You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìyá, ọmọ àti ọmọ-ọmọ jáde láyé lẹ́yìn tí wọ́n jẹ àmàlà tán ní Ilorin, àláyé rèé lórí ohun tí ṣẹlẹ̀
Ibanujẹ dori agba kodo niluu Ilorin, nipinlẹ Kwara lẹyin ti iran mẹta dero ọrun lẹyin ti wọn jẹ amala tan.
Lọjọ Aiku ọjọ kẹrin, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024 yii ni iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ.
Ohun ti a gbọ ni pe Abilekọ kan, Halimat Yusuf ati ọmọ rẹ, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn kan, Kamaldeen Yusuf, lo kọkọ ku lojiji lọjọ Aiku nigba ti ọmọ-ọmọ rẹ kan naa Khalid Abubakar, ẹni ọdun mẹwaa naa tun ku lọjọ Aje.
Iwadii fihan pe awọn mii ti wọn jẹ ninu amala ọhun si tun wa nile iwosan nibi ti wọn ti n gba itọju bayii.
Ohun tawọn ẹbi sọ nipa iṣẹlẹ naa ree
Nigba to n ṣọrọ lori iṣẹlẹ naa, Ọgbẹni Babatunde Ayinde, ti Agboole Ọpẹlẹ, lagbegbe Taiwo niluu Ilọrin, sọ pe Halimat lo ro amala fun ọmọ ati awọn ọmọ-ọmọ rẹ lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide nigba ti wọn lọ ile mọlẹbi ọkọ rẹ.
O ni lati igba ti wọn ti jẹ amala ọhun tan ni wọn ti n bi ti wọn si n yagbẹ bẹẹ ni wọn n sọ pe inu n run awọn.
O fikun ọrọ rẹ pe, wọn gbe Kamaldeen lọ sile iwosan ẹkọṣẹ imọ iṣegun oyinbo (UITH) ti Fasiti Ilọrin ṣugbọn o pada ku.
Lasiko ti Halimat, to jẹ iya lọ wo o lọṣibitu ni wọn sọ pe Kamaldeen ti ku ni iya naa ba fo sanlẹ to si gba ibẹ lọ ti Khalid Abubakar, to jẹ ọmọ-ọmọ rẹ toun naa jẹ ninu amala ọhun si tun ku laarọ ọjọ Aje ọṣẹ yii sile iwosan.
O tẹsiwaju pe awọn ko le fidi rẹ mulẹ bayii pe amala ti wọn jẹ ni ṣugbọn ileeṣẹ to n ri si eto ilera ni Kwara ti wa, wọn ti bu ninu elubọ ti wọn jẹ ọhun fun ayẹwo.
O ni eeyan mẹta lo ti ku bayii tawọn mẹta miiran si tun wa nile iwosan.
''O ṣee ṣe ko jẹ ibi ti Halimat lọ pẹlu awọn ọmọ rẹ ni wọn ti jẹ majele''
Khalifa Olokuta to ṣọrọ lorukọ mọlẹbi Agboole Olokuta, to jẹ ile awọn mọlẹbi ọkọ Halimat Yusuf, sọ pe Halimat pade iku ojiji latari ipo to ba ọmọ rẹ ni ati pe ki i ṣe amala ti wọn jẹ lọdọ awọn lo ṣeku pa wọn.
O ni awọn ọmọ miiran to wa ni ile Olokuta, to jẹ ninu amala ọhun si wa laye ati ni alaafia wi pe ko si ohun to ṣe wọn.
Fun idi eyi, o ni ile iya wọn nile Ọpẹlẹ, ni wọn ti jẹ majele ki i ṣe ile awọn.
O tẹsiwaju pe lọjọ Abamẹta ni wọn ṣe ayẹyẹ ikẹkọọjade imọ kurani nile ni ile ti o jẹ ile awọn mọlẹbi iya, ti gbogbo wọn si lọ sibẹ, pe o ṣee ṣe ko jẹ pe ibẹ ni wọn ti jẹ majele ki i ṣe ile Olokuta rara.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ kọmiṣanna lẹka eto ilera nipinlẹ Kwara, Dokita Amina El-Imam, sọ pe ileeṣẹ to n ri si eto ilera nipinlẹ Kwara, ko ti i fidi rẹ mulẹ bọya lootọ ni pe amala ti wọn jẹ lo ṣeku pa wọn tabi ki i ṣe ohun, sugbọn iwadii si n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa.
"Bi o tilẹ jẹ pe ọrọ iku awọn oloogbe naa ti da ariyanjiyan silẹ laarin mọlẹbi mejeeji, mọlẹbi agboole Olókúta, lagbegbe Ẹrúdá ati mọlẹbi Ọ̀pẹ̀lẹ̀, lagbegbe Taiwo, niluu Ilọrin, idi ni pe nigba ti wọn jẹ amala tan nile baba wọn nile Olokuta , ni wọn pada sile Ọpẹlẹ, nile iya wọn".
BBC Yoruba kan si alukoro ọlọpaa ni ipinlẹ Kwara, arabinrin Ejirẹ Adetoun Adeyẹmi, amọ o sọ pe wọn ko tii fi ọrọ naa to ọlọpaa leti.