'Bí oyún oṣù méje ni ikùn mi ṣe tobí nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìju tó ń bá mi fínra'

'Bí oyún oṣù méje ni ikùn mi ṣe tobí nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìju tó ń bá mi fínra'

“Awọn asiko kan wa ti inira naa ma n pọ fun mi, debi pe mi o ki n le sun.”

Nigba ti Arabinrin Princessa Oreo kọkọ ṣakiyesi pe ikun rẹ n tobi ju bo ṣe wa tẹlẹ lọ, ko tete mọ nnkan to jẹ.

Bi ere bi awada, ikun rẹ ga pupọ to fi tobi to ‘oyun oṣu meje’.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to sẹ pẹlu BBC, Princessa ṣalaye pe niṣe ni oun bẹrẹ si i wọ awọn aṣọ to tobi lati le bo aṣiri ikun rẹ to tobi.

Irinajo rẹ si ileewosan lo ti han pe, oyun iju, ti wọn n pe ni fibroid ni ede Gẹẹsi, lo ni.

Awọn dokita sọ fun pe iju to wa ninu rẹ ju ẹyọkan lọ, ti ikọọkan wọn si tobi pupọ.

Lati asiko naa si lo ti n wa iwosan kaakiri.

Arabinrin Princessa ṣalaye pe, oriṣi itọju bii mọkanla – agbo, ewe, oogun oyinbo, ati bẹẹbẹẹ lọ - ni oun gba nitori aisan naa.

Lẹyin ọ rẹyin, iṣẹ abẹ ti ko fẹẹ ṣe naa lo pada ṣe lati gbe oyun iju naa jade nileewosan.

Ki lo n fa oyun iju?

Iwadii imọ ijinlẹ kan ti fi han pe obinrin mẹta ninu mẹwaa, ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mẹẹdọgbọn si ọgbọn ọdun, lo ma n ni oyun iju ni Naijiria.

Awọn ile iwosan ikọṣẹ iṣegun oyinbo to wa ni ilu Calabar, Port Harcourt ati Enugu, ni wọn ṣe iwadii naa.

Dokita agba ni ẹka ti wọn ti n mojuto awọn ẹya ara ti obinrin fi n bimọ, Obstetrics and Gynaecology, ni Ile iwosan ẹkọṣẹ iṣegun Fasiti Calabar, Ugwu Brown, sọ fun BBC pe, ìju lo wọpọ ju ninu awọn nnkan to ma n wu ninu ikun obinrin, ni Naijiria.

Bakan naa ni Dokita Christine Ekechi, to jẹ onimọ nipa ẹya ara ti obinrin fi n bimọ, sọ fun BBC pe ti iya tabi ẹbi eeyan l'obinrin ba ni iju ri, o ṣeeṣe ki ẹni naa ni iju.

"Iwadii kan tun fihan pe ti eroja Vitamin D to wa lara obinrin ba kere, o le fa iju nla."

Ko si ẹni to mọ nkan to n fa a ni pato, ṣugbọn awọn onimọ sọ pe awọn nkankan wa to le fi obinrin sinu ewu rẹ

  • Ẹya: Awọn obinrin to jẹ alawọ dudu lo wa ninu ewu ju lati ni oyun iju, ju awọn obinrin to jẹ alawọ mii
  • Ajogunba: Obinrin ti iya tabi ẹgbọn tabi aburo rẹ obinrin ba ni oyun iju, wa ninu ewu lati ni i
  • Awọn ọmọbinrin to tete bẹrẹ nkan oṣu: Awọn obinrin to ba bẹrẹ nkan oṣu ki wọn o to o pe ọmọ ọdun mọkanla, lo ṣe e ṣe ko ni oyun iju, ju awọn akẹẹgbẹ wọn to bẹrẹ nkan oṣu lẹyin ti wọn pe ọmọ ọdun mẹtala
  • Sisanra ju boṣeyẹ lọ: Oyun iju ma n mu ki eroja ara 'estrogen' pọ si ninu ara, to si ma n mu ki ọra pọsi ninu ikun
  • Obinrin ti ko loyun ri: Obinrin ti ko ba tete bimọ wa ninu ewu lati ni oyun iju
  • Itọ ṣuga: Obinrin to ba ni aisan itọ ṣuga wa ninu ewu nla, lati ni oyun iju
  • Ẹjẹ riru: Obinrin to ba ni aisan ẹjẹ riru naa le ni oyun iju
  • Awọn obinrin to ba ni aisan PCOS: Aisan to l'agbara ni PolyCystic Ovarian Syndrome (PCOS) fun awọn obinrin kan

Awọn ami oyun iju

  • Ẹjẹ to ba n jade lasiko nkan oṣu yoo pọ ju bo ṣe yẹ. Ọjọ ti obinrin naa fi n ṣe nkan oṣu yoo pọ, yoo si maa ni irora inu rirun lasiko nkan oṣu
  • O ma n buru debi pe obinrin naa yoo nilo ki wọn fa ẹjẹ si lara
  • Oyun yoo ma a bajẹ mọ obinrin naa lara.
  • Inu rirun ati inira ni isalẹ ikun
  • Kindinrin obinrin naa yoo wu, tabi ki inu rẹ kún
  • Inira lasiko ti obinrin ba ṣẹṣẹ loyun
  • Obinrin naa yoo ma a tọ loorekoore, inira lasiko to ba n tọ tabi ṣe igbọnsẹ.

Bi o sẹ le tọju oyun iju

Itọju ti wọn yoo fun obinrin to ba ni oyun iju nii ṣe pẹlu ọjọ ori, to ba ṣi fẹ ẹ bimọ, bi iju naa ṣe tobi si, ati ibi to wa ninu ile ọmọ.

Itọju gboogi to wa fun ni 'hysterectomy'; eyi ni ilana ti wọn n gba lati yọ ile ọmọ obinrin kuro ninu ara.

Ṣugbọn, itọju naa yoo jẹ nipa oogun lilo tabi iṣẹ abẹ.