Orin Barrister ni mo fi kọ́ èdè Yorùbá, òwe – Mahmood ọmọ Hausa

Orin Barrister ni mo fi kọ́ èdè Yorùbá, òwe – Mahmood ọmọ Hausa

Salihu Dantata Mahmmod jẹ́ ara àríwá tó mọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ òrin olóògbé Sikiru Ayinde Barrister, Mr Fuji.

Mahmood ṣàlàyé fún BBC News Yorùbá wí pé láti kékeré ni òun ti fẹ́ràn láti gbọ́ orin Alhaji Agba nítorí àwọn òbí ló fi kọ́ òun.

Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí òun kìí ṣe Yorùbá, ìyá òun fẹ́ràn láti máa gbọ́ orin Yorùbá dáradára.

“Àwọn òbí tí wọ́n bi kò ní nǹkankan pẹ̀lú ìran Yorùbá àmọ́ màmá mi fẹ́ràn láti máa gbọ́ orin Barrister àti Kolawole Kollington Ayinla nígbà tí mo wà ní kékeré.”

“Nígbà náà ni èmi ti bẹ̀rẹ̀ sí ní fetí sí orin náà tó sì máa ń múmi lọ́kàn nígbà tí mó bá ń gbọ.”

Ó fi kun nígbà tí òun bẹ̀rẹ̀ sí ni fi etí sí àwọn àwo orin Barrister dada ni òun ri pé ó kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àròjínlẹ̀ àti ìrírí nípa ilé ayé.

Ó ní orin Barrister kún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀ ìṣítí àti ìwúrí nípa ọ̀nà tí ènìyàn le gbà lo ilé ayé.

Ọmọ Barrister kò gbàgbọ́ wí pé mo le kọ orin bàbá òun tó bẹ́ẹ̀.

Mahmood ní níbi tí òun fẹ́ràn àwọn orin Barrister dé, nígbà tí olóògbé Alhaji Agba dágbére fáyé òun báwọn péjú sí ìlú Ibadan fún ètò Fidau ọjọ́ mẹ́jọ.

Ó ní ní ọjọ́ mẹ́jọ tí Barry Made ń kọrin lọ́wọ́ tí wọ́n lọ sọ fun wí pé òun lé kọ àwọn orin bàbá rẹ̀ dada, kò gbàgbọ́ rárá.

“Nígbà tí mo gba gbohùngbohùn tí mo bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ àwọn orin náà ni ẹyọ kọ̀ọ̀kan, ẹnu ya àwọn ènìyàn pàápàá Barry Made.”

Ó yẹ kí ìjọba àpapọ̀ ṣe ohun málegbàgbé lórúkọ Barrister

Mahmood tún tẹ̀síwájú wí pé yóò ṣòrò fún ẹnikẹ́ni láti lè kọ ìdajì orin èyí tí Barrister kọ kó tó dagbére fáyé.

Ó ní pé pẹ̀lú gbogbo ipa tí Barrister ko lẹ́ka eré ìdárayá Nàìjíríà, ó yẹ kí àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀aṣòfin àpàpọ̀ Nàìjíríà ti gbé òfin kalẹ̀ láti bèrè fún ṣíṣe ohun málegbàgbé lórúkọ Barrister.

Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Oyo ti gbé ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀, ìjọba àpapọ̀ nílò láti gbé ohun kan kalẹ̀ lórúkọ Barrister kí ipa rẹ̀ le tẹ̀síwájú.

Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣíṣe ohun málegbàgbé lórúkọ Barrister yóò jẹ́ ohun ìwúrí fún ìran tó ń bọ̀.