Ọkùnrin kan fi àdó olóró gbẹ̀mí èèyàn 50

Oríṣun àwòrán, EPA
Ọkunrin ọdaran kan ti sekupa eeyan to to adọta ni ye lasiko ti iwọde kan n waye ni apa ariwa orilẹede Pakistan.
Awọn ẹsọ alabo ti kede pe ibu gbamu ọhun ti gba ẹmi awọn eeyan toto mẹrinlelogoji, ti eeyan toto igba si farapa yanayana ni iwọde ẹgbẹ oselu JUL-F ni Bajour.
Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ ọlọpaa fi lede , ọkunrin to wọ ado oloro naa sara sina bolẹ lara rẹ lẹyin to rapala bọ ibi ti awọn olori ẹgbẹ oṣelu naa joko si.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni iwadi awọn fihan pe isẹlẹ yii ko sẹyin isẹ ọwọ ẹgbẹ ẹlẹsin adijagbara ISIS.
ISIS ni o ti n da orilẹede naa ati orilẹede Afghanistan laamu lẹyin ti ijọba Aarẹ Ashraf Ghani kuro ni ijọba, to si tako isejọba Taliban ni orilẹede Afghanistan.
Bakan naa ẹgbẹ yii ni awọn ọmọ ologun kaakiri awọn apata ni Pakistan ti wọn sapamọ ni Peshawar.
Agbẹnusọ ẹgbẹ oselu JUL-F, Jalilk Jan ti pe fun iwadi lori isẹlẹ naa
"Ti ko ba si alaafia ni orilẹede yii, ko si ẹnikẹni yii yoo wa da idokowo rẹ si ibi bayii, a nilo alaafia ni Bajaur, Mohamand ati awọn agbegbe yooku. Ibu gbamu yii ku diẹ kato, a n pe fun iwadi lori isẹlẹ lati mọ ibi ti ọfa ti wa.
Ijọba ti wa kede ilu fararọ ni Bajaur ati awọn agbegbe to sumọ.
Awọn to farapa ti wọn fi ọkọ ofurufu gbe lati Bajaur lọ si ile wosan ni Peshawar pẹlu ọkọ oju omi awọn ọmọ ologun.
Olotu ijọba, Shehbaz Sharif ti bu ẹnu atẹlu isẹlẹ naa, to si ba awọn mọlẹbi to padanu eeyab wọn kẹdun, paapa awọn mọlẹbi olori ẹgbẹ oselu JUL-F Ziaullah Jan, ẹni to padanu ẹmi rẹ ni bi isẹlẹ naa














