Pásítọ̀ àtàwọn méjì míì dèrò àtìmọ́lé lẹ́yìn ikú ọkùnrin tí wọ́n yọ iké ẹ̀yìn rẹ̀ nítorí ₦‎10m

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Bayelsa ti bẹrẹ iwadii lẹyin iku ọkunrin kan ti awọn eeyan kan yọ ike ẹyin rẹ lọna ati fi nnkan inu rẹ gba miliọnu mẹwaa naira.

Eyii lo n waye lẹyin ti ẹgbẹ awọn fijilante kan, Onelga Security Peace and Advisory Committee, OSPAC, ni ijọba ibilẹ Ogba Egbema Ndoni, nipinlẹ Rivers fi ṣikun ofin mu eeyan mẹta lori iku ọkunrin abuke naa, Lucky Wilson.

Ẹni ọdun mẹrinlelogun ni ọkunrin abuke naa ko to jade laye.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, pasitọ wa lara awọn afurasi ti ọwọ tẹ lori ọrọ ọhun.

Iroyin ni iku oloogbe naa waye lẹyin ti wọn ṣe iṣẹ abẹ fun un.

Adari OSPAC, Felix Nwaobakata ṣalaye fun BBC pe ọwọ awọn tẹ awọn afurasi naa lasiko ti wọn n gbiyanju lati salọ siluu Port Harcourt lẹyin ti iya Lucky ke gbajare pe oun n wa ọmọ oun.

Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye

Nwaobakata sọ pe ọrọ naa bẹrẹ nigba ti iya oloogbe naa wa sọ fun ikọ awọn pe Lucky ati baba rẹ ririnajo lọ siluu Eko, amọ baba nikan lo pada wale, ti ko si le ṣalaye ohun to ṣẹlẹ si Lucky.

O ni ninu iwadii awọn, awọn fi ṣikun ofin mu ọkan lara awọn afurasi, to jẹ pasitọ ninu ijọ kan lagbegbe Omoku, to si sọ pe baba Lucky ati aburo baba rẹ kan lo fa a le awọn lọwọ.

O sọ pe lẹyin naa ni wọn bẹrẹ iṣẹ abẹ fun ki wọn le yọ ike to wa lẹyin lọna ati yọ nnkan ti wọn n pe ni ‘mercury’ ninu ike naa.

O ni “Afurasi naa ni gbogbo wọn fẹnuko lati ṣiṣẹ abẹ fun Lucky, wọn si kan si ọkunrin kan niluu Abeokuta, to si ṣeleri pe ohun yoo fun wọn ni miliọnu mẹwaa naira fun ike ọhun lati yọ ‘mercury’ inu rẹ.”

Afurasi ọhun sọ siwaju si pe oloogbe naa fura rẹ lo wa ba awọn pe ki wọn yọ ike oun ki oun le lanfani lati maa duro bi awọn ọkunrin to ku.

O ṣalaye pe awọn kilọ fun pe iku ni yoo gbẹyin iṣẹ abẹ naa amọ o kọ jalẹ pe wọn gbọdọ yọ ike naa ni, wọn si fẹnuko lori ọjọ ti iṣẹ abẹ ọhun yo waye.

Agbẹnusọ OSPAC ni awọn afurasi naa sọ pe ajọ kan ti kii ṣe ti ijọba, NGO, lo kọkọ sọ pe oun yoo yọ ike naa ti oun yoo si fun wọn miliọnu marun un naira ṣugbọn NGO naa ja awọn kulẹ.

Lẹyin ti NGO ọhun ja wọn kulẹ tan ni wọn tọ ẹlomiran lọ niluu Abeoukuta to ni oun yoo yọ ike ọhun lati yọ ‘mercury’ inu rẹ, ti oun yoo si fun wọn ni miliọnu mẹwaa naira.

Lẹyinorẹyin, afurasi sọ pe oloogbe ati baba rẹ tẹkọ leti lọ siluu Eko, ki wọn to gba ibẹ lọ siluu Abeokuta nibi ti baba ologbe ti fa a le awọn lọwọ pẹlu ẹgbẹrun marundinlogun naira owo ọkọ.

“Ko si mercury kankan ninu ike”

Adari eto ilera kan nipinlẹ Rivers, Golden Owhonda, ti sọ pe ko si ohun to n jẹ mercury ninu ike.

O ni aisan kan ti wọn n pe ni ‘scoliosis’ eyii to n yọ ọpa ẹyin lẹnu lo n ṣakunfa ike lara eeyan.

Dokita naa ni o jẹ ohun iyalẹnu pe awọn kan le gbẹmi eeyan nitori ohun ti ko fidi mulẹ, o si yẹ ki awọn afurasi naa foju wina ofin.

Gẹgẹ bii ohun ti dokita naa sọ, awọn kudiẹkudiẹ kan to maa n waye lasiko ti obinrin ba n bimọ le jẹ ki eegun ẹyin ọmọ wọ, eyii ti yọri si ike.