You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo ohun tí àwọn aráàlú ń là kọjá nítorí àìrí epo bẹntiróòlù rà lónìí
Bẹrẹ lati olu ilu orilẹede Naijiria lọ si awọn ipinlẹ mii ni awọn araalu ti n la ọpọlọpọ inira kọja lori rira epo bẹtinroolu.
Pupọ awọn Ileeṣẹ to n ta epo bẹntiroolu ni o wa ni titi pa niluu Abuja, ti ọpọ awọn osisẹ ijọba ati aladani ni ko anfani lati de si ibi iṣẹ wọn ni aṣiko.
Yatọ si pe ko si epo naa fun awọn araalu lati ra, ọpọ awọn ileeṣẹ to n ta epo bẹntiroolu lọwọlọwọ bayii ni wọn ti gbe owo le owo ti wọn n ta epo naa.
Lati ago marun-un owurọ ni mo ti wa ni ile epo
Pupọ awọn olugbe ilu Ibadan ni awọn agbegbe bi Iwo-road, Bodija, Sango, Oojo ati Eleyele ni ọrọ ọwọn gogo ṣe ọpọ ikoba fun.
Ọpọlọpọ awọn ile epo ni awọn agbegbe yii lo wa ni titi pa, ti awọn osisẹ wọn si joko sinu ile-epo nigba ti awọn miran si n ta epo naa ni ọwọn gogo.
Ikọ BBC ba Ọgbẹni Sunday lamidi ẹni ti o n fi ọkada sisẹ sọrọ, o salaye ohun ti oju rẹ ri
"Lati aago marun owurọ ni mo ti wa to si ile-po yi nitori ile-po NNPC yi ni owo wọn si walẹ ju lọ ni agbegbe bọdija wọn ta ni #560, ti awọn ile-po miran si n ta ni #680,#700 ati bẹẹbẹẹlọ".
Ọwọn gogo epo bẹntiroolu sakoba fun ọrọ ipinlẹ Kwara
Lasiko ti akọroyin ileeṣe BBC Yoruba kan si awọn ile epo lowurọ oni nipinlẹ Kwara, o ni ọpọ eeyan lo wa lori ila ti wọn si n reti epo yoo kan wọn ati pe ija ajaku akata waye ni ọpọ igba ni awọn ile epo naa.
BBC Yoruba ba Ogbẹni Wasiu Ọladele to jẹ awakọ sọrọ, o ni pe lati ago mẹrin idaji ni oun ti wa ni ile epo naa.
Omidan Ọmọlọla Awodibu to jẹ akekọọ sọ pe ohun ti duro fun ọpọ wakati lai ri ọkọ ati Okada ti yoo gbe ohun lọ ile ẹkọ.
Ni ile epo Bovas ládugbó offa garage to jẹ gbaju gbaja ile epo, titi pa lo wa.
Ile epo (NNPC) Asa-dam titi pa lo wa, ọpọ awọn ile epo lo gbe lẹkun ile epo wọn ti pa.
Ọlọkada ti orukọ n jẹ Jimọh akanji ni lati ago marun ijadi loun ti wa ni ile epo sibẹ ohun koi ti ri epo ra, o parọwa sì ijọba lati wa ikanse si ọrọ ọwọn gogo epo yii kara le dẹ araalu.
Ẹ ma fí wa sinu okunkun mọ lori ọrọ owo epo bẹntiroolu – Alaga awakọ l’Osun
Ileeṣẹ BBC Yoruba ba Femi Adeyemo to jẹ Alaga awọn ọlọkọ to wa ni adoju kọ ile Aregbesola nilu Osogbo.
Femi Adeyemo salaye siwaju wi pe, lati bi ọsẹ meji sẹyin ni wahala ọrọ epo petiroolu naa tun ti bẹrẹ ti ijoba apapọ ati ti ipinle ko sọ ikankan to fa ti epo petiroolu fi sọwọn.
Imọran mi si awọn ijọba ni wi pe, ki ìjọba apapọ jẹ ki gbogbo ara ilu ko mọ pato ibi ti ọrọ owo epo bẹntiroolu nlọ.
BBC Yoruba lọ se iwadi iye jala owo epo bẹntiroolu ni ile epo kan ti wọn npe ni Matrix niluu Osogbo.
Ọpọlọpọ awọn awakọ ati awọn ọlọkada lo to siwaju ile epo naa, ti wọn si nta jala owo epo kan ni 660 owo naira.
Yusuf Atanda to jẹ ọkan lara awọn ọlọkada to fẹ ra epo petiroolu salaye oun ti oju rẹ tí ri lati bi ọsẹ meji sẹyin.
Yusuf sọ fun BBC Yoruba wi pe, lati ago marun- un owuro ni oun ti wa epo bẹntiroolu kakari ki oun to de ile epo Matrix ni bii ago meje owuro ti oun ko si ti ni ireti wi pe oun yoo ri epo naa ra.
Yusuf tun tesiwaju ninu ọrọ wi pe, oun ko ni isẹ miran ju isẹ ọkada lọ. Isẹ naa ni oun fi tọju ẹbi oun.
Yusuf Atanda wa rọ awọn ijọba lati wa ọna abayọ si ọrọ owo epo petiroolu naa ki inira le din ku láwùjọ wa.
Ọwọn gogo epo bẹntiroolu ṣakoba nla fun ọrọ aje -Awọn olugbe ipinlẹ Ondo
Iwadi BBC Yoruba safihan rẹ pe awọn olugbe Ikare-Akoko, Owo, Ondo ati Akure ni iṣẹlẹ yi pa lara julọ bi o se sakoba fun awọn arin rin ajo ati awọn awakọ to fi mọ awọn onisowo.
N'ilu Akure awọn awọn arin rin ajo ni wọn bọ ha ti wọn si fajuro latari owo ọkọ to lọ soke si, ti wọn si benuate lu gbogbo awọn igbese ijọba eyi ti Are Bola Tinubu n dari. Bi wọn ṣe sọpe gbogbo aba ati igbese isejọba rẹ lo n se ipalara fun gbogbo ọmọ Naijiria
Lara awọn to ba BBC YORUBA sọrọ sọpe ọpọlọpọ ilé epo lo wá ni titi pa ti awọn pereje ton ta si n ta lowo gọboi.
Iwadi fi hàn pe awọn ile epo kan n ta petiro wọn ni N720 tí awọn miran si n ta ti wọn ni N850.
Olokada kan ati awakọ ti wọn ba BBC YORUBA sọrọ ni wọn fi aidunu wọn han lori bi wọn ṣe ji de ileepo ni afemoju ti wọn ko si ri petiro ra.
Awọn olugbe Ekiti kí gbe sita lori airi epo bentirolu ati ọwọn gogo re
Awọn ibudo ile epo diẹ ti o n ta epo bi NNPC, NIPCO, ENYO ati bẹẹ bẹẹ lọ sugbọn ti awọn ile epo aladani kankan ko ta epo.
Nigbati akọroyin BBC News Yoruba lọ kaakiri lati wo bi nkan ṣe ri fidi rẹ mulẹ pe iwọnba ọkọ moto lorin loju popo awọn opopona ni Ado-Ekiti.
Lara awọn ara ilu ipinle Ado-Ekiti to ba akoroyin wa soro ni Julius Ajayi ti gbogbo eyan mo si little by little ni ki ijoba apapo tete wa nkan ṣe si ọrọ epo yi pẹlu imoran pe ti o ba je pe wọn ma ya owo se rifanari ni ki wọn tete mojuto lati dekun iya yi.
Dauda Adeleke naa ni ki ijoba apapo tete ṣe ohun ti o ye lasiko pe ijiya wọn gogo epo yi ti pooju.
Adeoluwa Akinwunmi ni lati agogo meje owuro lohun ti wa ni ile epo ti ohun kosi ti ri epo ra titi di aago kan ọsan bayi rawọ ẹbẹ si ijoba lati mase maa fi iya jẹ mekunu.
Alaga ẹgbe task force Ọdun Ayọ Arinka ti ijoba ipinle Ekiti se agbekale rẹ naa lọ kakiri lati ri pe ko si rogbodiyan ni ile epo kankan ni ipinlẹ náà.
Arinka ni gbogbo ile epo ti ohun ati awọn emewa rẹ ti lọ kakiri ni wọn tele ilana sugbon awon ibi kokan ti o yẹ ki awọn fi ofin gbé wọn ni awọn ara ilu tún ba bebe.
Arinka ni ijọba ipinle Ekiti nṣe ojuse rẹ lati ri pe ọwọn gogo epo bentiroolu ko pa awọn olugbe ipinle Ekiti lara pupọ ki o ma ba mu akude gba ọrọ aje.
Wo ìdí tí ''ọ̀wọ́ngógó àti àìrí epo bẹntiróòlù rà yóò fi tèsíwájú síi fún ọ̀sẹ̀ méjì''
Ọwọngogo ati airi epo bentiroolu ra ti n peleke si nipinlẹ Eko at'awọn ipinlẹ mii lẹnu lọọlọ yii.
Afaimọ ki iṣoro t'awọn ọmọ Naijiria n koju yii ma tun tẹsiwaju pẹlu ọrọ ti ajọ IPMAN to jẹ ẹgbẹ alagbata epo rọbi ni Naijiria sọ wi pe o kere tan o maa to ọsẹ meji sii ki epo bẹntiroolu to wa kaakiri fun rira bii ti tẹlẹ.
Bo tilẹ jẹ pe ajọ NNPCL to n ri si ọrọ epo rọbi sọ lopin ọsẹ wi pe awọn ni epo to to ọmọ Naijiria lo ni ipamọ, alukoro ẹgbẹ IPMAN, Ọgbẹni Chinedu Ukadike ti fidi rẹ mulẹ pe ko si epo to to araalu lo ni Naijiria lọwọ yii.
Idi ree ti iṣoro 'ọwọngogo ati airi epo yoo fi tẹsiwaju'
Ninu alaye rẹ, alukoro ẹgbẹ IPMAN ni ara ipenija t'awọn alagbata epo rọbi n koju lọwọ yii ni pe ọpọ ile ifọpo nilẹ Yuroopu ni wọn n ṣe atunṣe níbẹ lọwọ.
Ukadike ni ati ri epo gbe wọlẹ lati ilẹ okeere jẹ ọkan lara ohun to ṣokunfa airi epo ra ati ọwọngogo epo to gbode.
Bakan naa ni alukoro ẹgbẹ IPMAN fidi rẹ mulẹ pe ọpọ alagbata epo rọbi ni ko tii ri isọdọtun iwe aṣẹ ti wọn fi n ṣiṣẹ ṣe.
Ọgbẹni Ukadike ṣalaye pe 1,050 awọn alagbata epo ninu awọn 15,000 ni o tii ri isọdọtun iwe aṣẹ ti wọn fi n ṣiṣẹ ṣe ni ọfiisi ajọ NMDPRA to n mojuto ọrọ epo rọbi.
"Iṣoro ti a n koju ni pe a o ri epo gbe wọle, eyi gan an lo n fa airi epo ra t'awọn eeyan fi n to kaakiri ile epo.
Nigba kugba ti iṣoro ba ti wa pẹlu gbigbe epo wọle lati oke okun, o maa n ṣakoba fun awọn araalu ni Naijiria nibi tori ati ilẹ okeere lati ti n gbe epo ti a n lo wọle.
Ọgagba NNPCL ti fi dawa loju pe nnkan yoo yatọ laipẹ tori awọn ọkọ ojuomi awọn ti n gbe epo wọle.
Ti eyi ba ti ṣẹlẹ, epo yoo wa kiri pada.
Ohun to maa n ṣẹlẹ ni pe ti iṣoro ba ti le wa pẹlu eto gbigbe epo wọle fun oṣu kan, o maa n to oṣu meji si mẹta lati ṣe atunṣe ki nnkan to le pada bọ sipo.
Lori awọn alagbata ti wọn ko tii ri isọdọtun iwe aṣẹ wọn ṣe, ajọ NNPCL ti ni wọn ko ni lanfaani lati wa lara awọn alagbata ti yoo maa gbepo wọle.
Idi niyii ti ọpọ ninu wa ko ṣe lanfaani lati gbe epo wọle lati ilẹ okeere.
Ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹrin ni gbedeke ọjọ ti NNPCL fun gbogbo awọn alagbata epo lati ṣe isọdọtun iwe aṣẹ wọn eyi to ti kọjá lọ bayii.
A wa n rọ NNPCL lati sun gbedeke ọjọ ti awọn alagbata gbọdọ ṣe isọdọtun iwe aṣẹ wọn siwaju sii tori ohun ti wọn n beere fun pọ," Ọgbẹni Ukadike lo ṣalaye bẹẹ.
Kinni ajọ NNPCL sọ lori ọwọngogo ati airi epo bẹntiroolu ra?
Ajọ NNPCL to n ri si ọrọ epo rọbi ni Naijiria ti sọ pe awọn ni epo to pọ ni ipamọ.
Agbẹnusọ NNPCL, Olufemi Soneye, sọ pe awọn eeyan ko ni maa to mọ nile epo laipẹ lai jina.
O sọ ninu ọrọ rẹ pe "ajọ NNPCL fẹ fi dawon araalu loju pe airi epo ra ati ọwọngogo epo tawọn eeyan koju ṣẹlẹ latari awọn kudiẹ kudiẹ kan to ṣẹlẹ.
Amọ, bayii gbogbo kudiẹ kudiẹ yii ni a ti yanju.
Bakan naa ni a n fi dawọn eeyan loju pe iye ti a n ta epo ko tii yipada.
A wa rọ awọn eeyan wi pe ki wọn ma fi ìbẹrù ra epo tori epo to to gbogbo eeyan ra wa.''