Wo ọ̀pọ̀ àkóbá tí òfin ìjọba ń ṣe fún okòwò epo bẹntiró lẹ̀nu bodè Nàíjíríà sí ilẹ̀ Benin

Wo ọ̀pọ̀ àkóbá tí òfin ìjọba ń ṣe fún okòwò epo bẹntiró lẹ̀nu bodè Nàíjíríà sí ilẹ̀ Benin

Bi o tilẹ jẹ pe iye epo bẹntiro ti wọn ni a n lo ni Naijiria fi ida ọgbọn dinku lẹyin ti ofin naa fidi mulẹ, amọ akoba nla nla lo n koju awọn olugbe awọn orilẹede to mule ti wa bi ọdun se n gori ọdun.

Ọna lati sewadi lori bawọn eeyan to wa ni orilẹede Benin, paapaa awọn ilu to jẹ ti Yoruba n gba lati ri epo ra tabi lo, lo mu ki BBC Yoruba se abẹwo sawọn ilu Yoruba to wa ni orilẹede naa

Bakan naa la fẹ mọ ipa to pọ ti ofin Naijiria maa n ni lori awọn eeyan to mule tiwa naa, abọ BBC Yoruba ree.

Ninu irinajo BBC Yoruba silu Owode-Apa ati Pogidi ti wọn wa lorilẹede Benin amọ ti wọn sun mọ ẹnu bode Naijiria, a gbọ pe ilu Badagry to wa ni Naijiria ni wọn ti maa n ra epo bentrol wa sinu ilu naa.

Amọ lati igba ti ijọba Naijiria ti se ofin pe wọn ko gbọdọ ta eroja epo rọbi ni ogun kilomita si ẹnu bode orilẹede yii, ni epo bẹntirol ti di imi eegun.

Ọpọ ileepo ti wo nigba ti awọn miran wa ni titipa, to si da paroparo

Se ni wọn si n sare soju popo ti wọn ba ti ri mọto kan, ti iwadi si fihan pe epo bentiro ni wọn fẹ ta fun onimọto Kii se ile epo nikan ni wọn ti n ta epo yii, se ni wọn tun n ta ninu sọọbu ati labẹ igi, lai bikita fun ewu to rọ mọ igbesẹ yii.

Bakan naa, a ri pe ọpọ ileepo to wa lawọn agbegbe yii ni wọn ti gbe ilẹkun wọn tipa.

Ọpọ ileepo mii ti wo nigba ti awọn miran wa ni titipa, to si da paroparo.

A si fi oju wa se mẹrin bi wọn se n ri epo bẹnrol sinu igo ke ke ke ati igo nla, ti wọn si n le sori atẹ bi ẹni pe epo pupa ni wọn n ta.

Igbesẹ yii si la ri pe o lewu pupọ fun awọn ontaja ati onibara epo bẹntirol yii nitori bi aabo to kun to ko se si fun wọn, ti igo epo naa si le tete gbina.

Koda, a gbọ pe ọpọ awọn ontaja epo naa lo ti fi okoowo naa silẹ nitori bo se gbe owo lori.

''N22,000 ni a n ra epo kẹẹgi kan lati Badagry amọ ka to gbe de ibi, ẹgbẹrun meje Naira la pin fawọn eeyan, ka to ri ọna kọja''

Yatọ si eyi, wọn ni awọn asọbode gan n han awọn ni eemọ nitori pe ọpọ kẹẹgi epo bẹntirol olowo iyebiye ni wọn ti gba silẹ lọwọ awọn.

Wọn ni ọpọ ontaja epo naa si lo ti jẹ gbese, ti epo bẹntirol si ti di imi eegun.

Nigba ti a se iwadi iye owo kẹẹgi epo bentiro kan ni awọn ilu mejeeji naa, a gbọ pe ẹgbẹrun mejilelogun Naira ni wọn n ra kẹẹgi epo bẹntirol kan ni Badagry wa sawọn ilu naa to wa ni orilẹede Benin.

‘’N22,000 ni a n ra epo kẹẹgi kan lati Badagry amọ ka to gbe de ibi, ẹgbẹrun meje Naira la pin fawọn eeyan, ka to ri ọna kọja.

Tẹlẹ tẹlẹ, wọn si maa n gbe wa sibi amọ nigba tijọba Naijiria ti se ofin pe wọn ko gbọdọ ta epo ni ogun kilomita si ẹnu bode, a ko ri epo ra mọ.

Ọkada ni a fi n gbe, ti a ba n lọ ra epo naa, N1000 la san fun ọkada amọ N7000 la fi gbe kẹẹgi kan wa sibi lati Badagry. Igo epo Kẹrosini kan ti di N1,500 lati Badagry bayii.”

“Ẹgbẹrun lọna ọọdunrun Naira, N300,000 owo ajọ ti mo gba, ni mo fi dokowo lori epo yii amọ to ku N50,000''

Ontaja miran to ba BBC Yoruba sọrọ, Aloya Dupe, tiẹ salaye bi owo nla to fi dokowo lori katakara epo naa se run.

“Ẹgbẹrun lọna ọọdunrun Naira, N300,000 owo ajọ ti mo gba, ni mo fi dokowo lori epo yii.

Kẹẹgi mẹjọ epo ni wn gba lọwọ mi nilu Gbaji.

Bi wọn se n gba a lọwọ mi ree titi ti owo ajọ ti mo gba fi ku ẹgbẹrun lọna aadọta Naira. Owo yii ni mo ko fun ọmọ mi ko lọ fi sanwo idanwo WAEC rẹ, ki n maa ba padanu gbogbo owo naa tan.”

Ọpọ awọn onta epo yii si lo n fi ika hanu pe inu okoowo yii ni awọn ti n bọ ara awọn ati idile awọn amọ ti gbogbo rẹ ti n doju de bayii.