You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Láàrin oṣù mẹ́ta, gbèsè Nàìjíríà ti di tírílíọnù mẹ́tàdínláàdọ̀rún(N87tn)
Ewu n bẹ loko Longe, gbese ti orilẹede Naijiria jẹ ti di tiriliọnu mẹtadinlaadọrun laarin oṣu mẹta pere.
Ẹka ijọba to n ri si ọrọ gbese Naijiria, DMO ṣalaye pe iye owo yii ni gbese Naijiria lẹyin oṣu mẹfa ninu ọdun 2023 yii.
Eyi tumọ si pe ida marundinlọgọrin ninu ọgọrun ni gbese naa fi le sii lẹyin ti gbese Naijiria jẹ N49tn ni ipari oṣu kẹta.
Ileeṣẹ ijọba to n ri ọrọ gbese Naijiria owo yi jẹ apapọ gbogbo gbese ti Naijiria n jẹ labẹle ati lagbaaye, to fi mọ gbese ti ipinlẹ mẹrindinlogoji ati Abuja n jẹ.
Ileeṣẹ naa ni afikun tiriliọnu mejilelogun(N22.712tn) ni koko owo to gori gbese ọhun.
Bakan naa ni ileeṣẹ ọhun tun ṣalaye pe awọn owo ti ijọba apapọ tun ṣẹṣẹ ya.
Amọ, ileeṣẹ naa sọ pe awọn eto ti ijọba aarẹ Bola Tinubu gunle yoo jẹ ki iyatọ ba ọrọ gbese ti Naijiria jẹ ni daadaa.
Ṣaaju ni ajọ ọhun ti kọkọ sọ pe gbese Naijiria yoo di tiriliọnu 77 lẹyin ti ile aṣofin agba buwọlu ẹbẹ aarẹ tẹlẹ ri, Muhammadu Buhari fun atunto akanṣe iṣẹ nile ifowopamo banki apapọ Naijiria, CBN.
Ṣaaju ni ọga agba ajọ DMO, Patience Oniha ṣalaye pe gbese Naijiria yoo di aadọrin tiriliọnu lai ṣe afikun tiriliọnu marun ùn owo ti ijọba ṣẹṣẹ ya ati tiriliọnu meji mii.
Amọ, gbese tiriliọnu mẹtadinlaadọrun yii ju afojusun ileeṣẹ ijọba to n ri si gbese Naijiria lọ.