You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Aya Tinubu ṣàfilọ́lẹ̀ aṣọ orílẹ̀èdè láti mú ìṣọ̀kan wà ní Nàìjíríà
Aya ààrẹ Nàìjíríà, Oluremi Tinubu ti ṣe ìfilọ́lẹ̀ aṣọ kan èyí tó júwe pé yóò mú ìṣọ̀kan wà ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà.
Ọ̀dọ́mọbìnrin ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n, Mofinyinfoluwa Bamidele ló ṣe àgbékalẹ̀ aṣọ náà tó sì jẹ ẹbùn mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n nááirà.
Ìgbìmọ̀ Renewed Hope Initiative (RHI) tí Oluremi Tinubu jẹ́ alága rẹ̀ ló gbé ìdíje kalẹ̀ fáwọn ọ̀dọ́ tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́ẹ̀dógún sí ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n láti ṣe àgbékalẹ̀ aṣọ kan tí yóò so gbogbo àwọn èèyàn pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà kan.
Tinubu ṣàlàyé pé ìdí tí àwọn fi ṣe àgbékalẹ̀ ìdíje náà lóṣù Kejì ọdún wáyé kò ṣẹ̀yìn ìrírí tí òun ní nígbà tí òun ṣe àbẹ̀wò sí orílẹ̀ èdè Zimbabwe nínú oṣù Kejìlá ọdún 2023 níbi tí òun ti rí nǹkan tó jọ bẹ́ẹ̀.
Ó sọ pé nígbà tí òun kópa níbi ètò níbi ètò ìpolongo #WeAreEqual tó wáyé ní Zimbabwe ni òun ti rí pé orílẹ̀ èdè náà ní aṣọ kan tó jẹ́ aṣọ tí gbogbo ìlú ń lò tó sì wú òun lórí.
Ó ní èyí ló jẹ́ kí òun rò ó pé kò ní burú tí irú àṣà báyìí náà bá wà ní Nàìjíríà, tí àwọn sì pinnu láti ri gbé ìdíje kalẹ̀ fáwọn ọmọ Nàìjíríà láti ṣe aṣọ tí àwọn yóò sì mú èyí tó bá dára jùlọ níbẹ̀.
Ó fi kun pé ìgbàgbọ́ òun ni pé aṣọ náà yóò dènà ìwà ẹlẹ́yàmẹ́yà àti pé nígbà tí òun tẹ́ pẹpẹ rẹ̀ síwájú ìgbìmọ̀ alákòso Renewed Hope Initiative, gbogbo wọn ni wọ́n gbàgbọ́ pé ìpinnu tó dára ni.
Aya ààrẹ náà sọ pé láti inú oṣù Kejì ni àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ náà, tó sì jẹ́ pé èèyàn tó lé ní ọgọ́rùn-ún ló fi iṣẹ́ wọn ṣọwọ́.
“A pé àwọn adájọ́ méjì ìyẹn Zainab Abba Folawiyo àti Banke Kuku tí wọ́n jẹ́ èèkàn nínú iṣẹ́ oge láti mú èyí tó bá dára jù nínú àwọn nǹkan táwọn èèyàn náà fi ránṣẹ́.
“Iṣẹ́ náà kò rọrùn àmọ́ a dúpẹ́ pé àwọn adájọ́ wa mú èyí tó dára jùlọ nínú àwọn aṣọ náà.”
Oluremi Tinubu ni ọjọ́ Kìíní, oṣù Kẹwàá tó jẹ́ àyájọ́ tí Nàìjíríà gba òmìnira ni àwọn èèyàn yóò wọ aṣọ náà.
Ó sọ pé àwọn ilé iṣẹ́ tó ń ṣe aṣọ ní Nàìjíríà ló máa pèsè aṣọ náà lọ́pọ̀ yanturu lójúnà àti pèsè iṣẹ́ àti pọkún ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà.
Ó ní ìgbésẹ̀ àwọn yìí wà ní ìbámu pẹ̀lú àfojúsùn ààrẹ Bola Ahmed Tinubu nípa ṣíṣe àtìlẹyìn fún àwọn iléeṣẹ́ abẹ́lé àti mímú ìṣọ̀kan wà ní orílẹ̀ èdè.