Ìjàmbá ọkọ̀ pa Mùsùlùmí bí 40 lásìkò tí wọ́n ń rìnrìn àjò lọ fún ayẹyẹ ọjọ́ ìbí Anọbi

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ogunlọgọ awọn ẹlẹsin Musulumi lo jẹ Ọlọrun nipe ninu ijamba ọkọ kan to waye lọjọ Aje.

Awọn olujọsin naa ni iroyin sọ pe o n rinrinajo lọ fun ayẹyẹ ọjọ ibi Anọbi, ninu ọkọ bọọsi J5 kan, niluu Saminaka, nipinlẹ Kaduna.

Iroyin sọ pe ọkọ akẹru nla kan lo gun ọkọ wọn mọlẹ lasiko to n gbiyanju lati ya fun ọlọkada kan to kọluu.

Oṣiṣẹ kan ninu àjọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Kaduna sọ pe eeyan mẹrindinlogoji lo ku ni owurọ ọjọ Aje.

Ṣugbọn ṣa, ẹni to gbe eto ti wọn n lọ fun kalẹ̀, Ahmad Dayyabu, sọ fun BBC pe ogoji eeyan lo ku, ti awọn mọkanlelọgbọn to farapa si n gba itọju nile iwosan.

"Ilu Kwandere ni awọn eeyan naa ti bẹrẹ irinajo wọn wa si Saminaka. Bi wọn ṣe de ilu Lere ni ọkọ akẹru nla kan gun ori ọkọ wọn mọlẹ."

O ni iwadii awọn fihan pe eeyan mọkanlelaadọrin lo wa ninu ọkọ to ko ijamba - eyi to tumọ si pe ero ti ọkọ ọhun ko ti pọ ju.

Wọn ti sin oku awọn eeyan naa bayii ni ilana ẹsin Isilaamu.

Ijamba yii waye lẹyin bi ọsẹ kan ti èèyàn bi aadọta ati ọpọlọpọ maalu jona ni ipinlẹ Niger.