'Ó lé ní N5m tí a fi ṣe àyẹ̀wò ká tòó mọ̀ pé àìsàn ọpọlọ ló ń ṣe Bisola Badmus'

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Oriṣiriṣi ọrọ lo n jẹyọ lẹnu ọjọ mẹta yii nipa Bisola Badmus, gbajumọ oṣere tiata Yoruba, nitori aisan to maa n daamu ọpọlọ (Encephalopathy), to n ṣe e.

Bo tilẹ jẹ pe oṣerebinrin yii ti fi igba kan bo aṣiri ara rẹ lai sọ ohun to n ṣe e, ọrọ aisan naa ati ohun ti oju rẹ ti ri ko bo mọ rara lasiko yii.

Lori eto kan ti Biola Adebayo t'oun naa je oṣere tiata maa n ṣe lori ayelujara, iyẹn Talk -To -B, ni Bisola ti farahan lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹsan-an ọdun 2024.

Nibẹ lo ti ṣalaye lori aisan naa niwọnba bi òye rẹ ṣe mọ, ti ẹnikan to ba a wa, Oluwatomiyin Olaniyi, si pari alaye naa ni kikun.

Bisola Badmus sọrọ nipa bi aisan naa ṣe bẹrẹ ni nnkan bii ọdun mẹta sẹyin.

O ni igbagbe lo kọkọ fi bẹrẹ, to si tun pada di pe oun ko le kọ tabi ka iwe mọ.

O ni oun ko da ọmọ bibi inu oun gan-an mọ mọ nigba naa, oun ṣaa dupẹ ẹmi ati ohun gbogbo lasiko yii.

Oluwatomiyin lo pada ṣalaye pe Bisola Badmus ri iku soju, Ọlọrun ni ko pa a.

O ni Adunni, bawọn ṣe maa n pe e, ti n run ilẹpa tẹlẹ.

Bisola Badmus sọrọ lori ipa ti Wasiu Ayinde K1 to bimọ fun, ko ninu ọrọ rẹ

Lara ọrọ ti olootu beere lọwọ Bisola lori eto naa ni ti Mayegun ilẹ Yoruba, Alhaji Wasiu Ayinde (K1), gbajugbaja olorin Fuji, ti Bisola sọ pe oun bimọ ọkunrin kan, Malik, fun.

Ọpọ eeyan lo n sọ pe ko yẹ ki iya owo jẹ Bisola, nitori agba ọjẹ onifuji to lokiki lo bimọ fun.

Wọn ni o da bii pe Wasiu Ayinde ko gba ọmọ ti obinrin onitiata yii bi fun un, ati pe boya lo n ṣe ojuṣe rẹ bii baba lori ọmọkunrin naa.

Nigba to n ṣalaye lori ọrọ yii, Bisola Badmus dahun pe, Wasiu mọ pe oun bimọ fun un, amọ kọkọ mọ ohun to n ṣe oun, 'mi o sọ fun un'.

‘Nigba to mọ, wọn gbiyanju agbara wọn, ṣugbọn wọn o da si mi mọ latigba yẹn.’

Njẹ K1 tilẹ gba ọmọ ti Bisola bi fun un gẹgẹ bi ọmọ rẹ ni olootu eto naa tun beere, nitori awọn eeyan n sọ pe Wasiu ko ya si i rara. Eyi ni Bisola Badmus dahun si pe,

‘O gba ọmọ mi lati ibẹrẹ, nnkan kan yipada ni. K1 lo ku si lọwọ lati ṣe ojuṣe rẹ lorii Malik.’

'Adunni rí ikú sójú, ó rí ìnira, owó tí a fi ṣe àyẹ̀wò lásán lé ní mílíọ̀nù márùn-ún náírà'

Ninu ọrọ Arabinrin Oluwatomiyin Olaniyi to jẹ aburo Bisola Badmus, ṣalaye pupọ nipa aisan yii, obinrin naa sọ bi iṣoro naa ṣe bẹrẹ.

O ni 'nigba ti aisan yii bẹrẹ, ti a ba lọọ ri dokita to n tọju ẹ, ti wọn ba beere pe awọ wo ni aṣọ ọrun rẹ, Adunni (Bisola) yoo sọ pe oun ko mọ ọ.

Oun lo si mura funra rẹ to gbe baagi, nile.'

Arabinrin Olaniyi sọ pe Bisola ko tii ku, ṣugbọn, o ti n tán.

O ni o de asiko kan to jẹ pe awọ ara rẹ ti n ṣi, to si ma n wo ara rẹ ni iwo ikaanu.

‘Ni nnkan bii ọdun meji sẹyin, ni ayajọ ọjọ ibi rẹ, Adunni ri iku soju, o ti n run ilẹpa.

‘Ti mo ba wo o bayii, mi o ki n le sunkun niṣoju rẹ, ti mo ba dele ni mo maa n sunkun gidi. Ko da emi gan-an mọ lawọn asiko kan, ko mọ ọmọ rẹ to bi naa mọ. Mi o si le sọ fun un pe ‘’Brain Tumor’’ lo ni.'

Obinrin naa ṣalaye pe owo ti a awọn na lori ayẹwo lasan, le ni miliọnu marun-un Naira, ki wọn o to mọ pe nnkankan lo di sinu ọpọlọ rẹ.

'Mo ranti ọjọ kan ti wọn fẹẹ gba omi kan lati inu ọpọlọ rẹ nileewosan, ti wọn ki abẹrẹ to gun gan -an bọ ọ lapa, ti ẹni to fẹẹ gba omi naa ko tun waa ṣe e daadaa.

‘Emi ti mo di i mu gan-an n bẹru, Adunni funra ẹ kan beere lọwọ mi pe ṣe oun wa ok ni, mo dahun pe bẹẹ ni.

O le ni miliọnu kan Naira, 1.2m ti a sẹ ayẹwo ẹyọkan ṣoṣo.

''Oju rẹ ri , o nawo, o de ọrun bọ. O ta mọto mejeeji to ni, o si tun ta ilẹ naa mọ.

''Ṣugbọn nitori ki i sọrọ ara rẹ fun awọn eeyan, awọn kọọkan to gbọ lo ran wa lọwọ, awọn mii t'oun naa ti ṣe fun naa dide, ati awọn ẹbi rẹ naa.

Awọn ẹgbẹ oṣere naa dide. A dupẹ pe owo n funa, o dẹ ṣi n gba itọju si i.''

Bisola Badmus funra rẹ naa jẹrii si ti awọn onitiata ẹgbẹ rẹ, o ni wọn gbiyanju fun oun daadaa.

Kunle Afod, oṣere tiata t'oun naa maa n dide iranlọwọ si awọn eeyan to ba ku diẹ kaato fun nidii iṣẹ naa, ti ṣabẹwo si Bisola Badmus.

Ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan naira lo fun un pẹlu ileri pe iranlọwọ miran tun n bọ wa lati ọdọ awọn eeyan to ti kan si oun.

Ta a ni Bisola Badmus?

Nnkan bii ọdun mọkanlelogoji sẹyin ni wọn bi Bisola Badmus, ọmọ ilu Ijebu-Ode, nipinlẹ Ogun ni.

Gẹgẹ boun funra rẹ ṣe wi, o ti pe ọdun mẹtalelogun bayii to ti n ṣiṣẹ ere ori itage.

Ọdọ Toyosi Adesanya lo ni oun ti bẹrẹ iṣẹ tiata ṣiṣe.

Adunni, bawọn eeyan ṣe tun mọ ọ si, tun jẹ ọlọwọ ṣibi to maa n se ase ayẹyẹ (Caterer)

Bisola Badmus bi ọmọkunrin kan, Malik, eyi to ni Wasiu Ayinde, (KI) loun bi i fun un.