You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo àwọn àwòrán tó ṣe pàtàkì nínú ìtàn ìgbé ayé Donald Trump
Donald Trump ti bori eto idibo ilẹ Amẹrika, yoo si pada sile ijọba White House.
Nigba to n sọrọ lẹyin aṣeyọri rẹ, o ni awọn eeyan ilẹ Amẹrika ti fun ẹgbẹ Republican lanfani lati ṣe ju ti atẹyinwa lọ.
Ni bayii ti Trump atawọn ọmọ ẹgbẹ Republican n ṣajọyọ aṣeyọri rẹ, iwọnyii ni awọn aworan to ṣe pataki ninu itan aye rẹ.
Ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹfa, ọdun 1946 ni wọn bi Trump lagbege Queens, ni New York.
Oun ni ikẹrin ninu ọmọ marun ti awọn obi rẹ bi.
O ni ibatan ọkunrin meji, Fred Jr ati Robert – ati ibatan obinrin meji, Maryanne ati Elizabeth.
Elizabeth nikan ni ibatan rẹ to ṣi wa laaye, awọn to ku ti jade laye.
Trump ṣe igbeyawọ nigba mẹta ọtọtọ, si bi ọmọ marun un.
Lọdun n1977 lo fẹ Ivana Zelníčková.
Ọdun 2005 ni o fẹ Melania Knauss.
Agbebọn ẹni ogun ọdun kan gbiyanju lati gbẹmi Trump lasiko ipolongo ibo.