You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Aláboyún àti àwọn mẹ́jọ farapa níbi ìjámba iná gáàsì l’Ékòó
Niṣe ni ọrọ di bi o ko le lọ, ki o yago lọna lọjọ Iṣẹgun to kọja yii lagbegbe Ajegunle si Apapa, nigba ti ina afẹfẹ gaasi deedee ṣẹyọ, to si ṣakoba fun ọpọ eeyan ati dukia.
Awọn ti ko din ni mẹsan, to fi mọ alaboyun kan ni wọn farapa kọja sisọ, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Yatọ si alaboyun to farapa, awọn ọmọ kekeeke ati agbalagba naa fara kaaṣa ijamba yii, bo tilẹ jẹ pe wọn ti wa nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ.
Gẹgẹ bi ileeṣẹ to n ri sọrọ ijamba ina nipinlẹ Eko, Lagos State Fire and Rescue Service (LSFRS) ṣe ṣalaye, wọn ni agba afẹfẹ gaasi kan lo n jo, to si ran mọ waya to n gbe ina kọja, eyi ni wọn lo ṣakoba.
Agbegbe yii ni wọn sọ pe awọn eeyan ti n ṣowo tita ati rira agba afẹfẹ gaasi, iyẹn Gas Cylinder lojoojumọ.
Margaret Adeṣẹyẹ to jẹ alakoso ileeṣẹ LSFRS ninu ọrọ rẹ sọ pe loju ẹṣẹ ti iṣẹlẹ ọhun waye ni awọn oṣiṣẹ wọn ti sare lọ daabo bo ẹmi ati dukia awọn eeyan.
O tẹsiwaju pe ọsibitu ijọba to wa ni Ajerọmi ati Gbagada, iyẹn Gbagada Burnt & Trauma Centre lawọn ko gbogbo awọn to farapa naa lọ fun itọju.
Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ pe Kẹkẹ Maruwa mẹrin, ṣọọbu mẹfa to wa ni titi pa ati apakan lara ile kan to wa lagbegbe naa lo jona kọja sisọ.
Adeṣẹyẹ tun jẹ ko di mimọ pe bi awọn ṣe tete debẹ lo jẹ ki ina naa dawọ duro lati ma ba a ṣakoba fun awọn ile ati dukia miran to wa nitosi.