Lásìkò tí Nàìjíríà ń pariwo àfikún owó oṣù, ńṣe nìjọba Oyo tún ń dín wa lówó àjẹmọ́nú - NLC Oyo

Aworan

Lowurọ ọjọ Aje ni ẹgbẹ osisẹ nipinlẹ Oyo tu sita lati se ifehonuhan, ti wọn si gbe agadagodo si ẹnu ọfisi Gomina ipinlẹ naa.

Ohun ti awọn oṣiṣẹ ipinlẹ yọ n fi ẹhonu han le lori yat si ohun ti awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ lapapọ n fapajanu le lori ti wọn si fi n gbero ati gunle iyanṣẹlodi lọjọru ọjọ keji oṣu kẹj ọdun 2023.

Awọn oṣiṣẹ naa ni lasiko ti gbogbo oṣiṣẹ n ke gbajare pe ki wọn fi kun owo to n ba awọn sile, nṣe ni ijba ipinlẹ Ọyọ tun n yọ lara awọn owo ajẹmọnu awọn kan .

Ẹwẹ, awọn oṣiṣẹ naa ni ẹhonu awọn tun da le bi ijọba ṣe kuna lati ṣeto igbega lẹnu iṣẹ fun awọn oṣiṣẹ.

Asiko to fun gomina lati joko ṣepade pẹlu Oṣiṣẹ ipinlẹ Ọyọ - Alaga ẹgbẹ Oṣiṣẹ NLC Ọyọ

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC, alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ ni ipinlẹ Ọyọ, Kayọde Oluṣẹgun Martins ni lara ohun ti awọn n fẹ ni ijokojiroro pẹlu ijọba ipinlẹ Ọyọ .

Martins salaye pe ọpọ igba lawọn aṣoju kii sọ ọgangan ọr fun ijọba eleyi to mu ki awọn kuku fi ni ki awọn gbe ara awọn wa ka gomina ipinlẹ Ọyọ mọ ile.

"Ohun ti a fẹ ni pe a fẹ ri Gomina, ki a salaye, awa naa si setan lati gbọ ohun to ba ṣe lalaye fun wa.

"Ifẹhonuhan yii yatọ si tijọba apapọ, ti ipinlẹ Oyo ni a n se yii.

"A fẹ joko pẹlu ijọba pe ibi bayii ni bata ti n ta awọn eeyan lẹsẹ, ọdọ wa ni ikun wa, a ni lati sọ wọn bi nnkan se n lọ,"

Bi pe ijọba n ja awọn osisẹ ni ole ni igbesẹ yii- Femi Aborisade

Awọn Oṣiṣẹ ni ipinlẹ Ọyọ

Ọkan lara awọn olufẹhonuhan, Femi Aborisade ni igbesẹ ijọba ipinlẹ Oyo lati gbe awọn igbesẹ lori adikun owo osu ati bi ijọba se kuna lati san owo osu fun awọn osisẹ fẹyinti kan

"Igbesẹ yii di pe ijọba ipinlẹ n ja awọn osisẹ ni ole ninu owo osu

"Ijọba n sọ gbogbo araye pe awọn n san owo osu sugbọn wọn ko sọ pe awọn ko san owo oṣu naa pe nitori owo to yẹ ki wọn san si apo owo ajẹseku awọn osisẹ ni wọn ko san.

"Ọpọlọpọ awọn osisẹ ni wọn ko ri igbega lẹnu isẹ wọn

"Eyi ni n pe fun nitori wọn n ja osisẹ ni ole ni