Ta ni olórí Hamas tuntun Yahya Sinwar tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn eeyan ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ Hamas lorilẹede Palestine, ti kede olori tuntun, Yahya Sinwar.

Eyi waye lẹyin iku olori tẹlẹ, Ismail Haniyeh, to ṣẹlẹ lọsẹ to kọja, ni Iran.

Yahya Sinwar lo ti n lewaju ogun Hamas ni Gaza lati 2017.

Igbagbọ awọn eeyan Israel nipa rẹ ni pe oun lo wa nidii ikọlu to waye lọjọ keje, oṣu kẹwaa ọdun 2023, nibi ti ọmọ Isreal ẹgbẹrun kan ati igba (1,200) ti ku.

Ki wọn too fi ẹnu ko lati yan Sinwar sipo olori tuntun yii, o gba awọn agbaagba ibẹ lọjọ meji gbako lati fi ṣepade.

Ọkan ninu awọn agbagba to ṣepade naa, sọ fun BBC pe orukọ meji pere ni wọn kọ wa to le rọpo Haniyeh to ku. Awọn orukọ naa ni Yahya Sinwa ati Mohammed Hassan Darwish.

Gbogbo ile pata lo fi ọwọ si iyansipo Sinwar, BBC si gbọ pe wọn nigbagbọ ninu rẹ lati koju Israel ni wọn ṣe gbe ipo naa fun un.

“ Ṣebi wọn ti pa Haniyeh to yara bi aṣa to si mọ bi eeyan ṣe n yanju ọrọ, ni bayii, ki wọn maa gbaradi lati koju Sinwar ati idari ologun’’

Bẹẹ ni ọga to ba BBC sọrọ ṣalaye.

Ta ni Yahya Sinwar?

Yahya Sinwar jẹ ẹnikan ti wọn bu ọla fun gan-an ninu Hamas.

Oun lo wa nipo kin-in-ni ninu awọn eeyan ti Israel n wa, America paapaa si fi orukọ rẹ sinu iwe awọn agbesunmọmi nilẹ okeere.

Ọdun 1962 ni wọn bi Yahya Sinwar si ibudo awọn eeyan ti ko rile gbe, ni Khan Younis to wa ni Gaza.

Sinwar lo da ẹgbẹ alaabo Majd silẹ.

Ẹgbẹ naa lo maa n wa awọn eeyan Palestine ti wọn ni wọn n gbabọde fun Hama, ti wọn n ba Israel ṣe.

Sinwar ti lo ọpọlọpọ aye rẹ lọgba ẹwọn Israel. Ni 1988, nigba ti awọn Israel mu un fun igba kẹta, ileẹjọ kan ju u sẹwọn gbere lẹẹmẹrin.

Ṣugbọn ni 2011, o wa ninu awọn ẹlẹwọn ẹgbẹrun kan ati mẹtadinlọgbọn (1,027) ti Israel da silẹ, nigba ti Hamas gba lati yọnda Gilad Shalit, iyẹn ṣọja Israel ti awọn Hamas ti fi si ahamọ ju ọdun marun-un lọ.

Lati ọjọ keje, oṣu kẹwaa ọdun 2023 ti ikọlu ti waye ni Israel, ko si ẹnikan bayii to foju kan Sinwar nigboro.

Ninu oṣu kẹfa ọdun 2024 yii, Akọwe ipinlẹ lorilẹede America, Antony Blinken, sọ pe awọn gbagbọ pe Sinwar n sa pamọ si ajaalẹ mẹwaa ninu Gaza ni.

Kí ni Israel sọ?

Lori iyansipo Sinwar, ijọba ilẹ Israel ati awọn ọmọ ogun Israel Defence Forces (IDF), sọ pe afi kawọn tete yanju rẹ, ki ẹgbẹ buruku ti wọn gbe dani le tete kuro loke eepẹ.

Bakan naa ni, Daniel Hagari, agbẹnusọ IDF, sọ fun ẹka iroyin kan ni Saudi Arabia, pe “Agbesunmọmi to lọwọ ninu awọn ikọlu to buru julọ ni Yahya Sinwar."

Oṣiṣẹ alaabo tẹlẹ ni US, Javed Ali, sọ fun BBC pe iyansipo Sinwar le di akitiyan lati pari ogun yii lọwọ.

O ni eyi ri bẹẹ nitori Sinwar ki i gbọ, ki i gba, yoo si ṣoro lati ba jokoo sọrọ.