You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Màá darapọ̀ mọ́ ìpolongo Yoruba Nation tí ipò ààrẹ̀ kó bá bọ́ sí Gúsù ní 2023 - Oluwo
Oluwo ti Iwo, Ọba Abdulrosheed Akanbi, ti sọ pe oun yoo darapọ mọ ẹgbẹ to n ja fun idasilẹ orilẹ-ede Oduduwa, ti ipo aarẹ ko ba fi bọ si Gusu Naijiria lọdun 2023.
Ninu atẹjade to fi sita ni ọjọ Ẹti, Oba Akanbi sọ pe ko ni i si idalẹbi kankan fun awọn to n ja ija naa, ti agbara ko ba fi bọ si iha Gusu.
O ni gbigbe agbara lati ẹkun kan fun ẹkun miran, ma n mu ki iṣọkan ko gbilẹ si ni orilẹ-ede ni.
Oluwo ṣalaye pe ipa ti oun ṣà gẹgẹ bi ori ade lo pa ina wahala ti ijijagbara fun orilẹ-ede Oduduwa, ko ba fa.
“Mo bẹ awọn ọba ni Ariwa, ati awọn oloṣelu to fi mọ gbogbo awọn alẹnulọrọ, lati ṣeranwọ ki agbara pada si Gusu Naijiria.
“Awọn oludije lati Gusu koju osunwọn lati dari Naijiria, bẹẹ ni ko si idi kankan to fi yẹ ki wọn o fi ipo agbara dùn wọn, paapaa fun iṣọkan orilẹ-ede.”
Oba Akanbi sọ pe akoyawọ ṣaaju idibo ọdun 2023 nikan lo le dena iru awọn iwọde to ti waye sẹyin.
Oluwo ni fifi agbara iṣejọba silẹ si Ariwa yoo tun ina ijijagbara fun orilẹ-ede miran dá.
O ni ireti oun ni pe awọn ti awọn pa ina ijijagbara naa, ko ni i pada darapọ mọ wọn ti agbara ba fi duro si Ariwa.
Nibo ni ipolongo Yoruba Nation de?
Laipẹ yii ni oludari ẹgbẹ to n ja fun idasilẹ orilẹ-ede Oduduwa, Ilana omo Oodua Ojogbon Banji, sọ fun BBC pe awọn ti fi iwe ifitonileti ranse si Aare Buhari lori erongba wọn.
O sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo naa pe awon ti jẹ ki ijoba mọ pe Yoruba setan lati lọ lasiko yii gẹgẹ bi o se tọna labẹ ofin iṣọkan agbaye.
Ati pe wọn ti fun ijoba Naijiria ni gbedeke asiko kan lati fi dahun ibeere iran Yoruba ninu lẹta naa.
Ọjọgbọn Akintoye ṣalaye pe iran Yoruba ko tii gba iyọnda lati da duro ṣugbọn ireti wa pe ki ọdun yii to pari ni yoo di mimuṣẹ pẹlu iranlọwọ awọn orilẹ-ede agbaye miran ti wọn n satilẹyin fun wọn.