Olúdije sípò gómìnà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn jáde láyé

Oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ People's Redemption Party, Ọjọgbọn David Bamgbose tí jade laye lẹyin ti ẹgbẹ oselu naa kede rẹ gẹgẹ bii oludije wọn lọjọ marun-un sẹyin.

Bamgbose, ẹni to jẹ oludasile ile gbogbo niṣe Yewa gbẹ ẹmi mi ni ọjọ Ẹti ni ile iwosan aladani kan ni ilu Abeokuta.

Ọjọgbọn ọhun to jẹ ẹni ọdun mẹrinlelaadọta ni ó gba asia ẹgbẹ oselu People's Redemption Party ni Ọjọ ajẹ ọsẹ yii.

Agbẹnusọ rẹ, Oduntan Olayemi lọ kede ipapoda Ọjọgbọn fun awọn akọroyin

"Wọn ní pe o rẹ awọn ni Ọjọbọ ọsẹ yii, tí a sì ni ka gbe wọn lọ ile wosan kan ni Olomore, sugbọn wọn ka gbe ile wosan FMC.

"A gbe wọn lọ sí ilé wosan ti ijọba ibilẹ Lantoro.''

" Wọn gba Ọjọgbọn wọle sugbọn wọn fi afẹfẹ gaasi mi ni titi wọn fi jade laye.''

" Nigba ti mo de si ile iwosan ni mo bá wọn níbi tí mimi wọn ti lagbara, nibi ti mo ti lọ ra ogun tí wọn kọ fun mi ni mo ti gba ìpe pe Ọjọgbọn tí jade laye."