le e, titi o fi sa asala fun ẹmi ara rẹ wọ agọ ọlọpaa Oke-Oyi, wọn si ba mọto rẹ jẹ kọja atunse.

Bakan naa ni Ọlaiya ni lara awọn to ba mọto naa jẹ tọwọ tẹ ni Yusuf Abdulkareem, ẹni ọdun mejilelogun, Arabinrin Jayeola Fatai, ẹni ogoji ọdun atawọn miiran ti ọlọpaa ṣi n wa bayii.

Ki ni ileeṣẹ ọlọpaa sọ lori ẹsun ti wọn fi kan Item7?

Kọmiṣanna Ọlaiya sọ pe iroyin ẹlẹjẹ ni iroyin tawọn eeyan kan n gbe kiri pe gbajugbaja to ni ile ounjẹ ti wọn ti n ta irẹsi ni ilu Ilorin, Item 7 lọwọ ninu iṣekupani naa.

“Eleyii jẹ irọ to jina si ootọ, ko lọwọ ninu rẹ, ati pe titan irufẹ iroyin ẹlẹjẹ yii nipa oniṣowo naa ko ni ṣakoba fun oniṣowo naa nikan bikoṣe pe yoo tun gba ijẹ lẹnu awọn oṣiṣẹ rẹ.

“Ẹni to n tan iroyin naa lori ayelujara rẹ, "Weaky TV" ni arakunrin Abdulwakeel Olajuwon ẹni ọdun mẹrinlelogoji.”

Abdulwakeel Olajuwon ni ẹnikẹfa ti awọn ọlọpaa ṣafihan rẹ lẹyin ti ọwọ ti tẹ oun naa.

Ọ̀kadà rẹ̀ la fẹ́ gbà ka sì tà á lówó gọbọi - Ọ̀kan lára àwọn afurasí náà ṣàlàyé

Lẹyin afihan naa, BBC News Yoruba fọrọ wa ọkan lara awọn afurasi naa, Peter Samuel, lẹnu wo, o ni ọkada tuntun ti oloogbe naa ṣẹṣẹ ra lo mu awọn loju ti awọn fi gba ẹmi rẹ.

Peter Samuel sọ pe, "ni nnkan bii ọjọ marun-un sẹyin ni ọga mi (ọkan lara awọn afurasi ti wọn mu naa) pe mi, wi pe iṣẹ wa lati ṣe.

"Igba ti mo de ọdọ rẹ, o ni ọlọkada ti o maa n gbe oun ṣẹṣẹ ra ọkada tuntun, wi pe ki n jẹ ka jọ pa a ka si gba ọkada rẹ, kaba le ta a lowo gọbọi.

"Ọlọkada naa gbe wa lọ si Olooru, igba ti a n pada bọ ni ẹnikeji mi bọ bata rẹ silẹ to si da ọlọkada naa duro pe oun fẹ lọ mu bata oun.

"Ibẹ lati la igi mọ-an lori, o ṣubu lulẹ, a si ge ori rẹ kuro lọrun rẹ. A o ri ọkada naa gbe tori a pade fijilante lọna, a ju ọkada naa kalẹ, a si ba ti wa lọ.”

Ẹwẹ, Ileeṣẹ ọlọpaa Kwara ti kede pe awọn ti sawari iyoku ara oloogbe naa, Rafiu Akao, ti awọn afurasi mẹta naa, Peter Samuel, Jeremiah Tiozinda ati Sunday Agbenke pa

Eyi waye ninu atẹjade ti agbẹnusọ ọlọpaa Kwara, Adetoun Ejire Adeyemi fi lede ni lọjọ Kẹjọ, oṢu Kọkanla.

Agbẹnusọ ọlọpaa ṣalaye pe awọn mẹtẹta ni wọn ti jẹwọ pe awọn ṣẹ ẹsẹ naa pẹlu ero lati gba ọkada ti oloogbe naa fi n ṣe iṣẹ ounjẹ oojọ rẹ.

Atẹjade naa ka wi pe lẹyin ti wọn tan Rafiu Akao lọ si oju ọlọmọ o tọmọ, ni wọn lagi bo o lori to si ṣubu lulẹ latori ọkada rẹ.

O sọ pe ọkunrin naa gbiyanju lati sa asala fun ẹmi ara rẹ sugbọn wọn ṣu bo o, Peter Samuel yọ ada jade, o si ge ori rẹ lulẹ, lẹyin naa ni Jeremiah Tiozinda gbe ori naa ati ada ti wọn fi ṣe iṣẹ laabi ju sinu odo, ti wọn si n gbe ọkada rẹ lọ.

"Ariwo iwa ika yii lo ta si awọn ẹsọ figilante agbegbe naa leti, ti wọn si gba tẹle wọn.

"Awọn afurasi naa sa wọ inu igbo, sugbọn ẹrọ ibanisọrọ, Peter Samuel jabọ sibi ti wọn ti huwa ọdaran naa, eyi lo si ṣe atọna si bi ọwọ ṣe tẹ wọn.

O ni wọn yoo wọ awọn afurasi naa lọ si ileẹjọ ni kete ti iwadii ba pari.

O fi kun-un pe ọga agba ọlọpaa ipinlẹ naa ti ṣeleri aabo to peye fun ẹmi ati dukia araalu, o si tun tẹmpẹlẹ mọ fifi ofin de ọkada ati kẹkẹ Marwa lati aago mẹsan-an alẹ titi di aago mẹfa owurọ.

O ni ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ pe o tasẹ agara sofin, yoo fimu kata ofin.