Pásítọ̀ parọ́ pé wón jí òun gbé, ó gba owó ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọmọ ìjọ làṣírí bá tú!

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Plateau ti pasitọ kan ti orukọ re n jẹ Albarka Bitrus Sukuva fun ẹsun pe o ji ara rẹ gbe, to si tun aimọye lọwọ awọn olujọsin rẹ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Alabo Alfred, ninu atẹjade to fi ransẹ si awọn akọroyin lọjọbọ ọsẹ yii ni ọwọ tẹ pasitọ ọhun pẹlu akẹgbẹ rẹ lẹyin ti awọn ọmọ ijọ ti san owo toto ẹgbẹ lọna ọgọrun un mẹfa owo itusilẹ.

“Ileeṣẹ ọlọpaa ti sawari Pasitọ kan, Albarka Bitrus Sukuva, ẹni to lẹdi apupọ pẹlu awọn eeyan lati ji ara rẹ gbe lati fi gba owo lọwọ awọn olujọsin rẹ.

“Lọjọ kẹrinla, oṣu kọkanla ọdun 2022, ni awọn ọmọ ijọ san ẹgbẹrun lọna ọgọrun mẹrin naira, ti wọn si san ẹgbẹrun lọna ọgọrun meji miiran lọgbọnjọ oṣu kejila .

“Lẹyin ọpọlọpọ iwadii, ileeṣẹ ọlọpaa fi iwe ipe ransẹ si Pasitọ, ti iwadi si fihan pe o lẹdi apupọ pẹlu awọn kan lati ji ara rẹ gbe.

“Lẹyin ọpọ ifọrọwerọ, Pasitọ jẹwọ, to si darukọ awọn ẹmẹwa rẹ ti wọn jọ isẹ naa. O darukọ Baruk Mailale, Nathaniel Bitrus ati awọn meji miiran.”

Gẹgẹ bii agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ṣe sọ, Afurasi tun jẹwọ pe oun dana ọkọ ayọkẹlẹ meji to jẹ ti Pasitọ agba nile ijọsin naa lọjọ kẹrin ọsu kinni ọdun yii.