Màmá mi kò fi ayé ni ẹnikẹ́ni lára, ó kọ́ mi láti jẹ́ akíkanjú àti aláàánú

Gbajugbaja oṣere to tun dije du ipo gẹgẹbi Igbakeji oludije sipo gomina nipinlẹ Eko, Funke Akindele ti sọrọ manigbagbe nipa iya rẹ to doloogbe, Dr. RB Adebanjo-Akindele.

Ẹgbọn Funke Akindele, Olubunmi Akindele lo kọkọ kede iku rẹ wọn ninu atẹjade ti wọn fi si oju opo Instagram.

Nibẹ ni Olubunmi ti kede pe Ọjọ Keje, Oṣu Keji, ọdun 2023 ni iya awọn jade laye.

Loju opo Instagram bakan naa ni Funke ti wa sọrọ iwuri nipa iya rẹ to doloogbe naa.

Funke ṣapejuwe iya rẹ gẹgẹ bi akinkanju obinrin to si tọ awọn ọmọ rẹ lati jẹ akinkanju ninu iṣẹ ti wọn ba yan laayo.

Bakan naa lo ni iya oun fi gbogbo aye rẹ tọ awọn eniyan sọna, to fi mọ awọn ti kii ṣe ọmọ to bi ninu ara rẹ.

O ni inu oun dun pe ipa igbe aye ti iya oun fi silẹ lọ yoo wa titi lai, ti oun ko si ni gbagbe rẹ.

‘’ Iya mi tọ mi sọna lati jẹ akinkaju obinrin ti ko ṣe imẹlẹ tabi fa sẹyin ni idi iṣẹ rẹ’’

‘’Olubukun lo jẹ fun gbogbo ẹni to wa ni ayika rẹ, lai fi ti awọn ọmọ rẹ nikan ṣe. Gbogbo ẹni to ba sunmọ ọ ni oun ṣaanu fun.’’

‘’Ẹ kọ wa ni ọna Ọlọrun, ẹ kọ wa lati maa gbadura, lati sin Ọlọrun ati lati fi gbogbo nkan le lọwọ.

Ẹ gbin ibẹru Ọlọrun si ọkan wa ati lati maa saanu fun awọn eniyan.’’

‘’Iya mi ko duro nipa kikọ awa ọmọ rẹ nikan, gbogbo awọn ọmọ-ọmọ lo jẹ ọla rẹ, ti o si kọ wọn lati maa gbadura lati kekere.’’

‘’Iya mi, o ko fi aye ni ẹnikẹni to sunmọ ọ lara, to si sa gbogbo ipa rẹ lati ri pe igbe aye wa dara.

Mo dupẹ lọwọ rẹ iya mi, ẹ ṣe ti ẹ kọ wa daradara.’’

‘’Bio tilẹ jẹpe o dun wa lọpọ lọpọ bi ẹ ṣe fi wa silẹ lọ, amọ igbe aye manigbagbe yin wa pẹlu wa titi lai ati awọn ọmọ-ọmọ pẹlu.’’

‘’Haa, iya mi, mo ṣedaro rẹ o, amọ mi o mi dẹkun igbiyanju mi ni ile aye gẹgẹ bi ẹ ti kọ mi lati maa ṣe.’’

‘’Maa ri pe mo fi gbogbo agbara mi ati iṣe mi ṣe ohun gbogbo to ba wa ni ikawọ mi, ti iwọ yoo si maa jẹri mi nibi to ba wa lọhun titi ayeraye.’’

‘’O dun mi lọpọlọpọ amọ igbagbọ mi nipe, ibi to dara ni o wa ni Ọrun.’’

‘’Inu mi dun wipe o ko sunkun lori ọmọ kankan tabi ọmọ- ọmọ to si gbe igbe aye to buyi kun eniyan.’’

‘’A o sọkun bi ẹni to n ṣọfọ lori rẹ iya mi, amọ a dupe pe o gbe igbeaye to wuyi. Ki ẹmi rẹ ni alaafia titi ayeraye. Mo ni ifẹ rẹ iya mi.’’